Wo ẹni tí a bí pẹ̀lú ọkàn tó tàsé

Aworan obinrin Bangladeshi, Monarani Das lẹyin iṣẹ abẹ

Oríṣun àwòrán, MANIPAL HOSPITAL BROADWAY

    • Author, Amitabha Bhattasali
    • Role, BBC News Bangla
    • Author, Ahmen Khawaja
    • Role, BBC World Service
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Nigba ti Monarani Das lati Bangladesh bẹrẹ si ni irora ni apa ọtun ti aya rẹ ni ọdun meji sẹyin, awọn mọlẹbi rẹ rẹ ro pe aya lasan lo n dun.

Wọn ko mọ pe ẹni ọdun mejilelaadọta ti wa nipo kan to ṣọwọn ati pe yoo jẹ ki o rin irin-ajo lati orilẹ-ede rẹ lọ si India fun itọju.

Ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu BBC Bangla, Ms Das ranti bi awọn ami aisan rẹ ṣe bẹrẹ.

O sọ pe: “Awọn ọjọ kan lẹyin ìrora ni apa ọtun aya mi, mo ni iṣoro mími.”

Laipẹ, o ni ikọlu ọkan. Lasiko to n gba itọju lọwọ ni awọn dokita ri p nnkan da yatọ lara rẹ, paapa ọkan rẹ.

Ms Das sọ pe: “Awọn dokita ri i pe ọkan mi wa ni apa ọtun aya.

Awọn dokita ni ilu abinibi rẹ ni guusu-iwọ-oorun Satkhira ṣe ayẹwo rẹ pẹlu aisan ọkan ti wọn n pe ni dextrocardia, nibi ti ọkan ti tọka si apa ọtun aya, dipo apa osi.

Yatọ si dextrocardia, Ms Das tun ni aisan mii “Situs inversus”, aisan miiran nibi ti awọn ẹya ara pataki ti ni iyipada lati awọn ipo to yẹ ki wọn wa.

Ẹdọ rẹ, ẹdọforo, Ọlọ, ati ikun ni wọn rii ni apa idakeji dipo apa ibi to yẹ ki wọn wa.

Iwadii fihan pe, dextrocardia le waye ni ẹẹkan ninu ẹgbẹrun mejila oyun.

Aworan alalaye

Oríṣun àwòrán, Others

Lẹyin ti wọn rii pe Ms Das ko ṣe dada, awọn ẹbi rẹ pinnu lati kan si onimọ ọkan ni ila-oorun ilu India niluu Kolkata.

Ọpọlọpọ awọn ara ilu Bangladesh gbagbọ pe eto ilera ni India dara. Ọpọ eeyan lo n lọ sibẹ fun itọju ni ọdọọdun, nitori naa idile Das pinnu lati mu Ms Das lọ si India.

Dokita Siddharth Mukherjee ti Ile-iwosan Manipal Broadway lo yọju si Ms Das, ẹni ti o ṣiṣẹ abẹ fun un ni Oṣu Karun ọdun yii.

Dokita Mukherjee sọ pe: “Ṣíṣe isẹ abẹ fun alaisan to ní dextrocardia jẹ ohun to ṣoro gan-an, torí pe ọwọ ọtun la saba maa n ṣiṣẹ si fun alaisan.

“Ninu yii, a ni lati ṣiṣẹ ni apa osi alaisan, eyi ti o jẹ tuntun, ṣugbọn ikọ wa ri daju pe wọn se isẹ abẹ naa.”

Iṣẹ abẹ naa lọ daradara, ati pe Ms Das ti pada si ile rẹ ni Bangladesh, ṣugbọn yoo pada si India laipẹ fun ayẹwo.

Ọkan sisun

Ara me riri to gba ori ayelujara kan ni ti ọkunrin kan ti wọn bi pẹlu ọkan rẹ to kọju si ọna alaafia, to si ma paarọ ipo rẹ lore kore lẹyin ọpọlọpọ ikọ.

Reza-ul Karim, ẹni ọdun mẹrindinlaadọrinwa lati West Bengal, ma ni iṣorọ mimi nigba to n dagba.

Ọgbẹni Karim sọ fun BBC Bangla pe: “Mo maa n ṣe ere idaraya nigba ti mo wa ni ọmọde, ṣugbọn nigba miiran, o nira fun mi, ti mo si ma hu ikọ pupọ.

O sọ pe: “Nigba to ya, Mo lọ sinu oṣelu fun ọdun marundinlọgbọn. Mo n sa kiri, mo ma n lọ ri dokita abẹle , ti mo si ma n lo awọn oogun to ba fun mi lorekore.”

Ṣugbọn ni ọdun diẹ sẹyin, Ọgbẹni Karim sọ pe o ko jafara bi ti tẹlẹ, to si n rẹ si ara, eyi to fa ti awọn ọmọ rẹ fi gbe wa si Kolkata lati wa ri dokita mi ile iwosn Medica Super Specialty Hospital.

Aworan Reza-ul Karim ni ile iwosanl

Oríṣun àwòrán, MEDICA SUPERSPECIALITY HOSPITAL

“N ko le mi daada, ti mo si ni lati tiraka dide lẹyin ti mo kunlẹ lasiko adura,” Ọgbẹni Karim sọ. "Mo daku nigba meji tabi mẹta nigba ti mo n gbadura."

Awọn dokita rii pe ọkan rẹ ti yipada lati apa osi lọ si apa ọtun lẹyin ti o ni ikọ-fèé nigba to wa ni ọmọde.

Wọn pinnu pe oun yoo nilo ṣe iranlọwọ fun ọkan rẹ lati ṣiṣẹ daradara ati lati se itọju ailemi rẹ.

Ni Oṣu Karun, Ọgbẹni Karim ati ẹbi rẹ ni wọn sọ fun pe yoo nilo “iṣẹ abẹ lẹsẹkẹsẹ” eyi to se pataki, laisi fifun alaye mii.

Lẹyìn iṣẹ abẹ fún wakati mẹta naa ni wọn sọ fun wọn irufẹ iṣẹ abẹ naa ati bi ko se wọpọ.

Iṣẹ abẹ pecemaker ni fifi ẹrọ kan ninu ọkan lati mojuto mimi, ti ko fi ni si aburu ati bi o ṣe lewu to.

Awoarn lati ibi iṣẹ abẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Dokita Dilip Kumar, ẹni to ṣiṣẹ abẹ lori Ọgbẹni Karim, sọ pe iṣẹ abẹ naa ṣọwọn nitori pe a maa n ṣe ẹrọ pace maker fun awọn ọkan to wa ni apa osi.

O sọ pe ẹgbẹ dokita ni lati lo ọna (CSP), eyi ti wọn ko tii lo fun ọkan ti o ni apa ọtun tẹlẹ.

Ọgbẹni Karim ti wa ni alaafia bayii lẹyin iṣẹ abẹ, ti yoo si tun yọju fun ayẹwo mii lati wo ilera rẹ. Dokita rẹ sọ pe ko ni awọn iṣoro mimi mọ ati pe o le gbadura ni irọrun – lai daku mọ!