Ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa abẹ́rẹ́ àjẹsára tó ń dènà àrùn Mpox

Aworan ẹni to n gba abẹrẹ ajẹsara

Oríṣun àwòrán, Getty image

Àkọlé àwòrán, Aworan ẹni to n gba abẹrẹ ajẹsara
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ibudo to n ri si idena ati gbigbe ogun ti itankalẹ aisan ni Europe, ti gba awọn arinrinajo nimọran,lati gba abẹrẹ ajẹsara to n dena arun Mpox bi wọn ba fẹẹ lọ si awọn ilẹ Afrika ti arun naa ti n jà lọwọ.

Ajọ eleto ilera agbaye, (WHO), sọ pe apa Ila-Oorun Afrika bii DR Congo, ti arun naa ti kọkọ ṣẹyọ, ati awọn miran bii Burundi, Kenya, Uganda ati Rwanda ti wọn ko ni arun naa tẹlẹ, ti kede ẹ laipẹ yii pe o ti ṣẹyọ nibẹ naa.

Bo tilẹ jẹ pe ko fi bẹẹ pọ.

Eeyan le ko arun yii lati ara ibalopọ pẹlu ẹni to ba ni Mpox.

Abẹ́rẹ̀ àjẹsára Mpox

Gẹgẹ bi alakalẹ ti ajọ WHO ati awọn mi-in fi ọwọ si, meji ni abẹrẹ ajẹsara yii.

Kokoro to n fa Mpox yii naa ni wọn lo n fa Smallpox, fun idi eyi, abẹrẹ meji ti wọn gbe kalẹ ọhun ti i ṣe JYNNEOS, n ṣiṣẹ fun awọn arun mejeeji yii.

Ibudo to n ri si itọju ati idena arun ni US, ṣalaye pe o yẹ ki awọn eeyan gba abẹrẹ meji yii, eyi ti ileeṣẹ apoogun Bavarian Nordic n ṣe jade.

Bi eeyan ba fẹẹ ri iṣẹ abẹrẹ yii daadaa bi wọn ṣe wi, eeyan gbọdọ gba abẹrẹ keji lẹyin ọsẹ kẹrin to gba ti akọkọ.

Ṣaa, ijọba Naijiria ko ti i kede ibudo itọju kankan ti eeyan ti le lọọ gba abẹrẹ ajẹsara yii, ṣugbọn bi eeyan ba le ba awọn dokita sọrọ, wọn le dari oluwarẹ sibi ti yoo ti ri i gba.

Àwọn nńkan tó lè ṣe ọ́ lẹ́yìn gbígba abẹ́rẹ́ àjẹsára Mpox

Gẹgẹ bo ṣe ri pẹlu awọn abẹrẹ ajẹsara mi-in naa, o ṣee ṣe ki eeyan ri awọn apẹẹrẹ wọnyi to ba gba abẹrẹ JYNNEOS.

*Ibi ti o gba abẹrẹ naa si le maa dun ọ. Ibẹ le pọn, o le wú, o si le maa yun ọ.

*Ara riro

*Irẹwẹsi

*O le maa ṣe ọ bii pe o fẹẹ bì.

*Iba

*Ẹfọri

*Otutu.

Awọn nnkan yii ṣee mojuto lai si wahala, iyẹn bi wọn ba ṣẹlẹ si ọ lẹyin abẹrẹ naa.

Ṣugbọn bi o ba gba a tan to si bẹrẹ si i ṣe ọ bii pe o ko le mí daadaa, tabi pe o fẹẹ ṣubu, abi èémi rẹ n lọ soke ju bo ṣe yẹ lọ, tete gba ileewosan lọ kiakia.

Awọn apẹẹrẹ mi-in ti o gbọdọ tete gba ileewosan lọ fun ni aya didun, eemi ti ko ṣe deede, tabi awọn inira mi-in to ba bẹrẹ si i ṣẹlẹ lara rẹ lẹyin abẹrẹ yii.