Ṣé lóòótọ́ ni pé Iléeṣẹ́ China ti dá ọkọ̀ òfurufú ààrẹ Nàìjíríà padà?

Oríṣun àwòrán, Others
Ileeṣẹ China to gbe orilẹede Naijiria lọ si ile ẹjọ ti da ọkọ ofurufu ijọba ti wọn gbẹsẹ le pada.
Gẹgẹ bii ileeṣẹ Reuters se gbe sita, Ileeṣẹ naa ninu atẹjade kan ti wọn fi lede lọjọ Ẹti ni awọn ti gba lati da ọkọ ofurufu ti ile ẹjọ Faranse gba lọwọ Naijiria.
Saaju ni ile ẹjọ kan lorilẹede Faranse gbe idajọ kalẹ, to si gbesẹ le ọkọ ofurufu mẹta eyi to jẹ ti orilẹede Naijiria lori adehun kan to wa laaarin ipinlẹ Ogun ati ileeṣẹ Zhongshan Fucheng Industrial Investment Co. Ltd
Lọjọ Ẹti, agbẹnusọ ileeṣẹ naa ba ileeṣẹ iroyin Premium Times sọrọ pe ijọba Naijiria kesi awọn pe Aarẹ Bola Tinubu nilo ọkan ninu ọkọ ofurufu naa lati rin irinajo lọ si orilẹede France fun ipade pẹlu Aarẹ France, Emmanuel Macron.
“Zhonshan ni oni iwa lori igbejọ to wa pẹlu Naijria.
“Wọn ti jẹ ka mọ bayii pe ọkọ ofurufu Airbus A330, eyi to wa ni orilẹede France nitori idajọ ile ẹjọ ni Aarẹ Naijiria nilo lati rin irinajo lọ ba Aarẹ Macron ni France lọsẹ to n bọ.
“Nitori iwa rere wa, Zhongshan ti gbe ẹsẹ kuro lori ọkọ ofurufu naa lẹsẹkesẹ. Eyi yoo fun aarẹ ni anfani lati rin irinajo rẹ.
“A si n ba awọn aṣoju Naijiria sọrọ lati ibi ti a yoo fi ọrọ to dawapọ gunlẹ si.”
Ileeṣẹ naa ko sọ ohunkohun nipa awọn ọkọ ofurufu meji yooku ati igba ti wọn yoo gbe ẹsẹ kuro lori wọn.
Ìròyìn tó wà nínú àṣẹ ilé-ẹjọ́ ti Paris tó ní kí wọ́n gba ọkọ̀ òfurufú ti ààrẹ Nàíjíríà ní France

Oríṣun àwòrán, Bola Tinubu/Getty Images/ Dapo Abiodun
Ijọba Naijiria ti sọ pe awọn ko ni ibaṣepọ pẹlu ileeṣẹ ilẹ China kankan ti yoo jẹ ki ile ẹjọ paṣẹ lati gba ọkọ ofurufu aarẹ ati lati tun gba awọn dukia to wa lorileede France.
Gẹgẹ bi ileeṣẹ aarẹ ṣe ṣalaye, ẹjọ naa wa laarin ileeṣẹ ilẹ China kan ti wọn pe ni Zhongshan Fucheng Industrial Investment Co. Limited ati ijọba ipinlẹ Ogun.
Esi yii lo waye lẹyin ti ileeṣẹ China naa ti sọ pe ọkọ ofurufu naa wa lara eyi ti ile ẹjọ Paris paṣẹ pe ki wọn fofin gba, lẹyin ti adehun to wa laarin ileeṣẹ naa ati ijọba ipinlẹ Ogun fori ṣanpọn.
Kini Bayo Onanuga sọ lori ọrọ yii?
Gẹgẹ bi Bayo Onanuga to jẹ oludamọran pataki lori eto iroyin fun aarẹ ṣe ṣalaye pe ileeṣẹ China naa n wa ọna ti ko tọ lati fi gba ohun ti kii ṣe ti wọn loke okun nipa iwa magomago.
“Ijọba apapọ ko si labẹ adehun kankan pẹlu ileeṣẹ naa.
Ẹjọ ti ileeṣẹ Zhongshan n gbiyanju lati lo, lati fi wa ọna alumọkọrọyi gba dukia ijọba Naijiria lo wa laarin ohun ati ijọba ipinlẹ Ogun,” ọrọ yii ni Onanuga sọ ninu atẹjade to fi sita.
Ijọba apapọ sọ pe awọn mọ nipa gbogbo igbiyanju ijọba ipinlẹ Ogun lati yanju ọrọ naa ni tubi-inubi.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Bi ọrọ to wa laarin ijọba ipinlẹ Ogun ati ileeṣẹ Zhongshan Fucheng ṣe bẹrẹ rèé.....
Gẹgẹ bi ileeṣẹ aarẹ ṣe ṣalaye bi ọrọ ọhun ṣe bẹrẹ, wọn ni iwe adehun lati ṣagbekalẹ agbegbe lati ṣe okoowo ọfẹ (free-trade zone) lo da wahala silẹ, to si jẹ ki wọn maa wa ọna lati gbẹsẹ le ọkọ ofurufu ijọba Naijiria.
“Iwe adehun kan to wa laarin ijọba ipinlẹ Ogun ati ileeṣẹ Zhongshan lati ṣagbekalẹ agbegbe okoowo ọfẹ lo ti wa nilẹ lati ọdun 2007.
Ọdun 2015 ni wọn tọwọ bọwe adehun, ti wọn si ti n gbiyanju lati yanju rẹ lati ọdun 2016.
Nigba ti yoo di ọdun 2019, igbẹjọ lojuna lati yanju isẹlẹ naa ti pari. Igbimọ olugbẹjọ naa ti paṣẹ pe ki ijọba Naijiria san ọgọta miliọnu owo dọla ($60m) ti wọn jẹ olujẹjọ keji san, nigba to jẹ pe ohun kan ṣoṣo ti ileeṣẹ Zhongshan ti ṣe ni fẹnsi yika agbegbe ti wọn ya sọtọ fun okoowo ọfẹ naa.
Won tun salaye pe....
“Nitori amọran ofin, ijọba ipinlẹ Ogun ti kọ igbesẹ lati san owo naa. Igbesẹ lati ma ṣe gba aṣẹ naa ṣiṣẹ pẹlu igbimọ ofin meje ọtọọtọ.
Bakan naa tun ni ipinnu ẹjọ kotẹmilọrun lori iṣẹlẹ yii tun ti wa ni ilẹ Amẹrika ati Gẹẹsi.
“Ijọba ipinlẹ Ogun tun ti n gbiyanju lati ba Zhongshan sọrọ lati sọrọ tubi-inubi. Ipade to kẹyin lo waye niluu London loṣu kẹsan, ọdun 2023, ti wọn si fi ọjọ mẹta gbako sọrọ, to fi jẹ pe ọpọ awọn alẹnulọrọ nipinlẹ Ogun, to fi mọ Gomina Dapọ Abiọdun ati adajọ agba ilẹ Naijiriai, Ọmọọba Lateef Fagbemi.
“Ileeṣẹ Zhongshan ti kọkọ gba ohun ti ipinlẹ Ogun n fẹ, ṣugbọn ti wọn tun yi ipunnu wọn pada lọjọ keji, ti wọn si duro lori wi pe ki ijọba ipinlẹ Ogun san gbogbo owo naa, lati le jẹ ki wọn yanju re sibẹ.
Eyi lo si fa ki ipade ọhun fori ṣanpọn, ti wọn si fi ipade miran si saa akọkọ ninu yii (2024).
Latigba naa, Zhongshan ti kuro. Ati pe niṣe ni wọn bẹrẹ igbesẹ lati bẹrẹ sii lo aṣẹ, eyi ti igbimọ amofin ijọba apapọ ati ipinlẹ Ogun bori.
“Ipinlẹ Ogun ko rẹwẹsi lati wa ọna lati yanju ọrọ naa ni tubi-inubi, pẹlu lẹta ti wọn kọ ranṣẹ lọsẹ to kọja. Zhongshan dahun lẹyin ti wọn gba aṣẹ ti ko ba ofin mu naa.”
Eyi ni ohun ti ileeṣẹ aarẹ sọ pe o fa aawọ laarin ijọba ipinlẹ Ogun ati ijọba ilẹ China.
Ki ni ijọba ipinlẹ Ogun sọ lori ohun to ṣẹlẹ?
Ijọba ipinlẹ Ogun naa ti sọrọ lori bi wọn ṣe gbesẹ le ọkọ ofurufu ileeṣẹ aarẹ gẹgẹ bi ọkan lara awọn dukia ti ileeṣẹ ilẹ China fi sinu ohun beere fun lati gba.
Ninu atẹjade ti Ọnarebu Kayode Akinmade to jẹ oludamọran pataki fun gomina lori eto iroyin, ijọba ipinlẹ Ogun sọ pe ileeṣẹ Zhongshan gba aṣẹ ile ẹjọ lai fi to ijọba apapọ Naijiria, ijọba ipinlẹ Ogun ati igbimọ amofin leti.
“Ipinlẹ Ogun gbọ nipa idajọ ile-ẹjọ Paris ti ọjọ keje, oṣu Kẹta ati ọjọ kejila, oṣu Kẹjọ, ọdun 2024, eyi ti wọn ko fi to ijọba apapọ Naijiria, ijọba ipinlẹ Ogun ati igbimọ eleto ofin.
Eyi ni iroyin tuntun nipa igbesẹ ti ko yẹ, eyi ti Zhongshan n wa ọna lati lọ dukia ijọba papọ mọ igbesẹ lati gba owo lọwọ Naijiria.
“Eyikeyi ninu ọkọ ofurufu tabi dukia ijọba to duro fun aami idanimọ ko le si ninu ohun ti wọn le fi kọ ẹjọ lọrun ninu ofin agbaye tabi ti ilẹ French. Zhongshan mọ-ọn-mọ tọju iroyin fun ijọba Naijiria, ipinlẹ Ogun ati igbimọ amofin,” eyi lo wa ninu ohun ti ijọba ipinlẹ Ogun sọ.
Ipinlẹ Ogun sọ pe awọn ti n gbiyanju lati sọrọ pẹlu ijọba apapọ lati wa ọna abayọ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2















