Lẹ́yin ìwọ́de ebi ń pa wá, Ganduje ní kí ìjọba ṣè ìwadìí Abbar Kabir

Aworan Umar Ganduje ati Gomina Abba Kabir Yusuf ti ipinlẹ Kano.

Oríṣun àwòrán, FB/Multiple

Àkọlé àwòrán, Aworan Umar Ganduje ati Gomina Abba Kabir Yusuf ti ipinlẹ Kano.
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Gomina tẹlẹ ni ipinlẹ Kano, Abdullahi Umar Ganduje,ti kesi ijọba apapọ Naijiria lati ṣewadii Abba Kabir Yusuf ti i ṣe gomina ipinlẹ naa lọwọlọwọ.

Ipe yii n waye latari ipa ti Ganduje sọ pe gomina Abba Kabir ko,ninu rogbodiyan to waye lasiko iwọde ebi n pa wa, to ṣẹlẹ nibẹrẹ oṣu kẹjọ 2024.

Ipinlẹ Kano jẹ ọkan ninu awọn ipinlẹ ti rogbodiyan ti lagbara lasiko ifẹhonuhan naa, ẹmi ati dukia si ṣofo pẹlu.

" O yẹ ki ijọba apapọ ṣewadii ijọba ipinlẹ Kano, nitori gbogbo eeyan lo mọ pe ki iwọde too waye rara, Gomina ipinlẹ Kano, Abba Kabir Yusuf, sọ awọn ọrọ to tako ilana ti awọn gomina ipinlẹ yoku gbe kalẹ.’’

Agbẹnusọ Ganduje, Edwin Olofu, lo sọ eyi di mimọ ninu atẹjade to fi sita l’Ọjọbọ,lorukọ gomina Kano tẹlẹ naa.

Lati igba ti ijọba Abba Yusuf ti de ori aleefa ni aarin oun ati Ganduje to gba ipo lọwọ rẹ ko ti i dan an mọran.

Kí ló ti ṣẹlẹ̀ ṣíwájú?

Ẹ o ranti pe iṣakoso Gomina Abba Yusuf lo kọkọ fi ẹsun kan Ganduje lori ifẹhonuhan to waye laipẹ naa.

Ijọba tuntun to wa lori aleefa ni Kano bayii, fi ẹsun kan Ganduje, pe oun lo ran awọn janduku to sọ iwọde naa di wahala niṣẹ.

Wọn ni gomina tẹlẹ yii lo ran awọn janduku lati kọlu kootu, ti wọn si ji awọn iwe pataki lọ.

Lara iwe ti Gomina Abba Yusuf sọ pe awọn janduku naa ko ni iwe ẹsun igbẹjọ Ganduje funra rẹ.

Bakan naa ni wọn n fi ẹsun kan iyawo Ganduje, Hafsat, ọmọ rẹ ọkunrin; Umar ati awọn meji kan, pe wọn ji biliọnu ipinlẹ Kano ko lasiko ijọba wọn.

Atẹjade ti agbẹnusọ GominaAbba Yusuf, Sanusi Bature Dawakin Tofa, fi sita l’Ọjọru, ọjọ kẹrinla,oṣu kẹjọ 2024 yii ni wọn ti sọ pe,’’gbogbo eeyan lo ti ri i bi awọn eeyan Ganduje ṣe pin nnkan ija oloro, owo ati ọti fun awọn ọdọ lati kọlu ọpọlọpọ agbegbe, to fa ofo ẹmi ati dukia.’’

Eyi ni Ganduje fesi si ninu atẹjade tiẹ, pe ai kunju oṣunwọn ijọba Abba Kabir lo jẹ ki iwe pataki sọnu ni kootu.