Àwíjàre Gbenga Daniel àti Ibikunle Amosun lórí ọkọ̀ òfúrufú Naijiria tí China gbẹ́ṣẹ̀ lé

Oríṣun àwòrán, Seneto Ibikunle Amosun/Otunba Gbenga Daniel
Awọn gomina tẹlẹ ri nipinlẹ Ogun, Ọtunba Gbenga Daniel ati Sẹnetọ Ibikunle Amosun, ti sọrọ nipa adehun to wa laarin ileeṣẹ orileede China, ipinlẹ Ogun ati ijọba apapọ Naijiria.
Ọtunba Gbenga Daniel (OGD), to ṣagbekalẹ erongba agbegbe okoowo ọfẹ, Free Trade Zone, ni 2007, nipinlẹ Ogun, sọ ohun to mọ nipa ibudo to mu ki China gbẹsẹle ọkọ ofurufu Naijiria mẹta yii.
OGD sọ pe oun fẹ ki araalu mọ pe ohun to wa nile ẹjọ, ni dida iwe adehun naa ni, eyi ti ijọba to gun ori aleefa lẹyin oun ko tẹwọ gba, ti ko si buwọ lu iwe adehun naa.
O ṣalaye pe ohun idanimọ orileede yii ni a n sọrọ nipa rẹ, o si yẹ ko jẹ nnkan ti araalu yoo da si lati wa ọna abayọ.
OGD rọ awọn eeyan lati yee sọ ohun ti oju wọn ko to lori ayelujara ati ninu iwe iroyin, o si pe fun ifọwọsowọpọ ijọba apapọ pẹlu.
Ìdí tí mi ò ṣe gba ìwe àdéhùn náà nígbà tí mo jẹ gómìnà - Amosun

Oríṣun àwòrán, Amosun
Ninu atẹjade to fi sita lọjọ Abamẹta, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹjọ ọdun 2024, Sẹnetọ Ibikunle Amosun, gomina ana nipinlẹ Ogun, ṣalaye idi ti ko fi gba iwe adehun iṣakoso to ṣiwaju rẹ lori ọrọ yii nigba to de ijọba.
Amosun ni bi ijọba ṣe n tẹsiwaju loriṣiriṣi ọna lo ṣokunfa ohun to ṣẹlẹ ṣaaju, lasiko ati lẹyin iṣakoso oun.
O ni gbara toun de ipo gomina, ileeṣẹ Chinese meji ọtọọtọ, Messrs China Africa Investment FXE ati Zhongfu International Investment FXE, ni wọn sọ pe awọn ni iwe aṣẹ lati ṣakoso Ogun Guangdong Free Trade Zone (OGFTZ).
O ni ija to wa laarin awọn mejeeji yii bẹrẹ sii da wahala silẹ, paapaa lẹka okoowo ati idaṣẹsilẹ lagbegbe naa.
"’Zhongfu International Investment FXE n dá ọgbọ́n tiẹ, China Africa Investment FXE naa n ṣe tiwọn"
" Bi Zhongfu International Investment FXE ṣe n dọgbọn pe awọn ni ojulowo tẹnanti, ti wọn si n ko awọn atako ibanilorukọjẹ silẹ lati sọ pe awọn laṣẹ labẹ ofin, bẹẹ naa ni China Africa Investment FXE sọ pe awọn yoo gba awọn alabojuto fidihẹ-ẹ (Interim Zone Managers.)
"Nipasẹ ohun to tẹ wa lọwọ nigba naa, Zhongfu International Investment FXE ni wọn yan gẹgẹ bi alakoso fidihẹ-ẹ́ lọjọ kẹẹẹdogun, oṣu kẹta, ọdun 2012, titi digba ti wọn yoo pari agbeyẹwo agbegbe naa.
"Lẹyin o rẹyin la pada mọ pe gbogbo ẹri ti ileeṣẹ Zhongfu International Investment FXE ko kalẹ lati tako China Africa Investment FXE ki i ṣe otitọ, bi ko ṣe obitibiti irọ.
"Ijọba wa ko mọ tẹlẹ pe ileeṣẹ Zhongfu International Investment FXE n wa gbogbo ọna lati ba orukọ ati eto ọrọ aje China Africa Investment FXE jẹ lasan ni, lati le gba gbogbo ẹtọ Guangdong Province ni China.
"A tun pada ri i pe ijọba ilẹ China, nipa Diplomatic Note 1601 to jade lọjọ kọkanla, oṣu kẹta, ọdun 2016, fidi rẹ mulẹ fun ijọba ipinlẹ Ogun, pe China Africa Investment FXE ni ojulowo awọn to ni iwe aṣẹ.
‘’Lẹyin ijororo to pọ, a gbe aṣẹ naa silẹ gẹgẹ bi ijọba China ṣe beere fun un.
"A ranti pe Zhongfu International Investment FXE lọ sawọn ile ẹjọ ni Naijiria loriṣiriṣi lati le gba iwe idajọ nipa akoso agbegbe ọhun. Gbogbo ẹjọ mẹrin naa ni wọn padanu.
"A tun tọ awọn ileeṣẹ aabo State Security Services ati ileeṣẹ NEPZA lọ lati gba amọran lori ohun ti a le ṣe. Lẹyin rẹ la fun ileese Zhongfu International Investment FXE niwe pe a ko le ba wọn ṣiṣẹ lọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu karun, ọdun 2016.
"O tun ya wa lẹnu pe Zhongfu International Investment FXE tun gba ile ẹjọ lọ.
Sẹnetọ Amosun sọ pe oun ṣiṣẹ lati ri i pe ohun gbogbo pada bọ sipo koun too kuro nijọba loṣu karun, ọdun 2019.














