A kò rán Yomi Fabiyi níṣẹ́ láti ṣe ayẹyẹ ọdún kan ikú Mohbad - Mọ́lẹ̀bi ṣèkìlọ̀

Aworan Mohbad ati Yomi Fabiyi

Oríṣun àwòrán, Mohbad/Screenshot ati Yomi Fabiyi/Facebook

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Ẹbi gbajugbaju onkọrin takasufe nni, ti iku rẹ ṣi n fa awuyewuye titi di asiko yii, Ilerioluwa Aloba ti ọpọ mọ si Mohbad ti sọ pe awọn ko ran ilu mọ-ọn-ka oṣere tiata nni, Yomi Fabiyi niṣe igbesẹ to fẹẹ gbe.

Wọn ni awọn ko le faaye gba awọn iwa ti ko ba ofin mu, nitori pe idajọ ododo ni awọn n fẹ lori iku ọmọ wọn to ku lai tọjọ.

Ni nnkan bi agogo marun ku iṣẹju mẹtadinlọgbọn irọlẹ Ọjọru, ọsẹ yii ni Yobi Fabiyi kede loju opo Facebook rẹ, nibi to ti n pe awọn eeyan jakejado agbaye lati jade fun iwọde ọdun iku Mohbad.

Yomi Fabiyi kọ ọ sibẹ pe “lọjọ Ẹti, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹjọ, ọdun ti a wa yii, gbogbo awọn to n fẹ idajọ ododo lori iku Mohbad yoo korajọ niwaju ile-ẹjọ Corona Inquest to wa niluu Ikorodu, ipinlẹ Eko, ati awọn ijokoo yooku.”

O sọ pe awọn yoo tẹsiwaju lati fi ifẹ akikanju ati atilẹyin wa han fun idajọ ododo lori ohun to ṣokunfa iku Mohbad; beere fun ẹkunrẹrẹ iwadii, idajọ ati igbẹjọ ti ko falẹ, gbigba gbogbo ‘estate’ to jẹ tiẹ fun mọlẹbi rẹ.

Bakan naa ni Fabiyi tun sọ pe “L’ọjọ kejila, oṣu Kẹsan, ọdun yii ti yoo jẹ ayẹyẹ ọdun, a maa yoo rin irin iranti, ti a si tun maa korajọ kaakiri agbaye lati bu ọla fun olorin to doloogbeohun, lati ṣe ẹyẹ fun un nipa ẹdun ọkan wa.”

O wa kadi ọrọ rẹ nilẹ wi pe aṣọ dudu ati aṣọ ikọpa funfun lawọn yoo lo lọjọ naa.

Ṣugbọn agbẹjọro mọlẹbi oloogbe naa, Monisola Odumosu fi sita, o ni awọn ko faaye gba ikorajọpọ layika ile-ẹjọ lasiko ti igbẹjọ ba n lọ lọwọ, lati le gba laafia ile-ẹjọ laaye.

“Ẹnikẹni lo lẹtọọ lati ṣe ohun to ba wu, niwọn igba ti wọn ba ṣee lọna to ba ofin mu. Iwe ofin ilẹ wa faaye gba gbogbo eeyan lati fi ẹdun ọkan wọn han,” Odunmosu ninu atẹjade to fi sita lo ti sọ eyi.

O tẹsiwaju pe “Ṣugbọn ṣa, wiwa si ile-ẹjọ lati wa ṣe nnkan wọnyi ni yoo tun jẹ iṣoro miran. Wọn ko gbọdọ pariwo. Ẹnikẹni ko gbọdọ di iṣẹ ile-ẹjọ lọwọ ni eyikeyi iwa. Bi bẹẹkọ, ẹni naa jẹbi ẹsun titapa fi ofin ile-ẹjọ.

“Amọran wa ni pe wọn ko gbọdọ di igbẹjọ ile-ẹjọ lọwọ ni eyikeyi igbesẹ ti wọn ba fẹẹ gbe lati ṣe ojuṣe wọn labẹ ofin.”

Kí ló mú mọ̀lẹ́bí yarí lórí ṣíṣe ayẹyẹ ìrántí ọdún kan ikú Mohbad?

Mohbad

Oríṣun àwòrán, Mohbad/Instagram

Awọn mọlẹbi onkọrin to ti doloogbe nni, Ilerioluwa Oladimeji Aloba ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Mohbad, ti sọ pe awọn ko nii gba k'ẹnikẹni ṣagbekalẹ eto iranti ọmọ wọn.

Wọn ni ki ẹnikẹni tabi ẹgbẹkẹgbẹ to ba n palẹmọ lati ṣeto iranti Mohbad fopin sii.

Atẹjade ti awọn agbẹjọro mọlẹbi oloogbe naa, Monisola Odumosu, fi sita lọjọ Aje to kọja fidi ikede naa mulẹ.

Mọlẹbi naa sọ pe awọn fẹ ṣeto iranti ọmọ wọn pẹlu alaafia lai ṣee ni alariwo, ko ma baa tun mu wọn ronu.

"Ẹ so ayẹyẹ iranti ọdun kan iku Mohbad rọ na, ẹ ma fi orukọ ọmọ wa pawo sapo ara yin, a ko tii sinku rẹ"

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Atẹjade naa ni “O ti de etigbọ mọlẹbi Aloba wi pe awọn ẹgbẹ kan n palẹmọ fun eto iranti ọdun kan iku ọmọ wa, Ilerioluwa Oladimeji Aloba (Mohbad), onkọrin to doloogbe.

Mọlẹbi Aloba wa n rọ gbogbo ẹgbẹ tabi ajọ to n gbero naa lati so ayẹyẹ iranti ọdun kan ọhun rọ na tori wọn ko tii sinku olorin oloogbe naa.

Fun idi eyi, mọlẹbi n rọ gbogbo eeyan lati pawọpọ pẹlu wa ninu adura nibi eto iranti, dipo ki wọn pe apejọ nla to maa mu wọn ronu.”

Awọn mọlẹbi naa tun fi erongba wọn han wi pe awọn kan ati awọn ẹgbẹ kan n gbero lati fi eto iranti iku Mohbad pawo sapo ara wọn.

Eyi ni wọn fi n sọ pe ki ẹnikẹni to ba fẹ ṣagbekalẹ eto iranti naa wa gba aṣẹ lọdọ mọlẹbi, ko to di pe wọn tẹsiwaju.

“Kii ṣe iroyin mọ pe awọn mọlẹbi kan ati awọn ẹgbẹ kan n palẹmọ lati gbe eto iranti iku Mohbad.

“A maa rọ awọn eeyan ati ẹgbẹ naa lati gba aṣẹ to tọ lọwọ mọlẹbi ko to di pe wọn gbe eto ọhun kalẹ.

Mọlẹbi Aloba ko nii fẹ ki ẹnikẹni lo orukọ oloogbe naa lati fi pa owo sapo ara wọn n,” atẹjade naa ṣalaye.

Bakan naa ni wọn rọ awọn eeyan naa lati tẹle erongba ati ifẹ mọlẹbi nipa didarapọ mọ wọn ninu adura lasiko ti nnkan ko rọrun yii.

Ta ni Mohbad to jade laye lọdun 2023?

Gbajumọ akrin takansufe ni Ilerioluwa Aloba ti ọpọ eeyan n pe ni Mohbad.

Ọjọ kejila, oṣu kẹsan ni Mohbad, to jẹ ọkan lara awọn akọrin ileeṣẹ Marlian Music to jẹ ti Naira Marley, jade laye.

Ọdun mẹtadinlọgbọn ni oloogbe naa lo loke eepẹ, ti iku rẹ si fa awuyewuye lori ayelujara.

Iku rẹ si ti fa ki wọn fi ofin gbe Naira Marley ti oun naa jẹ akọrin takansufe ati oludari ileesẹ Malian Music.

Bakan naa, wọn tun gbe eekan alaẹ kan nilu Eko, Balogun Eletu ti ọpọ mọ si Sam Larry ati awọn miran.

Ẹsun ti wọn fi kan wọn ni pe wọn dunkoko mọ oloogbe naa nigba aye rẹ amọ ti ileẹjọ gba oniduro wọn.

Bakan naa ni wọn gbe ọrẹ timọtimọ Mohbad, PrimeBoy lori iku akọrin naa.

Ọjọ kọkanlelogun, oṣu kẹsan, odun 2023 ni wọn wu oku rẹ lati ṣayẹwo oku (autopsy) lati mọ iru iku to pa a.

Benjamin Hundeyin to jẹ agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ Eko ninu oṣu kẹsan, ọdun 2023 sọ pe wọn ti pari ayẹwo naa, ati pe awọn n duro de esi ayẹwo.

Sugbọn lẹyin o rẹyin, wọn fi ikede sita pe ayẹwo ko le sọ ohun to gbẹmi Mohbad, amọ baba oloogbe naa ti lọtun ayẹwo miran se lati mọ iku to pa ọmọ rẹ.