Taliban yí òfin padà, ó ní ó lòdì sí òfin Sharia pé kí obìnrin ṣiṣẹ́ adájọ́ tábí kọ ọkọ sílẹ̀
- Author, Mamoon Durrani
- Role, BBC Afghan Service
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7

O ti to ọdun mẹta bayii ti Taliban ti gba agbara pada, ti wọn si ti yii ọpọ nnkan to jọ mọ ofin pada ni Afghanistan, eyi to n se akoba fun gbigbe to rọrun fun awọn araalu.
Ijọba Taliban ni eto ofin lorileede ko ki n se ti igbalode, ti wọn si n siṣẹ karakara lati yi awọn idajọ ti ile ẹjọ se saaju pada.
Awọn igbesẹ yii ni o ti jẹ ki ọpọ eeyan dide nitori ọpọ ẹjọ to ti di ohun igbagbe ni wọn n hu jade pada labẹ ofin Sharia, to si jẹ pe awọn obinrin ni gan an lo n jẹ irora igbesẹ yii ju.
Ijọba Taliban ni awọn iyawo ile kan ti ofin ti ni ki wọn kọ ọkọ silẹ ni wọn ni lati pada si igbeyawo naa pada ati pe gbogbo awọn Adajọ to jẹ obinrin ko ni anfani lati wa ni ẹka idajọ loriẹede naa.
“Awọn obinrin ko koju oṣu wọn to lati gbe idajọ kalẹ labẹ ofin Sharia, ẹka idajọ nilo awọn to ni ọgbọn ori nla.”
Taliban ni kawọn obinrin to ti gba asẹ nile ẹjọ lati kọ ọkọ wọn silẹ pada sile ọkọ ti wọn kọ silẹ
Lẹyin ọjọ mẹwaa ti Taliban pada si ijọba ni Bibi Nazdana, ẹni ogun ọdun to n ran iya rẹ lọwọ ni ile idana, nigba ti Baba rẹ wọle.
Oju baba rẹ kọrẹlọwọ, o sunmọ wọn lati mọ ohun ti baba n ba ẹgbọn rẹ ọkunrin sọ.
“Nigba ti mo gbọ orukọ mi, aya mi bẹrẹ si ni ma ja, ti mo si bu si ẹkun,” Nazdana sọ
Ile ẹjọ Taliban ni agbegbe rẹ ni Uruzgan ti gbe ẹjọ rẹ pada sita.
Wọn ransẹ pe ko wa wi tẹnu rẹ lori ẹjọ kikọ ọkọ ti ko hu lati fẹ, to gbe wa si ile ẹjọ.
Nigba ti Nazdana wa ni ọmọ ọdun meje, baba rẹ gba lati fi fun ọkọ lati fi pẹtu si ija mọlẹbi kan.
Igbeyawo to buru ni ’eyi to n sọ ọta mọlẹbi di ọrẹ’
Bi Nazdana se pe ọmọ ọdun mẹdogun ni Hakmatullah wa mu iyawo rẹ lọ si ile. Sugbọn Nazdana pe ẹjọ lati lodi si fifẹ ọkọ rẹ, to si bori ilẹ ẹjọ.
“Mo sọ fun ile ẹjọ pe ko wu mi lati fẹ arakunrin naa,”

Ikọ Taliban ni ofin Sharia ko gba obinrin laaye lati wa ro tẹnu rẹ nile ẹjọ
“Lẹyin ọdun meji ti a fi ja, mo bori ẹjọ naa.
Ile ẹjọ ki mi ku orire, ti wọn si sọ fun mi pe mo ti gba ominira mi, ti mo si le fẹ ẹni to ba wu mi,”
Lati fi bi inu wọn se dun to han sita, wọn se ayẹyẹ diẹ, ti wọn si pin ounjẹ fun ọrẹ ati awọn eeyan ni agbegbe wọn ni mọṣalasi.
Sugbọn lẹyin ọdun kan, Taliban gba agbara , ti wọn si gbe ofin Sharia kalẹ fun gbogbo ilu.
Ọkọ rẹ ana, ẹni to ṣẹṣẹ darapọ mọ ikọ Taliban, sọ fun ile ẹjọ pe ki wọn wọgile idajọ tu igbeywo rẹ ka.
Lọtẹ yii, Nazdana ko ni anfani lati wa nibi igbẹjọ naa, gẹgẹ bi ofin sharia ṣe gbe kalẹ.
“Ile ẹjọ Taliban sọ fun mi pe n ko le pada si ile ẹjọ nitori o lodi si ofin Sharia. Wọn ni ki ẹgbọn mi wa soju mi.
“Wọn sọ fun wa pe ti a ko gba lati foju han, wọn yoo da Nazdana pada si ọdọ ọkọ rẹ, Shams Nazdana, ẹni ọdun mejidinlọgbọn ṣalaye.
Pẹlu bi Shams ṣe rawọ ẹbẹ si Adajọ pe idajo tuntun le gba ẹmi aburo rẹ, ile ẹjọ wọgile idajọ rẹ tẹlẹ, to si ni ki Nazdana pada si ile ọkọ rẹ.
Nazdana ti gbe ẹjọ naa lọ ile ẹjọ kotẹmilọrun lati fi gba akoko ti yoo nilo lati saa kuro lorilẹede naa. Pẹlu ẹgbọn rẹ, o fẹ saa lọ si ilu to wa ni tosi.

“Ile ẹjọ dajọ pe asẹ ileejọ lati tu igbeyawo ka, ko ba ofin Sharia mu nipa igbeyawo mu"
Adajọ Uruzgan ko gba lati ba awọn akọroyin sọrọ, ẹwẹ a gbiyanju lati de ile ẹjọ giga Taliban to wa ni olu ilu Kabul lati wa idahun si ibeere.
“Awọn adajọ n se iwadii wọn daadaa, ti wọn si gbe idajọ kalẹ eyi to fi si ọdọ Hekmatullah,” eyi ni ọrọ Abdulwahid Haqani, agbẹnusọ ilẹejọ giga ṣalaye.
“Idajọ ile ẹjọ lati tu igbeyawo naa ka ni ko ba ofin Sharia mu nipa igbeyawo. Nitori akoko ti igbejọ naa ni Nazdana ko fi le farahan.
A gbiyanju lati kan si Hekmatullah sugbọn o ri lati le ba sọrọ.
Ohun to ṣẹlẹ si Nazdana ni ọ jẹ ọkan ninu ọpọlọpọ ẹjọ ti ijọba Taliban ti ro pe awọn ti yanju sugbọn ti wọn hu sita lẹyin ti wọn gba ijọba ni oṣu kẹjọ ọdun 2021
Ijọba Taliban ni ọpọ ẹjọ ti awọn hu sita lo jẹ ẹjọ to dirọ mọ iwa ọdaran, ida ogoji da lori ija ilẹ, ti ida ọgbọn si jẹ nipa titu igbayawo ka.
A ko fi idi awọn ida yii mulẹ.
Taliban le awọn adajọ to jẹ obinrin, wọn ni Sharia ko gba obinrin laaye lati wa ni ẹka eto idajọ
Nigba ti Taliban pada si ijọba, wọn se ileri pe ko ni hu iwa ibajẹ ijọba to kogba wọle, ti awọn yoo si ri pe ijọba ododo waye ni orekoore.
Wọn ti le gbogbo awọn adajọ, ti wọn si jẹ ko di mimọ pe awọn obinrin ko anfani lati wa lara ẹka idajọ.
“Awọn obinrin ko koju oṣu wọn lati gbe idajọ kalẹ nitori ofin sharia, ẹka ile ẹjọ nilom lati sisẹ pẹlu awọn eeyan to ni oye,” Abdulrahman Rashidi ṣalaye.
Adajọ tẹlẹ ni ile ẹjọ giga, Fawzia Amini jẹ ọkan lara adajọ to jẹ obinrin ti Taliban yoo kuro. O ni awọn obinrin bi Bibi Nazdana lo yẹ ki ofin dabobo
“Ti obinrin ba kọ ọkọ silẹ, ti ẹri si wa, ko si igbẹjọ to le yi pada nitori ijọba yipada.
Amini tun sọ pe yiyọ awọn obinrin kuro ni ẹka ijọba tunmọ si pe obinrin ko idabobo kan.
“A n ko ipa to se pataki. Fun apẹẹrẹ ofin pe wọn ko gbọdọ se ikọlu si obinrin ti a se ni ọdun 2009 jẹ aṣeyọri nla. A tun ti sisẹ lori awọn ofin to dabo bo obinrin, ọmọ orukan.
Lẹyin ọpọ ọdun to ti fi sisẹ, Adajọ Amini ni o ni lati kuro lorilẹede. Nigba ti Taliban gba ijọba, o ni o n bẹrẹ si ni ma gba
Ijọba Taliban ni ijọba to kogba wọle ko ni oye to tọ nipa ẹṣin Islam lati fi tukọ ilu.

"Awọn adajọ tẹlẹ ninu ijọba to kogba wọle ko tẹle ofin Sharia ninu idajọ wọn sugbọn Sharia la n lo bayii"
Ni ile ẹjọ to ga ju, wọn fi yara kan han wa nibi ti wọn ko iwe ẹjọ si, nibi awọn oṣisẹ ijọba ati ti isin yii ti n sisẹ.
Wọn ni pupọ awọn iwe ẹjọ yii lo waye lasiko ijọba to kogba wọle , ti awọn si ti gbe sita lẹyin ọpọ eeyan mu ẹjọ wa ba awọn.
“Awọn adajọ ti tẹlẹ ko tẹle ofin Islam ninu idajọ wọn sugbọn bayii ofin Sharia ni a n lo, “ Abdulrahim Rashid.

“N ko ni ominira gẹgẹ bii obinrin?”
Lati igba to ti saa kuro lọ orilẹede to wa ni tọsi, Mazdana ti lo ọdun kan lati wa ni abẹ igi, labẹ ibi kan to wa ni aarin ọna.
O joko sibẹ pẹlu awọn iwe kan to fi han pe o jẹ olominira obinrin.
“Mo ti kan ọpọ ilẹkun ti mo n bere fun iranlọwọ, paapa ni ọdọ ajọ agbaye UN sugbọn ko si ẹni to gbọ ohun mi. Nibo ni iranlọwọ wa? N ko le ni ominira gẹgẹ bii obinrin?















