Kí ló dé tí Ẹrọ Arike, gbajúmọ̀ oníṣòwò, ṣe ń yíra mọ́lẹ̀ torí ipò Alága ìjọba ìbílẹ̀ l‘Osun?

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Gbajugbaja obinrin oniṣowo nipinlẹ Osun ni Abilekọ Falilat Oyetunji ti ọpọ eeyan mọ si Ẹrọ Arike.
Bi iya naa ṣe ti pẹ ninu iṣẹ iṣegun lo tun jẹ gbajumọ laarin awọn ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Osun.
Bakan naa si ni ọkọ rẹ, Alaaji Akeem Oyetunji, naa jẹ eekan ninu ẹgbẹ PDP nipinlẹ Osun kan naa.
Sugbon lọsẹ to koja yii, awọn fidio kan jade sori ayelujara, nibi ti Ẹrọ Arike ti n fi ẹsun kan Alaga ẹgbẹ PDP Osun, Ọnarebu Sunday Bisi.
Ninu fidio naa ni Ẹrọ Arike ti ṣalaye pe Alaga PDP ati Yeyeluwa, Modupeola Sanni, ṣeleri lati fun ọkọ oun ni ipo alaga ijọba ibilẹ Boripẹ, iyẹn lẹyin awọn iṣẹ nla-nla toun ti ṣe ni Iragbiji ati agbegbe rẹ.
O ni wọn fẹẹ fi ipo naa san ọkọ oun lẹsan iṣẹ idagbasoke ilu ti oun fi owo ara oun ṣe lagbegbe Iragbiji ni.
Ẹrọ Arike sọ pe ẹrọ loun n ta, ọkọ oun si jẹ eekan ninu oloṣelu Osun, nitori ẹ loun ṣe ni ki wọn gbe ipo naa fun un.
O ni ṣugbọn niṣe ni wọn gbe ipo naa fun ẹlomiran lẹyin gbogbo idaamu oun, eyi lo fa a ti iya naa fi n gbera yilẹ ninu fidio to ṣe.
’’Ẹ gbà mí gbogbo Osun,ẹ má jẹ̀ kí wọ́n yan ọkọ mi jẹ lori iyansipo alaga ijọba ibilẹ’’

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Ninu fidio to kọkọ ṣafihan ẹhonu Ẹrọ Arike, ni obinrin naa ti wọ aṣọ alawọ elese aluko kan pẹlu ibori.
Bo ti n sunkun ninu fidio naa, lo n gbe ara rẹ yilẹ, to si n sọ pe,
‘’Wọn o ma gbọdọ yan ọkọ mi jẹ, Ọlọun ooo, ẹ gba mi o, gbogbo ipinlẹ Osun ẹ gba mi o, wọn ni ki n maa ṣiṣẹ, mo ti riṣẹ jẹ.
’’Gbogbo awọn eeyan pata n’Iragbiji, ẹyin mi ni wọn wa o, èrú ree o.
‘’Mo ti kuro ninu ẹgbẹ yin o, ẹyin lẹ le mi o, ẹ ṣeun, ohun to yẹ ki ẹ fi san an fun mi lẹ fi san yẹn. Ẹ tete wa solution ṣe si i ni o’’
Ẹrọ Arike ṣalaye nipa bi awon eeyan ṣe ti oun lẹyin lori ibo, ti oun pin ounjẹ ati owo.
O ni ki awọn Irunmọlẹ Osun dide o, wọn o gbọdọ yan ọkọ oun jẹ gbe o.’’

Oríṣun àwòrán, Screenshot
"Mo gbẹ kanga igbalode de adugbo Ọlọrunda, Pathfinder, Oke Abuja, Oke Iragbiji, Mọṣalaaṣi Nasfat, Agboole Ọlọyan ati agbegbe Ọtapete nilu Iragbiji lati seranwọ oselu"
Ninu fidio miran lẹyin ti akọkọ ni Ẹrọ Arike ti jokoo lori aga, to si bẹrẹ si i ṣalaye bi o ṣe fi owo ara rẹ ṣe awọn kanga igbalode (borehole) ati kanga gan-an si awọn agbegbe ni Iragbiji.
Ẹrọ Arike sọ ninu fidio naa pe,‘’gbogbo ibi ti mo gbẹ borehole de ni mo gbe rally de.
‘’Baba mi Chief of staff ati mama mi Yeyeluwa beere lọwọ mi pe ki ni mo fẹ, nigba ti wọn ri akitiyan mi.
‘’Mo sọ fun wọn pe ẹrọ ni mo n ta, ki wọn fun ọkọ mi to n ṣe oṣelu ni ipo alaga ijọba ibilẹ Boripe, wọn si kọ ọ silẹ, wọn lo ti di ṣiṣe naa niyẹn.
Ti mo ba purọ mọ wọn, ki Iṣẹda wọn jẹ mi niya’’
‘’A ti mura silẹ lati depo, a jọ ṣe swearing-in ni, ṣadeede ni wọn fi ẹlomi-in si i.
‘’Wọn ni mo n tara, mi o ṣe ni i tara, oloriburuku iyawo ni wọn yoo yan ọkọ rẹ jẹ ti ko ni i fi ẹhonu han.’’
Diẹ ninu awọn agbegbe ti Ẹrọ Arike sọ pe oun gbẹ borehole ati kanga de ni: Ọlọrunda, Pathfinder, Oke Abuja, Oke Iragbiji, Mọṣalaaṣi Nasfat, Agboole Ọlọyan ati agbegbe Ọtapete.
Àlàyé tí Alága ẹgbẹ oselu PDP Osun ṣe fún BBC Yoruba rèé lori ẹsun ti Ero Arike fi kan ẹgbẹ oselu naa
BBC Yoruba wa kan si alaga ijọba ibilẹ PDP nipinlẹ Osun, Ọnarebu Sunday Bisi, lati gbọ alaye rẹ lori awọn ẹsun iyanijẹ ti Ero Arike fi kan wọn.
Nigba to n ba wa sọrọ lori foonu, Bisi ni yoo dara ki Ero Arike lọ mu iwe ibi ti oun ti tọwọ bọ iwe adehun pẹlu rẹ tabi ti oun ti seleri l;ati yan ọkọ rẹ ni alaga Kansu.
"Ẹ ni ko mu ẹri wa, nibi ti mo ti sọ ọ, ti mo si tọwọ bọwe pe mo fẹẹ fun ẹnikan ni alaga.
‘’Ṣe wọn n pin alaga ni, ṣebi awọn araalu lo maa n mu ẹni to ba wu wọn.
‘’Ẹrọ Arike pẹlu ọkọ ẹ, ọmọ ẹgbẹ ni wọn, ipo oṣelu, ipo iṣejọba ti wọn maa n dibo yan, eeyan ki i ṣeleri ẹ fun eeyan.
‘’Ẹni ti wọn ba fẹẹ dibo fun maa n jade nipasẹ fifi ẹnuko nipa ẹni naa, tabi nipasẹ ibo abẹle ni ijọba ibilẹ wọn ni. Ko sẹni to ni agbara lati ṣeleri fun eeyan.
‘’Ẹgbẹ oṣelu awarawa ni PDP, a ki i fipa yan eeyan, awọn eeyan ni wọn maa n yan ẹni to ba wu wọn.
Ṣugbọn, bi mo ṣe sọ, eeyan wa ni Ẹrọ Arike, a ti n ba a sọrọ, a a dẹ maa ba a sọrọ lọ.’’

Oríṣun àwòrán, Ero Arike @Facebook
Iya daadaa ni Ẹrọ Arike l’Osun ati ninu ẹgbẹ oṣelu PDD amọ ọrọ yii ko kan ijọba Osun - Akọ̀wé ìròyìn Gómìnà
BBC Yoruba tun kan si Olawale Rasheed, tii se Akọwe iroyin fun Gomina ipinlẹ Osun, Ọmọọba Ademola Adeleke.
Nigba to n dahun si ọrọ yii, o sọ pe iya daadaa ni Ẹrọ Arike l’Osun ati ninu ẹgbẹ oṣelu PDP.
O ni bo tilẹ jẹ pe ọrọ yii ko kan ijọba, awọn ẹgbẹ PDP lo kan, ti wọn si n tẹle ilana ti wọn fi n yan eeyan sipo, sibẹ, o ni eeyan daadaa ni Ẹrọ Arikẹ, ko si ohun to le yi iyẹn pada.
‘’Gomina kọ lo n yanju ọrọ ẹgbẹ, ko si eyi to kan gomina nibẹ. Ọmọ ẹgbẹ to ba ni ẹhonu to fẹẹ fi han yoo sọ ọ laaarin ara wọn ni.
‘’Iya Ẹrọ Arike ti ẹ ri yẹn, iya daadaa ni. A ko le foju pa wọn rẹ’’
Bẹẹ ni Akọwe iroyin gomina Osun wi.
’’Ìwa àwọn olóṣèlú ni Ero Arike hù yẹn, ko si nnkan ti oloṣelu ko le fi wa agbara ati ipo.’’
Ṣugbọn ẹnikan to mọ bo ṣe n lọ nipa iṣẹlẹ yii to si jẹ oloṣelu, to ni ka fi orukọ bo oun laṣiri, ṣalaye pe iwa oloṣelu ni Ẹrọ Arike hu yẹn.
‘’Ti ẹ ba mọ nnkan ti wọn n pe ni oṣelu, ẹ maa mọ pe ko si nnkan ti oloṣelu ko le fi wa agbara ati ipo.
‘’Ti mo ba ri i pe wọn o fẹẹ mu mi fun ipo kan, mo le ko tọọgi ki n lọ lu awọn ti wọn o fẹẹ ki n debẹ.
‘’Ẹlomi-in le lo ilana ti Ẹrọ Arike lo yii, iyẹn ẹka ori ayelujara, ẹlomi-in le lọ si kootu, awọn miran a ko tọọgi wa, ìṣe oloṣelu lẹ ri yẹn.
‘’Ti PDP ni ẹ ri ti ẹ n sọ yii, awọn alatako wa nkọ?
Awọn ti wọn gbe ibọn, ti wọn tun n fa wahala.
Ẹ fi wa silẹ ninu ẹgbẹẹ tiwa yii o, ẹyin oniroyin, ẹ ma yọju si i.’’
Bẹẹ ni ọkunrin naa wi.
Ta ni Ero Arike?
Bi wọn ba darukọ Alaaja Falilat Oyetunji, ọpọ eeyan le ma mọ ẹni to n jẹ bẹẹ.
Ṣugbọn bi wọn ba ni Ẹrọ Arike, orukọ to gbajumọ ni.
Ọmọ bibi ilu Ẹdẹ, ni ipinlẹ Osun ni Alaaja Ẹrọ Arike Olokemeji gẹgẹ bawọn eeyan ṣe mọ ọ si.
Nnkan ipara to sọ lorukọ yii ti kuro ni ti ipinlẹ Osun lasan, kaakiri ilẹ Yoruba ni wọn ti mọ ọ, eyi to jẹ ki Arike di gbajumọ.
Asiko kan ti iroyin gbode pe awọn ajinigbe ji i gbe niluu Ede ni okiki rẹ tun kan si i.
Bi Arike ṣe gbajumọ ninu okoowo naa lo jẹ gbajumọ ninu oloṣelu nipinlẹ Osun, ọmọ ẹgbẹ PDP ni awọn eeyan mọ iya naa si.















