''Mo ṣiṣẹ́ abẹ nígbà márùn-ún kí ẹsẹ̀ mí lè gùn si àti àtúntò eegun nígbà mẹ́ta ṣùgbọ́n ó yíwọ́ fún mi''

Oríṣun àwòrán, Elaine Foo/Supplied
Niṣe ni ẹsẹ Elaine Foo le koko, to si ni awọ too-too-to jẹyọ lati ara ọgbẹ to wa nibẹ.
Ọkọọkan ami tototoo yii lo n jẹ iranti iṣẹ abẹ to ṣe nipa ki ẹsẹ rẹ le gun, eyi to gbodi lọ.
Lati ọdun 2016, obinrin ẹni ọdun mọkandinlaadọta naa ti ṣiṣẹ aabẹ marun-un, ati atunto egungun nigba mẹta.
Bakan naa, o ti lo gbogbo anfaani to ni lati daabo bo ẹmi rẹ tan.
Foo gbe igbesẹ ofin lodi si imọran dokita rẹ, ti wọn si yanju ẹjọ naa ninu oṣu Keje.
Nigba to to asiko kan, egungun eekannaa ẹsẹ rẹ kan, to si n jẹ ko maa ni irora lati inu ara rẹ, to mu ko maa sọ pe “wọn n din egungun oun lati inu.”
“Irin ajo mi jẹ ipenija to la ina kọja, ṣugbọn mo yege,” o sọ eyi.
Gbogbo igba ni dokita rẹ n sọ pe kii ṣe aikiyesara oun lo fa ohun to ṣẹlẹ si Foo, bi ko ṣe pe awọn ohun to maa n jẹyọ niyẹn nidi isẹ abẹ.
Dokita naa ni oun ti kilọ fun un ko to gbe igbesẹ naa, ati pe awọn ayipada nla to n ba agọ ara rẹ, tun nii ṣe pẹlu awọn igbesẹ rẹ to ti gbe sẹyin nidi isẹ abẹ.

Oríṣun àwòrán, Elaine Foo/Supplied
''Bi obinrin ba ga, o tumọ si pe o dara, giga tun mu ẹwa wa, mo kan ro pe awọn to ba ga maa n ri anfaani to pọ, ni mo fi se isẹ abẹ.”
Nigba to n ba BBC sọrọ, Foo salaye awọn koko ọrọ kan nipa isẹ abẹ to se ati idi to se n korira igbesẹ to ti gbe saaju naa bayii.
“Nigba ti mo wa ni ọmọ ọdun mejila, mo ga ju awọn ọmọbinrin miran lọ,” o sọ bẹẹ.
“Ni ọmọ ọdun mẹrinla, mo bẹrẹ sii kuru ju awọn yoku lọ.
Bi obinrin ba ga, o tumọ si pe o dara. Giga tun mu ẹwa wa. Mo kan ro pe awọn to ba ga maa n ri anfaani to pọ.”
Nigba to dagba, Foo bẹrẹ sii ri aiga tabi kukuru bii abuku, to si n korira ara rẹ si ohun ti awọn eeyan n ri.
Ohun to n jẹyọ yii, ipenija lo n jẹ fun, to si mu ọkan rẹ gbọgbẹ.
Nigba to pe ọdun marundinlọgbọn, o ṣe alabapade apilẹkọ kan nipa ile iwosan kan ni China, nibi ti awọn eeyan ti n ṣiṣẹ abẹ lati le jẹ ki ẹsẹ wọn gun.
Ọrọ naa kun fun ọpọlọpọ aleebu, ṣugbọn to tun ṣi n jẹ iyemeji fun un.
“Mo mọ pe awọn eeyan yoo ṣi sọrọ pe asan lori asan ni,” o sọ bẹẹ.
“Ṣugbọn nigba ti ẹ ba n koju iṣoro kikuru, ko si alaye kikun to le sọ bo ṣe ri lara yin.”
Ọdun mẹrindinlogun lẹyin naa, Elaine ṣawari ile iwosan aladani kan to n ṣe iru nnkan bayii ni London.
Akọṣẹmọṣe nipa iṣẹ abẹ nni, Jean-Marc Guichet, lo n ṣakoso ile iwosan naa, ati ẹni to tun ti ṣagbekalẹ irinṣẹ igbalode rẹ fun egungun, Guichet Nail.
“Asiko ti mo ke aleluya niyẹn, nitori pe mo le ṣe e ni London, ti maa si maa tọju ara mi nile,” o ranti.
Dokita Guichet ṣalaye awọn to ohun to le ti ẹyin rẹ yọ. Bii apẹẹrẹ aiṣe-daadaa ara, ọpa ẹjẹ ti ko ni ṣiṣẹ daadaa, ati pe o ṣee ṣe ki awọn egungun naa ba tun ba ara wọn ṣiṣẹ papọ.
“Ṣugbọn maa ṣe iwadii temi, idi ree ti mo fi n wa awọn dokita olowo nla ti yoo fun mi ni itọju to pe ye. Afojusun mi ni lati ga ni iwọn marun le ni meji (5ft 2in) si iwọn marun le ni marun(5ft 5in).”
Lọjọ karundinlọgbọn, oṣu keje, o lọ fun iṣẹ abẹ to lero pe yoo yi igbe aye rẹ pada, eyi ti owo rẹ to ẹgbẹrun lọna aadọta pọun (£50,000).
Iṣẹ abẹ ki ẹsẹ le gun kii ṣe ohun to wọpọ, awọn ile iwosan aladani ni wọn maa n ṣe kaakiri agbaye. Awọn ile iwosan lo si le sọ iye ti wọn yoo gba lati ṣe, to si bẹrẹ lati ẹgbẹrun mẹẹdogun pọun (£15,000) si ẹgbẹrun lọna aadọjọ pọun (£150,000).

Oríṣun àwòrán, Elaine Foo/Supplied
''Ni alẹ ọjọ ti mo ji, n ṣe ni mo pariwo titi to fi di agogo mẹfa aarọ ọjọ keji, ko to di pe mo gbagbe sun lọ.”
“Jiji mi jẹ ohun idunnu, nitori niṣe lo dabi ẹni pe ko si nnkan to ṣẹlẹ, Ko si irora.
Ṣugbọn lẹyin aadọrun iṣẹju, irora yii bẹrẹ, niṣe lo dabi ẹni pe wọn n dana ninu ẹsẹ mi.
Ni alẹ ọjọ naa, niṣe ni mo pariwo titi to fi di agogo mẹfa aarọ ọjọ keji, ko to di pe mo gbagbe sun lọ.”
Ni iru igbesẹ bayii, o ṣe dandan lati la irora kọja. Lasiko iṣẹ abẹ naa, egungun naa kan si meji, wọn si fi irin sii lati fi ṣe iranwọ ninu.
Diẹdiẹ ni irin naa n ga lati le jẹ ko gun, yoo si wa ti egungun naa sọtọọtọ. Igbesẹ yii ni lati jẹ ki eeyan ga bo ṣe fẹ. Awọn egungun to kan naa yoo jinna pada lati di alafo to wa nibẹ.
Iṣẹ abẹ naa pọ titi debi pe o gba asiko to pọ.
“Bi ẹsẹ yoo ṣe gun le gba to oṣu meji si mẹta, ti yoo si lọ ni ilọpo meji, ko to di pe o jinna, ti yoo si bẹrẹ sii ṣiṣẹ bo ti yẹ.” Ọjọgbọn Professor Hamish Simpson, to jẹ alaga tẹlẹ fun British Orthopaedic Association, lo ṣe ikilọ.
Bakan naa lo tun jẹ ko di mimọ pe “Fun awọn kan, yoo gba to ọdun kan ninu igbesi aye wọn.”
Nigba ti gbogbo eto ọhun pari, igbesẹ ẹsẹ gigun Elaine bẹrẹ. Lọpọ igba laarin ọjọ kan, yoo ṣe oniruuru igbesẹ ti ko ba ara rẹ, awọn igbesẹ yii si ni yoo ṣe anfaani fun bi egungun ati ẹsẹ rẹ yoo ṣe gun. Ṣugbọn ọsẹ meji lẹyin rẹ, o ni ajalu nla lo bẹrẹ.
“Mo maa n ni ọpọlọpọ irora ninu ẹsẹ osi mi. Ni alẹ ọjọ kan, nigba ti mo n yi bẹẹdi po, mo gbọ pe nnkan kan, lẹyin naa ni irora nla yii bẹrẹ.”

Oríṣun àwòrán, Elaine Foo/Supplied
Eekannaa to wa ninu ẹsẹ osi Elaine Foo ti kan, eyi si ni egungun to lagbara julọ ninu egungun ara eniyan
Elaine lọ fun iṣẹ ayẹwo inu egungun, eyi to fidi ẹru rẹ mulẹ.
Eekannaa to wa ninu ẹsẹ osi rẹ ti kan, eyi si ni egungun to lagbara julọ ninu egungun ara eniyan.
O mu ọkan rẹ gbọgbẹ, ṣugbọn to sọ pe Dokita Guichet fi ọkan rẹ balẹ pe ko nii si wahala.
“O sọ fun mi pe ohun ti mo ni lati ṣe bayii ni pe ki n ma ṣe ba ọkan jẹ. Ki n duro digba to maa jinna, to ba si ti jinna, a maa ṣẹṣẹ bẹrẹ igbesẹ pada.”
Wọn maa bẹrẹ igbesẹ ti yoo jẹ ki ẹsẹ ọtun Elaine gun, nigba ti wọn yoo tun mu ọjọ miran fun igba ti wọn yoo bẹrẹ igbesẹ ẹsẹ osi, to si jẹ pe igba ti ẹsẹ ọtun lo lati jinna naa ni ẹsẹ osi yoo lo.
“Mo padanu gbogbo igba didun aye mi''
Agbẹjọro dokita sọ pe kii ṣe aikiyesara Dokita Guichet lo fa a, o sọ fun ile ẹjọ:
“Ohun to ṣẹlẹ yii kii ṣe aikiyesara Dokita Guichet, bi ko ṣe pe lara awọn aleebu to maa jẹyọ lati ara iṣẹ abẹ naa, eyi ti a ti kilọ fun Arabinrin Foo tẹlẹ lo fa a.
Bi Foo ko se tẹle adehun nipa asiko ti eekanna yoo lo ni ẹsẹ rẹ tun ṣakoba fun ipenija.”
Bakan na lo fi kun un nile ẹjọ pe loorekoore ni Foo sọ pe oun ko le tẹle awọn amọran Guichet, to si loun yoo wa ọna abayọ sii.
Dokita Guichet tako gbogbo ẹsun ti Foo fi kan an, to si ni ko le mu oun fun aṣiṣẹ ara rẹ nitori oun ti ṣe ikilọ fun un.
Elaine sọ pe aabo wa fun Foo nitori o n san owo rẹ deedee. Ṣugbọn to ni o ti san kọja owo to yẹ ko san.
“Mo padanu gbogbo igba didun aye mi.
Mo mọ pe awọn eeyan yoo fẹ gbọ nipa abamọ mi, ati pe bi wọn ba beere lọwọ mi lonii pe ṣe ti mo ba mọ pe maa koju awọn ipenija yii, ṣe maa tẹsiwaju, ohun ti mo maa sọ ni pe ‘rara, mi o nii ṣe e.”















