Wàhálà bẹ́ sílẹ̀ lásìkò ọdún iṣu tuntun l'Ondo, ọ̀pọ̀ dèrò àtìmọ́lé

Nigeria Police Force

Oríṣun àwòrán, NPF

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Rogbodiyan bẹ silẹ niluu Ibule-soro, to wa ni ijọba ibilẹ Ifefore, nipinlẹ Ondo lasiko ọdun iṣu tuntun.

A gbọ pe asiko ti ọdun naa n lọ lọwọ ni iro ibọn n dun lakọlakọ.

Iroyin ni wahala naa ko ṣẹyin ede aiyede to n waye laarin awọn ololufẹ Ọba ilu ọhun, Oluleke Ogunlade atawọn ti ko fẹ Ọba naa lori itẹ.

Ọba Oluleke Ogunlade lo wa lori itẹ Ibule-soro bayii bo tilẹ jẹ pe awọn ko fẹ iyansipo rẹ, ti ọrọ naa ṣi wa nile ẹjọ.

Ṣaaju ni ori ade naa ti kọkọ kede ọjọ karundinlọgbọn, oṣu Kẹjọ, ọdun yii, gẹgẹ ọjọ ọdun iṣu tuntun naa, eyi ti yoo jẹ ayajọ ọdun kan rẹ lori oye.

Amọ igbesẹ naa ko dun mọ awọn araalu kan ninu latari pe wọn ni ọjọ ti wọn maa n ṣe ọdun naa, eyii ti wọn ko fẹ ko ni iyapada rara.

Wahala bẹrẹ lasiko ti awọn ọmọ ilu ti wọn tako Ọba naa gbe igbesẹ lati bẹrẹ ọdun iṣu tuntun ọhun lọjọ Ẹti, eyii ti wọn sọ pe o jẹ ayajọ ọjọ ti ọdun naa maa n waye tẹlẹ gẹgẹ bii aṣa ilu wọn.

Awọn eeyan naa ti korajọ laarọ kutu lati bẹrẹ ọdun ki awọn ọlọpaa atawọn ologun kan to lọ tu wọn ka.

Ẹnikan ti ọrọ naa ṣoju rẹ, amọ ti ko fẹ fi orukọ ara rẹ lede sọ pe ni kete ti awọn ọlọpaa naa de ni wọn bẹrẹ si n yinbọn soke, ti wọn tun n yin gaasi tajutaju si gbogbo awọn ti wọn ri.

O ni “wọn yin gaasi tajutaju sinu ọpọlọpọ ile ti awọn arugbo n gbe, bẹẹ ni wọn tun ja wọ awọn ile kan, ti wọn si fi ṣikun ofin mu awọn eeyan nibẹ.”

Gẹgẹ bii ohun to sọ, ọpọ eeyan ni ọlọpaa mu, ti wọn si ko lọ si agọ wọn to wa niluu Igbara-Oke, to jẹ olu ilu ijọba ibilẹ ọhun.

Wayi o, agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Funmilayo Odunlami-Omisanya, ti sọ pe awọn ti pẹtu si wahala naa.

O ni ṣe lawọn ọlọpaa lọ pana rogbodiyan to waye nibẹ, bẹẹ ni awọn ko gbe sẹyin ẹnikẹni.