Wo ohun tọ ṣẹlẹ̀ sí oníjìbìtì orí ayélujára tó fẹ́ gbá akọ́ròyìn BBC

BBC World Service Correspondent Joe Tidy
    • Author, Joe Tidy
    • Role, Cyber correspondent, BBC World Service
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Awọn onijibiti ori ayelujara ti gbiyanju lati ṣe gbajuẹ fun akọroyin BBC kan, Joe Tidy.

Onijibiti naa lo aworan obinrin arẹwa kan, to sọ pe ilu Chicago, l’Amẹrika ni oun ti wa ati pe oun fẹ ki awọn mejeji jẹ ololufẹ.

Joe Tidy gba lati ba onijibiti to n dibọn bii obinrin naa dọrẹ lọna ati mọ bi wọn ṣe n lu jibititi ọhun.

“Kaarọ o arẹwa ọkunrin, bawo ni oni ṣe maa jẹ?”

Irufẹ awọn atẹjisṣẹ bayii ni akọroyin BBC naa maa n gba lati ọwọ obinrin ọhun, Jessica, lojumọ.

Fun ọpọlọpọ ọsẹ ni itakurọsọ fi n lọ laarin awọn mejeji loju opo Instagram, titi ti wọn fi di ọrẹ atata.

Tidy ni kete ti oun gba atẹjiṣẹ akọkọ lati ọdọ Jessica ni oun ti mọ pe onijibiti ni.

O ni iyalẹnu lo jẹ fun oun pe awọn onijibi naa maa n ni suuru, wọn si maa n ni ọpọ ifọrọwerọ pẹlu awọn ti wọn ba fẹ lu ni gbajuẹ, lọna ati le ri wọn mu ni igbẹyingbẹyin.

Jessica sọ fun Tidy pe “ọkunrin to jẹ olootọ, oniwatutu” loun n fẹ.

"Jessica" picture stolen from a real woman's account
Àkọlé àwòrán, Aworan obinrin naa 'Jessica' ree amọ igbabọ wa pe ẹrọ AI ni wọn fi ya aworan naa

Ni igbẹyingbẹyin, Jessica tu aṣiri ara rẹ pe onijibiti ni oun lẹyin to ṣafihan apo iṣuna ‘crypto’ rẹ, eyii to ni owo ti iye rẹ le ni $47,000 ninu.

Jessica sọ fun ọkunrin naa pe “iwọ naa le ri owo gọbọi nidi crypto bii temi o’.

Tidy sọ pe “ni kete to mẹnuba ọrọ owo ni mo mọ pe ootọ ni ifura mi pe onijibiti ni.”

Irufẹ jibiti ti wọn fẹ lu akọroyin BBC yii ni wọn n pe ‘pig bucthering’ ninu eyii ti wọn ti maa n kọkọ fi ọrọ ifẹ lọ awọn ti wọn ba fẹ lu ni jibiti ki wọn to tan wọn pe ki wọn wa ṣowo crypto.

Pig Butchering screenshots

Gẹgẹ bii atẹjade kan ti ajọ ọtẹlẹmuyẹ FBI fi lede, nnkan bii biliọnu mẹta dọla lawọn eeyan padanu sinu jibiti ọhun lọdu 2022 nikan ṣoṣo.

Ninu oṣu Kẹta ọdun yii, baba ẹni ọdun 82 kan ṣekupa ara rẹ niluu Maryland, nilẹ Amẹrika, lẹyin ti wọn lu u ni jibiti gbogbo owo to fi ọjọ aye rẹ kojọ.

Lọdun 2022, ọkunrin kan padanu owo to le ni $1m.

Pig butchering conversation. Scammers say 'pay me and I will talk to you'

Onimọ nipa jibiti, Brittany Allen sọ pe awọn onijibiti maa n mọọmọ ba eeyan dọrẹ ko le rọrun fun wọn lati lu irufẹ ẹni bẹẹ ni jibiti.

O ni “nnkan meji pataki ti wọn maa n lo ni ibadọrẹ ati ijẹgaba le eeyan lori.”

Lẹyin ọsẹ mẹsan an gbako, Tidy sọ fun jessica pe akọroyin BBC ni oun ati pe oun mọ pe onijibiti ni.

Jessica jẹwọ pe lootọ loun fẹ lu Tidy ni jibiti amọ oun ko mọọmọ nitori awọn eeyan kan lo n lo oun lati lu u ni jibiti.

Ninu oṣu Kẹta ọdun yii, ijọba doola ọpọ eeyan ninu ọọfisi awọn to n lo wọn lati lu awọn ẹlomii ni jibiti ni Philippines.

Awọn eeyan naa sọ pe ọtọ ni iṣẹ ti wọn gba wọn fun ki wọn to maa lo awọn lati lu awọn eeyan ni jibiti.

Lẹyinorẹyin, Jessica fopin si ibadọrẹ oun ati Tidy lẹyin to ri pe akara oun ti tu sepo.