Òní ni àṣekágba ìwọ́de ‘ebi ń pa wá’ #EndBadGovernance, àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ láàrin ọjọ́ mẹ́wàá rèé

Aworan iwọde ‘ebi ń pa wá’
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 10

Oni Ọjọ Abamẹta, ọjọ kẹwaa oṣu kẹjọ ọdun 2024 ni iwọde 'Ebi n pa wa' to n lọ lọwọ lorilẹede Naijiria wa sopin gẹgẹ bii ikede ti awọn olori iwọde gbe sita saaju iwọde naa.

Iwọde ọhun ni isinmi de ba diẹ lẹyin iroyin jade pe ọwọ ti tẹ awọn eeyan kan to n se agbatẹrun fun iwọde naa.

Iwọde naa bẹrẹ lọjọ kinni oṣu kẹjọ ọdun 2024 ni igbagbọ wa pe yoo wa sopin lonii, ọjọ Kẹwaa Oṣu kẹjọ ọduyn 2024, kaakiri orilẹede Naijiria.

Iwọde yii lo waye ni ọpọ ipinlẹ lorilẹede Naijiria, ti awọn ipinlẹ mii si kọ lati kopa ninu iwọde.

Lara awọn ipinlẹ ti iwọde naa ti waye lọjọ kini ni olu ilu Abuja, ipinlẹ Eko, Oyo, Osun, River, Kano, Bauchi, Borno, Kaduna ati bẹbẹ lọ.

Awọn ipinlẹ ti ìwọde ọhun ko ti waye ni ipinlẹ Ondo, Ekiti, Enugu, Abia, Imo, Akwa ibom, Ebonyi ati ọpọ ipinlẹ lẹkun ila oorun Naijiria.

Ki gan lo fa iwọde Ebi n pa wa?

Ohun akọkọ ti a le sọ pe o sokunfa iwọde #EndBadGovernance ni igbesẹ ijọba ti o n fa ọwọngogo ati ebi ni ilu nitori kudiẹkudiẹ to de ba eto-ọrọ aje lorilẹ-ede Naijiria.

Akoko yii lorilẹede Naijiria ni ọpọ ti ṣapejuwe gẹgẹ asiko ti kudiẹkudiẹ de ba eto ọrọ aje ju ninu itan orilẹede Naijiria nitori idiyele ti o gbalẹ, paapaa lori iye owo ounjẹ.

Ọpọ awọn amoye ti so pe ohun to n sẹlẹ yii kọ sẹyin igbesẹ ijọba lati se awọn atunṣe si eto-ọrọ aje, paapaa bi wọn se yọ awọn iranwọ epo kuro ati mimu idinku ba owo Naira labẹ ijọba Aare Bola Tinubu, pẹlu erongba pe yoo jẹ ki ọpọ awọn onisowo wa se ọrọ-aje wọn ni Naijiria.

Ọpọ igbesẹ ni Aarẹ Tinubu ti gbe lati ma jẹ ki iwọde naa, paapa pipese ohun iranwọ fun awọn ọdọ ati akẹkọọ sugbọn awọn to nse agbstẹru iwọde naa fariga.

Iwọde ọhun lo bẹrẹ ni ọjọ kinni oṣu kẹjọ kaakiri orilẹede Naijiria, ti yoo si waye fun ọjọ mẹwaa.

Ọpọ oluwọde lo tu sita, ti wọn oniruuru patako soke lati fi ẹhonu wọn han, to n sọ pe ‘O ti to’, ‘Awọn ilana ijọba n ni wa lara’ , ‘ Ara n ni wa’, ‘Ẹ da owo iranwọ epo bẹntiro pada’.

Ki lo sẹlẹ lasiko iwọde naa

Aworan
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Lọjọ akọkọ iwọde to jẹ ọjọ kinni oṣu kẹjọ ọdun 2024 ni o jẹ ọjọ ti iwọde ọhun lagbara ju, ti ọpọ eeyan si padanu ẹmi wọn

Nipinlẹ Eko, nibi ti ọpọ ti gbagbọ pe o yẹ ki iwọde naa di wahala ni gbogbo adugba da paroparo ti ọpọ ṣọọbu, awọn ile ìfowopamọ ṣe wa ní titipa.

Yatọ si ipinlẹ Eko, awọn ipinlẹ yooku ti iwọde naa ti waye bi ipinlẹ Oyo, Osun ni iwọde ọhun waye ni pẹlẹ kutu, ti ọpọ awọn oluwọde si n pe fun ifopinsi ijọba ti ko dara ni orílẹ ede Naijíria.

Awọn oluwọde, ti wọn gbe oniruuru akọle, ti wọn sì n pariwo ki ijọba ti ko dara dopin ní Naijiria ni awọn agbegbe Freedom Park nipinlẹ Eko ati ile ijọba niluu Ibadan.

Ni Ilorin, ipinlẹ Kwara ẹwẹ, paroparo ni papa iṣere Metropolitan Square, ibi ti ile ẹjọ fun awọn olufẹhonuhan laṣẹ lati lo fun iwọde wọn, ni gbogbo ibẹ da.

Awọn ọlọpaa atawọn ẹṣọ aabo miiran wa nibẹ lati mojuto awọn oluwọde amọ awọn oluwọde ko to nnkan nibẹ rara.

Awọn ọlọpaa fẹ ẹ pọ ju awọn olufẹhonuhan lọ nitori awọn eeyan ko tu sita boya nitori ibẹrubojo atawọn gbedeke ti ti ile ẹjọ gbe kalẹ lori iwọde naa.

Nipinlẹ Kano, Kaduna, Nasarawa Borno ati awọn ipinlẹ kan ni apa ariwa orilẹede Naijiria ni o da bi pe iwọde ‘ebi ń pa wá’ ti gba ọna miiran yọ si awọn araalu.

Yatọ si pe ọpọ lo tu sita lasiko iwọde naa, ọpọ dukia ati ẹmi lo sofo, jagijagan lo waye lasiko iwọde ni awọn ipinlẹ kan ni apa ariwa lorilẹede Naijiria.

Ado oloro bugbamu nipinlẹ Borno, ti ọpọ eeyan si padanu ẹmi wọn, ti awọn mii si farapa yanayana.

Akọroyin BBC to wa ni Kano jabọ pe oniruru patako alakọle ni awọn ọdọ naa ko lọwọ ti wọn si n sọ awọn ọrọ ẹhonu loriṣiriṣi.

Gẹgẹ bi o ṣe ọ, o ni nnkan bii eeyan mẹta lo ti fara gbọta ibọn lara awọn oluwọde naa.

Yatọ si pe ọpọ eeyan fara gba ọta, ọpọ sọọbu ni awọn oluwọde ja lulẹ ti wọn si bẹrẹ si ma ko dukia awọn salọ.

Awọn oluwọde mii tun se ikọlu si ọfisi Gomina ipinlẹ Kano, ti wọn si ba ọpọ dukia jẹ.

Awọn ipinlẹ wo lo kede ofin konile-gbele?

Aworan

Ni ọjọ kinni iwọde 'Ebi n pa wa', ọpọ rogbodiyan lo bẹ silẹ ni awọn ipinlẹ kan ni apa ariwa orilẹede Naijiria.

Bakan naa ni iwọde ọhun ja si iku ojiji fun ọpọ eeyan, ti awọn mii si farapa.

Lẹyin ti ado oloro kan bu gbamu lagbegbe Kawori, ipinlẹ Borno, Gomina ipinlẹ naa, Babagana Umar Zulum, kede ofin konile-o-gbele ni Borno.

Bakann ni Gomina ipinlẹ Kano, Abba Kabir Yusuf, Gomina ipinle Kanduna, Uba Sani ati Gomina ipinle Nasawara, Abulaahi Sule naa kede ofin konile gbele ni awọn ijọba ibilẹ kan fun wakati mẹrinlelogun.

Pupọ awọn ipinlẹ yii ni wọn ti fopin si ofin konile-gbele bayii lẹyin isinmi ti de ba iwọde lasiko yii.

Gbigbe asia orilẹede Russia soke

Aworan

Oríṣun àwòrán, Channels TV

Ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria ni ọwọ awọn ti tẹ awọn ọmọ ilẹ okeere kan ti wọn funrasi pe wọn n ṣe agbodegba fun awọn to n lo aṣia orilẹede Russia fi ṣe iwọde lawọn agbegbe kan lapa oke ọya lorilẹede Naijiria.

Kọmiṣọna ọlọpaa ni ipinlẹ Kano, Salman Garba lo sọ eyi lẹyin ipade abo ti wọn ṣe pẹlu gomina ipinlẹ Kano, Abba Yusuf lọjọ Iṣẹgun.

Gẹgẹ bi o ṣe wiawọn ọlọpaa atawọn agbofinro yooku yoo ya bo gbogbo awọn to ba n domi alaafia ru ni ipinlẹ naa.

Bakan naa lo tun kede pe wọn tidẹ okun ofin isede to wa nilẹ nipinlẹ naa kuro ni agogo mẹfa aarọ si mẹfa irọlẹ.

Ọwọ awọn oṣiṣẹ agbofinro DSS lorilẹede Naijiria ti tẹ awọn aranṣọ to n ran aṣia orilẹede Russia fun awọn oluwọde niilu Kano.

Ileeṣẹ agbofinro DSS ni ọwọ tẹ awọn telọ naa ti wọn n ran awọn aṣia ti wọn n pin kaakiri ipinlẹ naa.

Bakan naa ni ileeṣẹ agbofinro DSS tun fi kun un pe ọwọ awọn ti tẹ awọn to gbe iṣẹ naa fun wọn., bẹẹ ni iwadi awọn ṣi n tẹsiwaju lori rẹ.

Ọmilẹgbẹ awọn oluwọde lapa ariwa orilẹede Naijiria ni wọn n mu aṣia orilẹede Russia kiri lasiko iwọde to n waye nibẹ.

Ki orilẹede Russia sọ lori iṣẹlẹ yii?

Ijọba Russia lorilẹede Naijiria ti ni awọn ko mọ nnkan kan nipa awọn eeyan to gbe asia orilẹede naa kiri lati fẹhonuhan ni Naijiria.

Lọjọ Aje, ọjọ karun-un oṣu keje ọdun 2024, ni ajọ to n ṣoju Russia ni Naijiria, fi atẹjade kan sita pe awọn ko lọwọ ninu iwọde ti wọn ti gbe asia Russia kiri lorilẹede yii.

Gẹgẹ bi awọn aṣoju Russia ni Naijiria ṣe wi, “ Ijọba apapọ Russia ati awọn aṣoju wọn ko lọwọ ninu igbesẹ yii, awa si kọ ni adari rẹ.

“ Gẹgẹ bi ìṣe wa, a n tẹnumọ ọ bayii, pe Russia ki i koju bọ ọrọ abẹnu awọn orilẹede ilẹ okeere, Naijiria naa si jẹ ọkan lara wọn.”

“ Awọn ti wọn fi asia Russia wọde ni Naijiria ṣe bẹẹ lati ọwọ ara wọn ni, ko si tumọ si pe ijọba orilẹede Russia mọ nipa rẹ. ”

Se lootọ ni pe Ogun eeyan lo ku lasiko iwọde 'Ebi n pa wa'?

Amnesty International fi ẹsun kan ọlọpaa pe wọn n lo ọgbọn lati ṣeku pa awọn eeyan nigba ti wọn ba ti ko ara wọn jọ tan, ati pe wọn tun n lo ọta ìbọn gidi pẹlu awọn oluwọde.

Bakan naa ni Ileeṣẹ kan, Beacon Consulting, to n tọpinpin eto aabo, ti kodin ni ogun eeyan ti wọn di oloogbe ninu iwọde to bẹrẹ ni Naijiria lọjọ akọkọ ninu oṣu kẹjọ ọdun 2024, ipinlẹ mẹfa ni iṣẹlẹ iku naa si kan.

Wọn fidi iwadii wọn mulẹ bayii lori iwọde to n kede pe opin gbọdọ ba iṣakoso buruku ni Naijiria.

Awọn ipinlẹ naa ni: Adamawa, Borno, Gombe, Jigawa, Kaduna, Kano, Kebbi, Nasarawa, Niger ati Yobe.

Ileeṣẹ yii ṣalaye pe eeyan mẹfa ni wọn pa nipinlẹ Niger, mẹrin ku ni Borno, eeyan mẹta si dero ọrun ni Kaduna.

Beacon Consultant sọ pe eeyan mẹrin lo ba iwọde lọ ni Kano, ẹnikan lo ba a lọ ni Kebbi, awọn meji si dero ọrun ni Jigawa.

Iwadii wọn naa tun sọ pe awọn agbofinro kuna lati ṣiṣẹ wọn, eyi ni wọn lo fa a ti iwọde fi di rogbodiyan.

Ijọba orilẹede yii ko ti i fi atẹjade to n tọka iye eeyan to ku sita lori rogbodiyan naa.

Ki esi ileeṣẹ ọlọpaa si awọn ẹsun yii?

Ileeṣẹ ọlọpaa orilẹede Naijiria ti sọ pe ko si òtítọ kankan ninu ọrọ ti ajọ ajafẹtọọ Amnesty International sọ wi pe awọn ọlọpaa ti ṣeku pa oluwọde mẹtala kaakiri orilẹede Naijiria.

Agbẹnusọ ọlọpaa, Muyiwa Adejobi ṣalaye pe afurasi bii 681 ni ọlọpaa ti mu fun ọkan o jọkan iwa ọdaran l'asiko ifẹhonuhan to ti bẹrẹ lati Ọjọbọ ọsẹ to kọja.

Adejobi sọ pe ipinlẹ Gombe, Jigawa, Kaduna, Sokoto, Nasarawa, Katsina, Kano ati Abuja ni ile iṣẹ ọlọpaa ti mawọn afurasi odaran naa.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa fikun ọrọ rẹ pe ọlọpaa kan tawọn ti ro pe o ti ku tẹlẹ ti n mi pada bayii.

"Ọlopaa mẹsan an lo farapa lẹyin t'awọn oluwọde ṣe ikọlu si wọn.Ọkan lara wọn ti a ro pe o ti ku tẹlẹ ni o ti ye bayii.Amọ, ẹsẹ kan aye, ẹsẹ kan ọrun ni o wa," Adejobi lo sọ bẹẹ.

Ki ni Aarẹ sọ lori iwọde yii?

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Nigba to n ba awọn araalu sọrọ lọjọ Aiku, ọjọ kẹrin oṣu kẹjọ ọdun 2024, Aarẹ Bola Ahmed Tinubu sọ pe yiyọ owo iranwọ ori epo kii ṣe ohun to rọrun, ṣugbọn ohun to ṣe pataki julọ ni lati yọ ọ danu.

Dida owo iranwọ ori epo bentiro pada jẹ ọkan pataki lara awọn ohun ti awọn olufẹhonuhan n beere fun, lati le dẹkun iṣẹ ati oṣi lawujọ.

Aarẹ Bola Tinubu lasiko to n ba awọn ọmọ Naijiria sọrọ laarọ ọjọ Aiku sọ pe ọkan pataki lara awọn igbesẹ lati mu atunto ba eto ọrọ aje ni yiyọ owo iranwọ ori epo naa jẹ.

O ni fun igba pipẹ ni eto ọrọ aje Naijiria ti dẹnukọlẹ, to si n fa idena fun ilọsiwaju.

Tinubu sọ pe “Fun bi ọdun kan le sẹyin, orileede wa, Naijiria ti de ipele to jẹ pe a ko le maa wa ọna abayọ igba diẹ lati fi yanju iṣoro ọjọ pipẹ, nitori awọn iran ti wọn ko tii bii.

“Eyi lo jẹ ki n gbe igbesẹ to le lati yọ owo iranwọ ori epo lati le dẹkun lilo owo ilẹ okeere, eyi to ti ko ipa to ku diẹ kaato ninu eto ọrọ aje wa ati ifasẹyin ilọsiwaju eto ọrọ aje.”

N jẹ se iwọde yii ni anfani lati tan ìṣoro orilẹede Naijiria?

Bi iwọde se n pari lonii ni ọpọ awọn araalu ti n koju pe iwọde naa ko yi nnkan pada, ti ijọba ko si se kankan pato lori ohun ti ilu n bere fun.

Sugbọn awọn amoye kan si ni igbagbọ pe iwọde to kasẹ nlẹ lonii ti se aṣeyọri ni iwọnba to le se.

Nigba to n ba ikọ BBC sọrọ, ọkan lara oluwọde nipinlẹ Oyo, Solomon Emiola, ni ohun ti awọn araalu n bẹrẹ fun ki ṣe ohun ti ijọba le kofiri se sugbọn iwọde to sẹsẹ pari ti jẹ ki ijọba ma gbe igbesẹ ni bi to ti yẹ lati mu ayẹdẹrun fun awọn araalu.

O tẹsiwaju pe bo ti lẹ jẹ ko ki n se gbogbo nnkan ti awọn n bẹrẹ ni ijọba ti ṣe sugbọn o han gbangba pe wọn ti bẹrẹ si ni ma gbe igbesẹ.

“Ti ẹ ba wo, ẹ ri pe ijọba ti n gbe igbesẹ lori iwe ofin orilẹede Naijiria, to si wa lara ohun ti a n bere fun.

“Diẹdiẹ ni a n se, sugbọn iwọde yii ransẹ ikilọ si awọn oloṣelu, ti ẹ ba ri, ọpọ gbogbo wọn lo sa lọ.

“Bakan naa lo tu aṣiri awọn ipinlẹ kan ati ijọba apapọ., Eyi lasan gan jẹ aṣeyọri fun wa.

“Fun Seyi Makinde lati bọ si sita lori owo ti ijọba apapọ fun gan jẹ aṣeyọri ni iwọnba tiẹ

“Fun ileeṣẹ ọlọpaa lati ri pe awọn dabobo awọn oluwọde tun si pe wọn mọ ohun ti a fẹhonuhan lori, aṣeyọri ni”

Sikiru Akinola, ninu ọrọ to ba BBC sọ, ṣalaye pe iwọde ‘Fifi opin si ijọba buburu’ ko ṣe aṣeyọri kankan, ti ko si tan iṣoro awọn araalu.

Akinola ni Aarẹ Tinubu ṣẹṣẹ lo ọdun kan ni ori oye, ti ko si to fun ijọba lati tan iṣoro to ti wa n lẹ tipẹ.

“Nigba ti wọn bẹrẹ iwọde, ohun ti wọn pe ni ‘fifi opin si ijọba buburu’ nitori pe awón eeyan n pariwo nipa ọwọngogo ati ebi.

“Ohun to jẹ ki iwọde ma se aṣeyori ni awọn eeyan ti wọn binu si aarẹ lọwọ lori ohun to waye ni apa ariwa orilẹede Naijiri, to si jẹ ibẹ ni iwọde naa ti fa wahala ju.

“Awọn eeyan yii lo anfani iwọde yii lati fa wahala sugbọn wọn ko ṣe aṣeyọri nitori lẹyin ijọ kinni ijọ keji, iwọde naa walẹ.

“Fun emi, ko se aṣeyọri kankan,”