Ẹ̀tọ́ aráàlú ni wọn ń bèèrè fún pẹ̀lú ìfẹ̀hónúhàn 'ebi ń pa wá,' ìjọba gbọdọ̀ tẹ́tí sí wọn - Obasanjo

Aworan Olusegun Obasanjo

Oríṣun àwòrán, Olusegun Obasanjo/X

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Aarẹ tẹlẹri lorileede Naijiria, Oloye Olusegun Obasanjọ ti sọ pe ẹtọ araalu ni lati jade fi ẹhonu han lori awọn ohun ti ko wọn lọrun laarin ilu bi eto ọrọ aje to dẹnukọlẹ.

Obasanjo lo sọrọ naa niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun lọjọ Ẹti, ọsẹ yi lasiko to n gba awọn aṣoju-ṣofin ilẹ Naijiria lalejo.

Aarẹ Obasanjo sọ pe ojuṣe ijọba ni lati ba araalu sọrọ, ki wọn si ṣe ohun ti araalu n fẹ lasiko ko to di pe o pẹ ju.

O sọrọ naa lati fesi si iwọde to n lọ lọwọ kaakiri Naijiria, nibi ti awọn eeyan ti n fẹhonuhan lori akọle ti wọn pe ni #EndBadGovernance, eyi to bẹrẹ lọjọ kinni, oṣu kẹjọ, ọdun yii.

Bi ẹ ko ba gbagbe, Ọjọbọ, ọsẹ to kọja ni awọn ọdọ kaakiri Naijiria jade lati fẹhonu han si ijọba lori ipo ti eto ọrọ aje Naijiria wa, paapaa ọwọngogo to fa iṣẹ ati oṣi laarin ilu.

Yatọ si eyi, awọn araalu tun fẹhonuhan lori aisi eto aabo to peye ati awọn oniruuru iṣoro miran to n doju kọ wọn.

Obasanjo nigba to n sọrọ bu ẹnu atẹ lu bi ijọba Aarẹ Bọla Tinubu ko ṣe sọrọ ti yoo tan iṣoro ti araalu n koju, eyi to fa ọwọngogo.

“Ẹ jẹ ohun ti ẹ jẹ lonii nitori pe ẹ jẹ ọmọ Naijiria, Obasanjo lo sọ eyi.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Siwaju sii lo tun sọ pe: “Mo jẹ ohun ti mo jẹ nitori pe mo jẹ ọmọ Naijiria. Ki lo wa de ti wọn maa jẹ ọmọ Naijiria, ti wọn yoo si maa jiya ninu iṣẹ ati oṣi?

“Gẹgẹ bi mo ti ṣe ikilọ ṣaaju, a nilo lati mọ pe ori ike ẹtu ibọn la jokoo le lori, bi a ba si kọ lati bẹrẹ sii ṣe ohun to yẹ.

“Fun apẹẹrẹ, ohun ti awọn ọdọ n beere fun yẹ lati beere fun, ati pe wọn nilo ki wọn ba wọn sọrọ, abi ki lo de ti wọn fi gbọdọ fi ẹtọ to tọ si wọn dun wọn?

“Wọn n beere ohun ti wọn n fẹ ni, a ko si wa da wọn lohun. Ọpọ wọn ni wọn ti sun kan ogiri, ti wọn si n wa gbogbo ọna, wọn n binu, wọn ko si tun gba wọn si iṣẹ.

“Ki la wa n lero pe yoo ṣẹlẹ? Wọn nilo lati gbọ wọn, ki wọn si ṣe awọn nnkan ti wọn n fẹ fun wọn.”

Obasanjọ tẹsiwaju ninu ọrọ rẹ pe ṣiṣe agbekalẹ igba ti awọn to di ipo oṣelu mu yoo lo kọ ni iṣoro, bi ko ṣe pe ki irori awọn ti wọn wa ni ipo oṣelu yi pada si rere.

“Kii ṣe pe ki Naijiria ṣagbekalẹ saa kan ṣoṣo ti yoo jẹ ọlọdun mẹfa ni iṣoro, bi ko ṣe pe ka pada si ibẹrẹpẹpẹ.

“Bi irori awọn to wa ni ijọba ko ba yipada, o tunmọ si pe Naijiria yoo ṣi tubọ maa wa ni ibi to wa.

“Ni ti emi gẹgẹ bi ẹnikan, ohun to ṣe pataki ni pe ka ṣe ohun to tọ lasiko. Boya a fi ontẹ lu saa ọlọdun mẹfa kan ṣoṣo, tabi saa meji ọlọdun mẹrin-mẹrin, ibi ti yoo ti ṣiṣẹ ni irori wa ati bi a ṣe n ronu idagbasoke.”

Laipẹ yii ni awọn aṣoju-ṣofin ilẹ Naijiria gbe iwe aba dide, eyi ti yoo jẹ ki awọn aarẹ, gomina, ati ipo laarin awọn Ariwa ati ẹka Guusu yoo ṣe maa yi, ati ọjọ kan ṣoṣo fun eto idi aarẹ, gomina, awọn aṣofin agba ati ile igbimọ aṣofin ipinlẹ.