Manchester United àti Manchester City yóò wàákò fún ife Community Shield lónìí láti ṣílẹ̀kùn sáà Premier league

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ikọ agbabọọlu Manchester City to gba ife ẹ̀yẹ Premier League ni saa bọọlu to kọja lọ yoo maa waako pẹlu orogun ati alamuletiwọn Manchester United ti wọn gba ife ẹyẹ FA Cup lonii ọjọ kẹwaa oṣu Kẹjọ ọdun yii ninu ifẹsẹwọnsẹ Community Shield ni papa iṣere Wembley.
Ere bọọlu Community Shield yii ni yoo ṣide saa bọọlu tuntun idije Premier League fun 2024/2025.
Ifẹsẹwọnsẹ yii jẹ ẹda ere bọọlu aṣekagba idije FA Cup saa bọọlu to kọja ninu eyi ti Man United ti lu Man City pẹlu ami ayo meji si ẹyọkan gba ife naa mọ wọn lọwọ ni papa Wembley yii kan naa.
Igba akọkọ ree ti Man City ati Man United yoo pade ninu idije Community Shield lati ọdun 2011 nigba ti United fagba han City pẹlu ami ayo mẹta si meji lati gba ife ẹyẹ ọhun.
Ẹgbẹ agbabọọlu Man United to ti gba ife ẹyẹ Community Shield fun igba mọkanlelogun yoo bẹrẹ saa bọọlu tuntun yii ninu idije Premier League nigba ti wọn yoo maa koju Fulham lọjọ Ẹti ọsẹ to n bọ ni papa iṣere Old Trafford.
Man City to ti gba ife ẹyẹ Premier League fun igba mẹrin lera lera bayii yoo bẹrẹ saa bọọlu tuntun nigba ti wọn yoo maa waako pẹlu Chelsea lọjọ Aiku ọjọ kejidinlogun oṣu Kẹjọ yii.
Ohun ti Eric Ten Hag ati Pep Guardiola sọ ree
Ẹwẹ, akọnimọọgba Man United Eric Ten Hag ti sọ pe oun yoo lo awọn agbabọọlu to lamilaaka fun ifẹsẹwọnsẹ naa.
Ten Hag ni "ọrọ ati gba ife ẹyẹ niyii, a o sa gbogbo agbára wa lati ṣe bẹẹ.
Olukọni Man City, Pep Guardiola, naa ko gbẹyin nigba to sọ pe awọn agbabọọlu oun ti ṣetan lati gba ife ẹyẹ Community Shield ni papa iṣere Wembley lọsan an ọjọ Satide.
Guardiola ni "ifẹsẹwọnsẹ yii ṣe pàtàkì tori idije aṣekagba lo jẹ pẹlu Man United.
Amọ, a tun maa lo idije naa lati gbaradi fun saa bọọlu tuntun lẹyin ti ọpọ awọn agbabọọlu ti lọ fun isinmi."
Igba kẹta niyii ti Man United ati Man City yoo koju ara wọn ninu idije idije aṣekagba ere bọọlu laarin oṣu mẹẹdogun lẹyin ti Man City fagba han Man United ninu ifẹsẹwọnsẹ aṣekagba idije FA Cup ọdun 2023.
Pẹnariti ni wọn yoo fi yanju ẹ bi ẹnikankan ko ba jawe olubori ninu awọn ẹgbẹ agbabọọlu mejeeji laarin iṣẹju aadọrun.















