Mínísítà eré ìdárayá sàlàyé ìdí tí ọmọ Nàìjíríà Ese fi yá kẹ̀kẹ́ láti kópa nínú ìdíje Olympics

Aworan Ese lovina Ukpeseraye

Oríṣun àwòrán, Ese lovina Ukpeseraye/X

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Lọjọ Aiku to kọja yii, ọmọbinrin awakẹkẹ n ni, Ese Lovina Ukpeseraye dije gẹgẹ bi awakẹkẹ kan ṣoṣo to n ṣoju ilẹ Afrika nibi idije Olympics to n lọ lọwọ.

Nigba to n fi idunnu rẹ han l’Ọjọbọ, ọsẹ yii, Ese gbe ọrọ kan jade lori ikanni ayelujara nibi to ti n dupẹ lọwọ awọn akẹgbẹ rẹ lati Germany ti wọn fun un ni kẹkẹ to fi kopa.

Kete to gbe ọrọ naa sori ayelujara ni awọn ọmọ Naijiria ti bẹrẹ sii bu ẹnu atẹ lu ajọ to n ri sọrọ ere idaraya lorileede ọhun lori wi pe wọn ko le pese kẹkẹ lasiko idije.

Bo tilẹ jẹ pe Ese ko sọ ninu ọrọ rẹ pe ikọ Naijiria to lọ sibi idije naa ya kẹkẹ, eyi lo si fa awuyewuye lori ayelujara.

Ọmọ ọdun marundinlọgbọn naa to kopa ni ere idaraya naa ti wọn pe ni ‘Keirin ati Sprint cycling’ lo pari pẹlu ipo kẹfa pẹlu iṣẹju 13.108, fun kilomita mejidinlọgọjọ (158km).

Ko ni anfaani lati yege fun ipele to kangun si eyi to kangun si aṣekagba ti a mọ si ‘quarterfinal’.

Ese, ninu ọrọ tọ fi soju opo ‘X’ rẹ ṣalaye pe: “nitori asiko perete ti wọn fun mi lati kopa ni idije ọhun, ẹka ti Keirin & Sprint, nko ni kẹkẹ latio fi sare pẹlu awọn akẹgbẹ yooku.

"Ninu ẹmi ati ọkan elere idaraya, awọn akẹgbẹ mi lati ikọ German @bunddeutscherradfahr ni wọn wa gba mi silẹ nipa ṣiṣe iranwọ kẹkẹ fun mi. Ẹ ṣeun,” ohun to kọ ree.

Bi awọn ọmọ Naijiria kan ṣe n dupẹ lọwọ ikọ German to ṣe iranwọ naa, awọn miran bẹrẹ sii bu ẹnu atẹ lu ileeṣẹ to n ri ṣakoso ere idaraya ni Naijiria lori bi wọn ṣe n ya kẹkẹ lati fi kopa ninu idije.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 1

Bawo ni Ese ṣe ri kẹkẹ ọhun ya lọwọ ikọ Germany lati fi sare?

Ese lovina Ukpeseraye

Oríṣun àwòrán, Ese lovina Ukpeseraye/X

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Lẹyin gbogbo awuyewuye naa, Minisita fọrọ ere idaraya, John Owah Enoh loju opo ‘X’ rẹ, ṣalaye ohun to ṣẹlẹ ti ọrọ fi ri bẹẹ, to fi di Ese lọ n ya kẹkẹ lati fi kopa.

Minisita naa sọ pe aṣigbọ ni ọrọ ọhun jẹ fun awọn ọmọ Naijiria, nitori pe ikọ Naijiria peregede fun ere sisa opopona kan ṣoṣo ninu idije, to si jẹ pe eyi nikan lo gbaradi fun pẹlu irinṣẹ to yẹ.

O tẹsiwaju pe ikọ Naijiria ti gbaradi fun ere sisa to jẹ pe ọna kan ṣoṣo ni wọn ri anfaani rẹ gba, ko to di pe wọn gba ipe lati ọdọ ajọ to n ṣakoso kẹkẹ lati fi sare lagbaye, ICU wi pe wọn yege lati kopa ni ọna kan ṣoṣo.

O sọ pe awọn si nilo irinṣẹ ti yoo gba ẹka to n ri ṣorọ fifi kẹkẹ sare ni ọpọlọpọ oṣu lati ra.

BBC ri lẹta ti wọn kọ lọjọ kẹtalelogun, oṣu keje, ọdun 2024, eyi ti ajọ International Cycling Union fi ranṣẹ si awọn alakoso lorileede Naijiria.

Enoh sọ pe ajọ to n ri si fifi kẹkẹ sare ni Naijiria, “nipasẹ ẹgbẹ Ese to wa ni Europe ti wọn si n ṣiṣẹ papọ pẹlu ileeṣẹ kan niluu Germany ni kẹkẹ ‘Track Bike’ kan ṣoṣo fun Ese wa.

“Igbesẹ yii lo waye lẹyin ti wọn le orileede kan lọ sile, ti wọn si wa rii pe Naijiria nikan lo tun peregede lati yege fun ikopa ninu idije naa.

“O ṣeni laanu pe, anfaani yii nilo irinṣẹ miran lati fi kopa, gẹgẹ bo ti ṣe ri ni ẹka fifi kẹkẹ sare. Fun are sisa ti wọn yan Naijiria fun yii, irinṣẹ pataki kan ṣoṣo ti wọn buwọ lu ni wọn maa lo. O maa gba wa ni ọpọlọpọ oṣu lati gbe wọle lẹyin ti a ba ti san owo fun.”

Nibi ifọrọwerọ kan l’Ọjọbọ, Aarẹ to n ṣakoso ere idaraya fifi kẹkẹ sare ni Naijiria (NCF), Giandomenico Massari jẹ ko di mimọ pe ikọ Naijiria maa n lo kẹkẹ wọn lati fi kopa ninu idije ni.

O sọ pe ohun to ṣẹlẹ ni pe nigba ti wọn yoo fi gba ipe fun anfaani tuntun naa lati ọdọ ICU, awọn ikọ wọn ti wa ni Paris fun idije ọhun.

Giandomenico sọ pe ẹnikan ṣoṣo to yege fun idije ọhun naa lo tun yege fun anfaani tuntun yii, ṣugbọn ti yoo nilo irinṣẹ lati lo, ti wọn si gbọdọ gba aṣẹ lọwọ Olympics ko to di pe o bẹrẹ sii lo o.

“Fun gbogbo irinṣẹ Olympics ti wọn n lo, wọn gbọdọ aṣẹ. Fun idi eyi, kẹkẹ wa, eyi to yẹ fun ọna ti wọn fẹẹ lo ko si nilẹ, bi ko ṣe pe eyi to yẹ fun ọna ti tẹlẹ nikan lo wa nilẹ.

“Iye ti kẹkẹ naa jẹ ko ni iṣoro ti a ni. Yoo gba ọpọlọpọ oṣu ko to di pe wọn gbe e wa lẹyin ti a ba ti san owo fun un. Fun idi eyi, ko si ọna lati ri kẹkẹ naa.”

Ṣugbọn sibẹ, a ko le padanu irufẹ anfaani nla bayii fun Naijiria, igba akọkọ si ree ti Naijiria yoo maa peregede fun opopona kẹkẹ sisare ninu idije Olympics, paapaa ọna yii. Idi ree ti a fi sa ipa wa lati kopa nibẹ.”

Aarẹ naa tun ṣalaye siwaju pe wọn ba ikọ ẹgbẹ Castelli ti Ese wa pẹlu wọn sọrọ lati fun un ni kẹkẹ ti wọn buwọ lu fun Olympic naa, eyi ti yoo lo lati fi kopa, bi bẹẹ kọ, Naijiria ko nii kopa rara.

O ni asiko perete ni Naijiria ri gba, nitori pe Egypt to peregede tẹlẹ ni wọn ja kuro lọna, ko to di pe wọn pe aṣoju Naijiria lati kopa, to si jẹ aarin ọsẹ meji pere ni.

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 2