Ìdí rèé tí ọkàn àwọn Mùsùlùmí tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì kò fi balẹ̀ lórí rògbòdìyàn UK

“Ohun ti awọn eeyan n pe ni rogbodiyan...ohun ni ẹmi n pe ni ikọlu.”
Agbegbe Stockport to wa ni Greater Manchester ni Huma Khan n gbe, ọkan lara awọn ile-ẹkọ girama lagbegbe naa lo si ti n ṣiṣẹ olukọ.
Rogbodiyan to si n foju han kaakiri ilẹ Gẹẹsi ti jẹ ko pinnu lati maa tẹsiwaju, ṣugbọn sibẹ ọkan rẹ ko balẹ.
“O ba mi lẹru nigba ti mo kọkọ rii. Mo ro pe rogbodiyan to n ṣẹlẹ naa ti jẹ ko di ohun ti awọn eeyan n pe ni ifẹhonuhan, eyi ti emi n pe ni ikọlu, bot ilẹ jẹ pe o ti di awuyewuye lori ayelujara, eyi to jẹ pe irọ ni, o mu aya mi ja.” O sọ fun BBC.
O sọ pe oun ko nii yi ilana iṣẹ ohun pada, bo tilẹ jẹ pe ọkan rẹ ko balẹ.
“Mo dagba sinu ki wọn doju kọ mi, ki wọn maa kọ lu mi nitori ẹsin ti mo nigbagbọ ninu ẹ, bi mo ṣe ri, ati bi mo ṣe n mura.
“Mi o le maa bẹru...ṣugbọn sibẹ, mo maa n wa ni ifoya ni gbogbo igba ti mo ba n lọ sile mi. Ṣe maa tun maa wa ninu ewu ni?
Ifarabalẹ Eerie

Rogbodiyan to n fa iafọkanbalẹ le da alaafia ilu laamu, bo tilẹ jẹ pe ki ṣe gbogbo igba.
Nigba ti a ṣabẹwo si ile itaja igbalode Salford to wa lẹyin ilu Manchester, si ẹkun ariwa ilu naa, lọsan ọjọ Iṣẹgun to bọ si.
Ọpọ awọn olokoowo ni wọn gba lamọran lati tilẹkun ileeṣẹ wọn, nitori ti wọn ro pe ifẹhonuhan naa le tan kalẹ titi de irọlẹ ọjọ naa.
Awọn to n kọja lọ le fara gba a, pẹlu bi awọn ọlọpaa ṣe n da awọn eeyan lọna lati yẹ ara wọn wo, paapaa awọn to n lo iboju ṣugbọn ti wọn ko darapọ mọ ifẹhonuhan.
Ni ẹkun Guusu Manchester, ko fẹẹ si iyatọ kankan nibẹ.
Agbegbe Moss Side jẹ ile fun awọn to gbookan lagboole ẹsin musulumi ti wọn wa lati ilẹ Asia, Middle East ati Afrika. Lọjọ Iṣẹgun, awọn ile ounjẹ igbalode kun fun onibara rẹpẹtẹ.
Pupọ awọn to n gbe lagbegbe naa ni wọn sọ pe awọn ri aabo lawọn ileeṣẹ wọnyi to wa lagbegbe wọn. Ṣugbọn sibẹ, wọn sọ pe ohun to n ṣẹlẹ naa n ba wọn lẹru.
"Ọdun 2018 ni mo wa lati Syria, emi pẹlu mọlẹbi mi ri ibi abo idasi nibi," Alaa, to n ta iwe Arabiiki ni Manchestewr lo sọ bẹẹ.
"Awọn iṣẹlẹ to n ṣẹlẹ bayii ko sọ daadaa nipa ọjọ iwaju. Fun awọn asiko kan, mo n gbe igbe aye ti ko pariwo. Mi o fẹ ki wọn ṣe ipalara fun mi mọ,” o sọ fun BBC.

Ogun lo le Abdul Hakeem kuro ni Somalia ni ogun ọdun sẹyin. Ọkan rẹ ko tun wa balẹ mọ pẹlu bi ẹgbẹ ajafẹtọ kan ṣe tun n doju kọ ẹgbẹ awọn musulumi bayii.
"Bi awọn ẹgbẹ mejeeji yii ba fi pade, wọn le da wahala nla silẹ, koda ogun nla. Ohun to si le mi kuro ni Somalia wa si Manchester ree."
Alaa tun n kọminu lori bi awọn musulumi ṣe pe fun didaabo bo awọn mọṣalaṣi, okoowo ati awọn ile - nipa lilo iwa ipa to ba yẹ.
“Mi o gba pẹlu eyi. Niṣe lo yẹ ki eyi maa waye nipa atilẹyin awọn alakoso ati ijọba ti wọn ti fọkan awọn musulumi balẹ pe ko nii si wahala kankan fun wọn, ati pe aabo wa.
“Mo ro pe o uẹ lati daabo bo awọn mọṣalaṣi wa, ka si tun daabo bo igbagbọ wa ninu ohun ti a gbagbọ, a wa n fun awọn miran ni ọrọ sọ lati maa pe wa ni agbebọn ati alakatakiti.”
Huma Khan tun sọ pe eyi yoo ko ipa to pọ ninu igbesi aye awọn ọjọwẹwẹ to ṣẹṣẹ n dagba.
“Ohun ti mo ṣakiyesi pe o le nibẹ ninu ọrọ pẹlu awọn ibatan mi ni pe, wọn ṣi kere bii ọmọ ọdun mejila ati mẹwaa ati meje. Mo ni lati maa ṣalaye lati fọkan wọn balẹ pe ohun to n ṣẹlẹ lawọn adugbo wa ni Manchester ki ṣe ohun ti ọpọ awọn eeyan to wa nibi jẹ."
‘Mi o tii ri ija ẹlẹyamẹya nibi ri’

Saeed, toun naa jẹ ojulowo ọmọ Syria wa si ilẹ Britain lọdun mẹta sẹyin, to si ti lo igba pipẹ lati rin irin ajo kaakiri ilẹ Europe.
“Mo ti lọ kaakiri ilẹ Europe, bẹẹ si ni mo ni iwe irinna ilẹ Swedish. Mo mọ ọn mọ wa si ilẹ England nitori pe wọn bọwọ fun igbagbọ lai yọ ẹnikẹni silẹ. Kristẹẹni, Musulumi ati Juu - gbogbo wọn ni wọn n gbe pẹlu alaafia.
“O ba mi lẹru gidi nigba ti mọ gbọ pe ija ẹlẹyamẹya lo n waye. O n ba wa lẹru nigba ti a kọkọ gbọ nipa iroyin ọhun, eyi kii ṣe ohun to n waye tabi ti a ti ri tẹlẹ. Mo ti n gbe nibi lati bi ọdun mẹta, awọn eeyan naa si dara.
“Wọn le ran yin lọwọ, wọn ran mi lọwọ nipa ede, to fi jẹ pe nigba ti mo ri iroyin naa, o ba mi lẹru si ohun ti mo n foju ri gangan."
Rogbodiyan naa ti tan kaakiri ilu to wa ni England and Northern Ireland latigba ti wọn ti gun awọn ọmọdebinrin mẹta ni Southport to wa lẹkun Ariwa England lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu keje.
Iroyin ẹlẹjẹ to si n tan kaakiri lo tubọ jẹ ki rogbodiyan ọhun da ija ẹlẹyamẹya silẹ, to fi jẹ ki wọn m,aa kọlu awọn to wa aabo wa sibẹ.
Lẹyin ikọlu ọbẹ to waye ni Southport, ọpọ awọn iroyin ẹlẹjẹ ori ikanni ayelujara lo mu ki wọn maa ṣe ikọlu si awọn to wa farapamọ si ilẹ Gẹẹsi, paapaa awọn to gba ori omi wọle. Iroyin ẹlẹjẹ miran tun sọ pe musulumi ni ọkunrin naa.
Lẹyin eyi, rogbodiyan to bẹ silẹ ti da rukerudo ti ko tii ṣẹlẹ ri silẹ lẹyin eyi to waye lọdun 2011 nibi awọn ọlọpaa yinbọn pa Mark Duggan.
“A ti ri awọn rogbodiyan kẹyin ti n lọ bi ogun ọdun” Ọmọwe Dr Jawad Amin, alaga Greater Manchester Muslim Safety Forum lo sọ eyi.
“Ohun to n kọ wa lominu nipa iṣẹlẹ yii ni pe iroyin ẹlẹjẹ lo daa silẹ, paapaa awọn ti wọn n fẹ ki iru nnkan bayii waye lori ayelujara,” o sọ fun BBC.
“Boya Musulumi lo ṣe ikọlu yii tabi ohun kọ, ko yẹ ko jẹ ohun ni yoo fa rogbodiyan to wa nilẹ.”















