Mo tọrọ àforíjìn fún bí Ìkọ̀ Nàìjíríà ṣe lulẹ̀ ní ìdíje Olympics - Minisita

Aworan Minisita ere idaraya lorilẹede Naijiria, John Enoh

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Minisita fun ere idaraya, John Enoh ti tọrọ aforijin lọwọ gbogbo ọmọ orilẹede Naijiria lori bi ikọ Naijiria to lọ si idije Olympic to waye ni Paris lorilẹede France se kuna lati gba ami ẹyẹ kankan wale.

O ni Aarẹ Bola Ahmed Tinubu buwọlu owo toto N12bn fun idije, to si jẹ pe pẹlu gbogbo owo naa, ikọ Naijiria ko ri nkankan mu pada wa le.

Ninu ọrọ to gbe sori opo ayelujara X rẹ, Minisita se ileri lati wa ọna abayọ si gbogbo ohun to fa iṣubu ikọ Naijiria ni idije Paris.

Elere idaraya ọgọrin ni Naijiria fa kalẹ fun idije Olympic sugbọn wọn kuna lati gba ami ẹyẹ kankan wale.

“Idije Olympic ti wa sopin, mo gba pe o yẹ ki a se ju bi a se ti se lọ.

“Mo ni lati tọrọ aforijin lọwọ awọn eeyan to gba ruku ti wa, ki wa si ọna abayọ saaju ki idije Paralympic to bẹrẹ.

“Bi a se n pada si ile yii, a ni lati se gbogbo nnkan lati ri pe irufẹ yii ko waye ni ọjọ iwaju ati a o si se atunse si yiyan awọn olori lati tukọ awọn ajọ ere idaraya wa.

“Gbogbo nnkan to yẹ ka se gẹgẹ bii ileeṣẹ ijọba ni a se sugbọn esi idije yii ko dun mọ wa ninu rara.”

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Lẹ́yìn ò rẹyìn, ọwọ́ òfo ni ikọ̀ Nàíjíríà bá kúrò ní ìdíje Olympics tó wáyé nílùú Paris

Aworan awon elere idaraya Naijiria

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Gbogbo iko elere idaraya ti wọn lọ ṣoju orileede Naijiria nibi idije Olympics to n lọ lọwọ niluu Paris ni wọn ti jabọ patapata, lai ri ife ẹyẹ kankan gba lati fi gbe ogo ilẹ wọn ga.

Pabo ni ireti gbogbo ọmọ Naijiria ti wọn ti n foju sọna fun aṣeyọri nla nibi idije Olympics naa ja si, pẹlu bi gbogbo awọn aṣoju ti wọn gbojule ṣe padanu sọwọ awọn alatako wọn.

Hannah Reuben padanu ija oni kilogiraamu mẹrindinlọgọrin ti awọn obinrin, eyi ti wọn pe ni (Women’s Freestyle 76kg fight) laarọ ọjọ Satide.

Reuben padanu sọwọ akẹgbẹ rẹ, Enkh-Amaryn Davaanasan ti Mongolia ni ipele ‘round of 16’, to si jẹ adanu nla fun ilẹ Guusu Afrika.

Ikọ Naijiria lọ si Olympics lori bi wọn ṣe n tayọ lẹka ere idaraya ti wọn yan laayo, ati bi wọn ṣe peregede. Ilẹ Naijiria fi orukọsilẹ fun idije mejila, ṣugbọn to ṣeni laanu pe wọn ko gbe ogo wọn yọ lasiko yii gẹgẹ bi wọn ti n ṣe tẹlẹ.

Ẹ dun ọkan lo jẹ fun ọpọ ọmọ Naijiria nitori awọn kudiẹ-kudiẹ to waye, eyi to jẹ ki wọn pada sile lọwọ ofo lai gba ife ẹyẹ kankan.

Ọdun 2012 si ni iru nnkan bayii ti ṣẹlẹ gbẹyin nigba ti wọn lọ kopa ninu idije ere idaraya to waye ni London.

Bi awọn ikọ Naijiria ko ṣe fakọyọ lo jẹ iranti ti awọn eyi to ti waye sẹyin lọdun 1952 ni Helsinki, Melbourne ti ọdun 1956, Rome lọdun 1960, Mexico ti ọdun 1968, Moscow lọdun 1980, ati Seoul to waye lọdun 1988 nibi ti Naijiria ko ti gba ife ẹyẹ kankan.

Biliọnu mejila naira la gbọ pe Aarẹ Bola Tinubu buwọ lu fun awọn ikọ Naijiria ti wọn fẹ lọ ṣoju nibi idije to waye ni Paris ọhun. Biliọnu mẹsan naira fun awọn to ti kopa tẹlẹ, ati biliọnu mẹta fun awọn to tun n lọ.

Afojusun ori papa ja si ofo

Bi a ba wo bi idije ọhun ṣe lọ, Naijiria kopa ninu oriṣiriṣi idije ori papa bii ere sisa, bọọlu ẹlẹsẹ ati ti ọlọwọ, to fi mọ awọn miran, eyi ni wọn maa n gba ife ẹyẹ nibẹ ju.

Favour Ofili ti fi itan balẹ gẹgẹ bi ọmọ Naijiria ti yoo kọkọ wọ ipele to kangun si aṣekagba nibi idije ere sisa ti igba mita (200m) ni Atlanta 1996.

Bo tilẹ jẹ pe o tayọ gidi pẹlu iṣẹju mejilelogun le iṣẹju aaya marun (22.05), ko pada de ipele aṣekagba.

Ninu ere sisa 200m, Udodi Chudi Onwuzurike naa tun de ipele to kangun si aṣekagba, nigba ti akẹgbẹ rẹ toun n sa 400m, Ezekiel Nathaniel naa kọja ipele ọhun.

Ireti ọmọ Naijiria tun ja kulẹ nibi ẹka ti 4x400m ti awọn ọkunrin nigba ti wọn ja wọn danu lori ẹsun wi pe wọn tapa si ofin ati ilana.