Ẹ máa gbóríyìn fún iṣẹ́ ọlọ́pàá láwùjọ– Adejobi

Oríṣun àwòrán, Muyiwa Adejobi/X
Olumuyiwa Adejọbi to jẹ agbẹnusọ agba fun ileeṣẹ ọlọpaa orileede Naijiria ti gba awọn araalu lamọran lati maa gbe oriyin fun iṣẹ eto aabo ti wọn yan laayo gẹgẹ bii ọlọpaa nitori wọn n sa gbogbo agbara wọn.
Adejobi sọ pe ko ṣee ṣe fun awọn ọlọpaa lati mu gbogbo awọn ọdaran ati awọn oniwa ibajẹ lawujọ tan lẹẹkan ṣoṣo, bi ko ṣe pe iranlọwọ araalu ni yoo jẹ ki ọwọ tẹ awọn amookunṣeka naa.
Adejobi lo sọrọ naa lori ikanni ayelujara ‘X’rẹ lasiko to n fesi si ọrọ awọn eeyan ti wọn pe fun fifi ọwọ ofin mu awọn afurasi ajinigbe ti wọn n jaye familete-n-tutọ pẹlu owo ti wọn n pa nidi iwa ibajẹ lori ayelujara.
Ninu ọrọ ti Adejobi kọ soju opo rẹ, o ni: “A ko le rọwọ to gbogbo ọdaran tan lẹẹkan ṣoṣo. Sibẹ, ẹ gbọdọ maa yin wa fun awọn diẹ ti a ti fi ọwọ ofin mu. Ojoojumọ la n rọwọ to wọn, ni ọpọ yanturu.
“Ileeṣẹ ologun ati ọlọpaa n gbiyanju agbara ati akitiyan wọn. Ẹ gbọdọ maa ri ipa ati akitiyan ileeṣẹ agbofinro, ki ẹ si maa gboriyin fun wa.
“A ni lati maa ṣiṣẹ lori ajọṣepọ nipa idasi ẹnikọọkan lati gbogun ti iwa aisi eto aabo ati oniruuru iwa ọdaran ni Naijiria.
“Ohun kan to daju ni pe ko si ọdaran to maa lọ lai jiya. Ẹ ṣeun.”
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post











