Ẹgbẹ́ agbàbọ́ọ̀lù wo ló kún ojú òṣùwọ̀n láti gba ife ẹ̀yẹ Premier League kúrò lọ́wọ́ Man City ní sáà yìí?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lati bi saa mẹsan an bayii ni ọpọ amoye nipa ere bọọlu ti n darukọ pe ẹgbẹ agbabọọlu ni o ṣeeṣe ko tun gba ife ẹyẹ premier league saaju ko to di pe wọn bẹrẹ idije naa.
Ẹgbẹ agbabọọlu Man City ti gba ife ẹyẹ ligi ilẹ Gẹẹsi ni ẹ mẹfa laarin ọdun meje, to fi mọ gbigba ni igba mẹrin lerawọn.
BBC ṣe akojọpọ awọn ẹgbẹ agbabọọlu to ṣeeṣe ki wọ ija mọ Man City lọwọ lati gba ife ẹyẹ ligi saa yii.
Arsenal

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ipo keji ni Arsenal gbe ni saa to kọja, ami meji ni Man City fi leke wọn.
Saa keji lerawọn ni Man City ti ja irawo Arsenal si ipo keji.
Pẹlu bi ikọ Arsenal ti se ra agbabọọlu tuntun, Riccardo Calafiora lati Bologa fun owo toto #42m, ọpọ awọn ololufẹ wọn lo n ri irufẹ iyatọ ti waye ni saa yii.
Balogun ikọ naa, Martin Odegaard sọ ni opin saa to kọja pr awọn ti ẹgbẹ agbabọọlu naa pada, ti o si da oun loju pe Arsenal ni yoo gba ligi ti saa yii.
Liverpool

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ipo kẹta ni wọn pari si ni saa to kọja.
Igba akọkọ ree lati ọdun 2015/16 ti wọn yoo bẹrẹ saa wọn laisi Jurgen Klopp to jẹ olukọni wọn.
Saa to kọja ni Klopp kede oun yoo fi ipo oun silẹ gẹgẹ bii olukọni Liverpool, ti wọn si ti kede Arne Slot gẹgẹ bii ẹni ti yoo rọpo rẹ.
Ọpọ awọn amoye nipa ere bọọlu ko ri Liverpool gẹgẹ bii ẹgbẹ agbabọọlu to le gba ligi ni saa yii sugbọn igbagbọ wa pe ara le ti ọwọ wọn wa.
Aston Villa

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ipo kẹrin ti wọn pari si ni saa to kọja.
Wọn ni anfani lati kopa ninu idije Uefa Champion League.
Olukọni Unia Emery yii ẹgbẹ agbabọọlu naa pada, ti wọn ya ọpọ eeyan lẹnu .
Ọpọ agbabọọlu tuntun lo ti darapọ mọ ẹgbẹ agbabọọlu Aston Villa, to si da pe awọn naa ko wa sere ni saa yii
Sugbọn n jẹ wọn le gba ife ẹye ligi ilẹ Gẹẹsi ni saa yii.?
Chelsea

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ipo kẹfa ni wọn pari si ni saa to kọja
To ba ṣeeṣe fun ikọ yii lati ra gbogbo agbabọọlu lagbaye, wọn yoo ra gbogbo wọn sugbọn n jẹ saa yii yoo yatọ fun wọn ?
Wọn rọpo Olukọni wọn, ti wọn si ti kede olukọni tuntun Enzo Maresca, olukọni to gba ligi keji fun ẹgbẹ agbabọọlu Leicester ni saa to kọja.
Ọpọ agbabọọlu tuntun lo ti darapọ mọ wọn bi Kiernan Dewsbury-Hall, Tosin Adarabioyo, Pedro Neto ati bẹbẹ lọ.
Bakan naa ni wọn ta awọn agbabọọlu bii Thiago Sliva, Hakim Ziyech, Ian Maatsen, Lewis Hall ati Omari Hutchinson.
Agbabọọlu to fi gbogbo gba jẹ balogun fun ikọ naa, Conor Gallagher naa ti darapọ mọ Atletico Madrid.
Ọpọ awọn amoye ko ri ẹgbẹ agbabọọlu gẹgẹ bii ẹgbẹ agbọọlu to le pintu ni saa nitori pupọ awọn agbabọọlu wọn lo jẹ ọdọ sugbọn yoo jẹ aṣeyọri nla fun wọn ti wọn gbiyanju lati gbe ipo ti wọn fun wọn ni anfani lati kopa ninu idije Uefa Champion League.
Manchester United

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Bo ti lẹ jẹ pe wọn bẹrẹ saa yii pẹlu ifẹsẹwọnsẹ Community Shield, eyi ti wọn padanu sọwọ Man City, ọpọ awọn ololufẹ si ni igbagbọ ninu wọn.
Erongba ọpọ ni pe olukọni wọn yoo padanu iṣẹ rẹ ni ipari saa to kọja sugbọn ẹgbẹ agbabọọlu naa pinnu lati wa pẹlu Erik ten Hag.
Awọn agbabọọlu bi Joshua Zirkzee ati Leny Yoro lo ti darapọ mọ ikọ Man Utd.
Igbagbọ awọn amoye ni pe Man Utd le dara ti awọn agbabọọlu wọn ko ba farapa.















