'Ilé onídìrí àti aṣaralóge la fi n pa ìbànújẹ́ wa rẹ́, àmọ́ wọ́n tún ti fi òfin dè é'

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Bẹrẹ lati ọjọ Aje, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Keje, awọn obinrin ni orilẹ-ede Afghanistan ko ni le lọ si ile onidiri lati ṣe irun ori wọn l’ọṣọ mọ, nitori pe ijọba Taliban ti fi ofin de e lorilẹ-ede naa.
Bi ọjọ ṣe n sun mọ ti ofin naa yoo bẹrẹ iṣẹ, BBC ba awọn obinrin mẹta sọrọ nipa rẹ.
Zarmina, ẹni ọdun mẹtalelogun, to jẹ iyawo ile sọ fun BBC pe ṣaaju asiko yii, oun kii le jade kuro nile lai si alamojuto to tẹle oun. O ni ṣugbọn oun fi ọgbọn bẹ ọkọ oun lati fun oun ni anfaani lati lọ si ile onidiri ni ẹẹmeji si ẹẹmẹta laarin ọdun.
Awọn ọrọ pẹẹpẹpẹ to ma a n ba awọn obinrin ẹgbẹ rẹ sọ nile onidiri lo ma n mu u ni ọkan le, ni iru awujọ bi ti Afghanistan ti wọn ti n tẹ awọn obinrin mọ ẹrẹ̀.
Ọmọ ọdun mẹrindinlogun ni Zarmina wa nigba to ṣe igbeyawo. Botilẹ jẹ pe o pari ile ẹkọ girama, awọn ẹbi ọkọ rẹ ko gba ko lọ si fasiti.
'Omije kun oju gbogbo wa'

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Nigba to lọ sile onidiri ni oṣu to kọja, bi Zarmina ṣe n fi aró kun irun ori rẹ lọwọ, ni iroyin ibanujẹ jade pe Taliban ti fi ofin de ile onidiri.
“Ipaya mu ẹni to ni ile onidiri naa, o si bẹrẹ si ni sunkun. Oun lo n pa owo ti ẹbi rẹ fi n gbọ bukaata.”
Awọn obinrin bi ẹgbẹrun lọna ọgọta lo n ṣe iṣẹ onidiri ati atoriṣe jakejado Afghanistan.
“Niṣe ni gbogbo wa bu sẹkun, lai le sọ ohunkohun.”
Agbegbe Kandahar, ni Gusu Afghanistan nibi ti taliban fi ṣe olu ileeṣẹ ijọba rẹ, ni Zarmina n gbé.
O ni nnkan to wọpọ ni pe awọn ọkunrin ma n fi ofin de awọn ọmọ wọn obinrin láti má lọ sile onidiri, tabi ṣe oju wọn loge.
“Ọpọ obinrin lo n wọ hijaabu ati ẹ̀kú to bo oju wọn, nigbakugba ti wọn ba jade saarin igboro. A si ti gba a gẹgẹ bi ara àṣà wa.”
Ọdun meji sẹyin ni ọkọ Zarmina padanu iṣẹ gidi to n ṣe, ilu miran lo si ti n ṣisẹ bayii. Zarmina funra rẹ n ri owo diẹdiẹ lati ara kikọ awọn ọmọde.
Madina
Ẹni ọdun mejilelogun ni Madina, o si n gbe ni Kabul.
Lootọ ni kii jade kuro nile, amọ ko si iroyin to n lọ lori ayelujara nipa iṣaraloge ati ẹwà, ti kii gbọ́.
O ni lilọ si ile onidiri ati aṣaraloge n mu ki igbeyawo rẹ tuntun si lojoojumọ.
“Ọkọ mi fẹran lati ma a ri irun ori mi ninu oriṣiriṣi àwọ̀, ati ti mo ba gé si oriṣiriṣi ọna.
“Funra rẹ lo ma n gbe mi lọ si ile onidiri, ti yoo si duro de mi titi ma a fi ṣe irun mi tan – pẹlu iwuri si lo fi ma n sọ pe mo rẹwa pupọ, eyi to ma n mu inu mi dun.”
Tẹlẹ ni Madina ni afojusun lati di agbẹjọro, ṣugbọn awọn Taliban ko faaye gba awọn obinrin lati lọ si Fasiti mọ́. Lati igba naa, ko ri iṣẹ kankan ṣe nitori pe ọpọlọpọ iṣẹ ni wọn ti fi ofin de awọn obinrin lati má a ṣe.
Madina ma n bo ori rẹ to ba jade, ọkọ rẹ ati awọn obinrin mi ninu ẹbi rẹ nikan si lo ma n ri irun ori rẹ.
Ile aṣaraloge lo da igba rere pada fun mi

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ko ṣe e ma ni, ni ile onidiri fun Somaya, to n gbe niluu Mazar-i-Sharif. Ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn ni.
Lọdun mẹta sẹyin, oju rẹ jona lẹyin ti ẹrọ amulegbona to wa ninu yaara rẹ gbina. Lati igba naa, ko ni irun irun oju ati ipenpeju mọ.
“Mi o le wo oju mi mọ, nitori pe mo burẹwa pupọ.
“Fun ọpọlọpọ oṣu si ni mi o fi jade kuro nile, nitori mo lero pe oju mi ni awọn eeyan n wo, ti wọn si n fi mi ṣe yẹyẹ.”
Lootọ ni oogun oyinbo wo ọgbẹ́ rẹ́ sàn, ṣugbọn ile aṣaraloge ni wọn ti da ayọ̀ ọkàn pada fun.
“Mo lọ si ile aṣaraloge lati ṣe ‘microblading’ (eyi jẹ tatuu ọlọjọ pipẹ ti wọn ma n fa si oju). O si jẹ ki oju mi rẹwa si.
“Ti mo ba wo irun ipenpeju mi, ẹkun ayọ ni mo ma n sun. Ile aṣaraloge ni wọn ti da igba rere pada fun mi.”
Nigba ti Taliban gba ijọba, pupọ ninu awọn ile onidiri ni ko ṣilẹkun wọn mọ. Idi ni pe ofin ti de awọn obinrin lati ma a fi oju wọn han, Ẹ̀kú to bo gbogbo ara ati oju wọn ni wọn n wọ̀ bayii, ipenpeju wọn nikan ni eeyan n ri.
Somaya ni iwe ẹri imọ ijinlẹ ‘Masters Degree’ ninu itọju aarun ọpọlọ, o si n ṣiṣẹ oludamọran fun awọn to ni aarun ọpọlọ.
Iye awọn obinrin to n wa si ọdọ rẹ ti pọ̀ si i lati igba ti Taliban ti n gbe oriṣiriṣi ofin jade lodi si awọn obinrin.
Ọpọ awọn obinrin lo da bi Somaya, to ni àpá ati ọgbẹ́ ni oju wọn ṣugbọn wọn o ni owo lati ṣe iṣẹ ab
Fun iru awọn obinrin bẹ, ile aṣaraloge ni wọn ti n pa ironu ati ibanujẹ wọn rẹ, ti wọn si n ni ireti.
(Orukọ gbogbo awọn obinrin yii ni a yipada)














