Wọ́n fi ẹ̀sùn kan àwọn ọkùnrin tó na obìnrin yìí dojú ikú tí wọ́n tún ju òkú rẹ̀ s' ódò adágún ilé ìtura

Oríṣun àwòrán, CHINYERE CHIZZY/FACEBOOK
Ìròyìn ti jáde lẹ́yìn iku arabinrin kan to lọ si ile ijo ile itura kan eyi to si ti mu ijọba gbe ile itura naa ti pa nipinlẹ Anambra.
Ijọba gbe agadagodo ti gbogbo ilẹkun ile itura Cosmila Hotel and Suites ni ilu Awka Ìpínlẹ̀ Anambra lẹyin ti wọn fi ẹsun kan awọn ọkunrin kan pe wọn lu arabinrin Chinyere Awuda titi doju iku pẹlu iranlọwọ mọnija ile itura naa.
Iroyin to n fo kiri amọ ti a ko tii le fidi rẹ múlẹ̀ ni pe Chinyere Awuda ti ọpọ mọ si Chizzy to jẹ ọmọ bibi Ìpínlẹ̀ naa kagbako iku tirẹ lalẹ ọjọ ti awọn ọkunrin naa lù ú ni alubami lẹyin eyi ti wọn ri oku rẹ.
Bakan naa ni iroyin tun ni oludari ile ijo naa ko jẹ ki awọn ẹṣọ gba a silẹ, dipo ki wọn ṣe èyí, ṣe ni wọn pa ina lati le jẹ ki lilu ti wọn n lu u tẹsiwaju.
Lẹyinrẹ́ ni wọn lọ ju oku rẹ sinu adagun omi “swimming pool” to wa ninu ile itura naa eyi ti wọn ti pa ti fun ọjọ pipẹ.
Ẹṣẹ wo ni Chinyere ṣẹ?

Oríṣun àwòrán, CHINYERE CHIZZY/FACEBOOK
Akọroyin BBC gbera lọ si ile itura naa nibi ti iṣẹlẹ iku arabinrin Chinyere ti ṣẹlẹ ni aarọ Ọjọ Iṣẹgun
ṣugbọn wọn ko jẹ ko wọle sinu ọgba naa lati ṣe iṣẹ rẹ.
Titi di akoko yii, ko ti ye ẹnikẹni ohun to jẹ ẹṣẹ Chinyere ni pato eyi to mu ki awọn ọkunrin naa ro o pe o yẹ ki awọn da sẹria fun un.
Bakan naa, ko ye idi ti mọnija ile ijo naa paṣẹ fun awọn ẹṣọ alaya gbangba lati duro maa woran bi iṣẹlẹ naa ṣe n ṣẹlẹ.
Ẹwẹ, kọmisọna fun eto igbafẹ ni ipinlẹ Anambra, Don Onyenji to paṣẹ pe ki wọn ti ile itura naa pa sọ pe iṣẹlẹ yii ba oun ninu jẹ gidi gan.
O ni titi awọn ọlọpaa yoo fi pari iwadii wọn ni ile itura ọhun yoo fi wa ni titi pa.
Bakannaa, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Anambra ni awọn ti n tan ina wa ohun to ṣokunfa iku arabinrin naa.
Agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ naa, Tochukwu Ikenga sọ fun ileeṣẹ iroyin BBC Igbo lori ẹrọ ibaraẹnisọrọ pe awọn ti gbọ si iṣẹlẹ naa.
“Lootọ ni a gbọ nipa rẹ. A si n ṣe iwadii rẹ lọwọ, Ikenga sọrọ.















