Àìsàn Diphteria tún pa ènìyàn mẹ́wàá ní Kaduna, ohun tí a mọ̀ rèé

Oríṣun àwòrán, Ministry of Health Kaduna
Ileeṣẹ eto ilera ni ipinlẹ Kaduna ti kede pe aisan Diphteria to n ja kiri bayii ni Naijiria ti pa eniyan mẹwaa ni agbegbe Kafanchan, ni ipinlẹ naa.
Ninu atẹjade ileeṣẹ naa ni wọn ti ni awọn to ni aisan yii fi awọn ami kan han ki wọn to gbẹmi mi.
Awọn ami ọhun ni ara to gbona janjan, ọna ọfun didun ati ọrun to wu.
Alaga ijọba ibilẹ Kafanchan, Ọga Najib Muazu ni ajakalẹ arun naa bẹ silẹ ni agbegbe wọn ti eniyan mẹwaa si ti gbẹmi mi.
Muazu ni lati ọjọ meji ṣẹyin ni wọn ti ti gbogbo ọja ati ileẹkọ lati dẹkun ajakalẹ arun naa.
Ijọba ipinlẹ Kaduna ni iṣẹlẹ naa kọ awọn lominu, ti wọn si ni ki ijọba sa ipa wọn lati gbogun ti ajakalẹ arun naa.
Awọn eleto ilera to ti wa ni agbegbe naa kilọ fun awọn eniyan lati yẹra fun awọn aisan, ki wọn bo ẹnu wọn ti wọn ba n sin tabi wukọ, ki wọn si rii pe eroja ara wọn jipepe.
Ki ni aisan Diphteria yii gan?
Dipheteria jẹ kokoro aifojuri kan to maa n ṣe akoba fun ọna ọfun ati imu.
Iwosan wa fun aisan Diphteria, aṃọ ti o ba ti kọja ala, o le ba ọkan, kindinrin ati eroja ara jẹ.
Amọ pẹlu bi iwosan ṣe wa to, aisan naa si ma n ba awọn ọmọde.
Awọn ami Diphteria ni agọ ara eniyan ni:

Oríṣun àwòrán, Ministry of Health Kaduna
Kẹlẹbẹ bi ewe arọ to bo ọna ọfun
Ki ọna ọfun maa dun eniyan
Aile mi daradara abi mimi gulegule
Dida ikun ni imu
Ara gbigbona ati otutu
Ara riro, ki o maa rẹ eniyan
O ṣeeṣe ki egbo wa ni ara eniyan, eleyii ti o ma n waye fun awọn eniyan to ba n gbe agbegbe ti ko ni omi to mọ gaara.
Imọran ni pe ki eniyan lọ si ileewosan ni kiakia ti oun tabi awọn ọmọ rẹ ba ti sunmọ ẹni to ni aisan naa.
Ki lo n fa aisan Diphteria?
Aisan to ma n fa Diphteria ni bacteria Corynebacterium diphtheriae ma n fa lẹyin ti o ba ti pọju ni ara.
O si ma n tan ka nipa omi ara eniyan to ba ni i, ninu ikọ tabi ti eniyan to ba ni aisan naa ba n wu ikọ.
Paapaa aisan naa ma n tan kalẹ nibi ti ooru abi eniyan ba pọ.
Iṣoro aisan Diphteria
Ti wọn ko ba tete se eto iwosan fun ẹni to ba lugbadi aarun naa, o le fa
aile mi daradara.
Ki eniyan ni aisan ọkan eleyii to lee fa ki ọkan tete da iṣẹ silẹ, to si le gbẹmi eni naa.
Bi o se le dena aisan Diphtheria
Ki eto iwosan to wa fun aisan Diphteria, o jẹ aisan to wọpọ laarin awọn ọmọde tẹlẹ ri.
Nibayii, abẹrẹ ajẹsara ti wa lati dena rẹ, ti iwosan pipe si wa fun un - Fun idi eyi, tete lọ ileewosan too ba ko firi rẹ!












