Ìdí rèé tí mo fi kúnlẹ̀ níwájú Pásítọ̀ Adeboye - Soun Ogbomoso sàlàyé

Oríṣun àwòrán, Oba Ghandi Olaoye/Facebook
Yoruba bọ, wọn ni ti ko ba nidii, obinrin kii jẹ Kumolu, ohun lo difa fun Soun ilu Ogbomoso, Ọba Afolabi Ghandi Olaoye, Orumogẹgẹ Kẹta to ṣalaye idi to fi kunlẹ niwaju Pasitọ Enoch Adeboye ijọ Redeemed Christian Church of God lasiko to gori oye.
Ọpọ ọmọ Yoruba lo tu itọ soke fi oju gba a pe ko yẹ ki ori ade kunlẹ niwaju alufaa kankan tori enikan ki i fi ori ade tẹlẹ.
Ọrọ naa di ohun tawọn eeyan n gba bi ẹni n gba igba ọti lori itakun ayelujara papaa julọ lasiko ti Oba Ghandi ṣẹṣẹ gori oye.
"To ba jẹ oniṣẹṣe ni mi, ti mo si kunlẹ niwaju babalawo, ko si ẹni to maa sọ nkankan"
Nigba ti o n sọrọ laipẹ yii ninu ifọrọwerọ kan to ṣe pẹlu Teju Babyface, Kabiyesi naa ṣalaye pe "to ba jẹ pe oniṣẹṣe ni mi, ti mo si kunlẹ niwaju babalawo, ko si ẹni to maa sọ nkankan.
Mo kunlẹ niwaju Adari ijọba Redeem, Pasitọ Adeboye tori mo ṣẹṣẹ gori oye nigba naa ni.
Mi o le kunlẹ siwaju Pasitọ Adeboye mọ bayii ayafi ti o ba ni idi pataki kan loku.
Amọ, mi o le tọrọ aforijin lori wi pe mo kunlẹ niwaju Pasitọ Adeboye."
Ọba Ghandi ṣalaye siwaju si wi pe nigba to ya l'awọn eeyan ri fọto Soun to ti waja, Ọba Jimoh Oladunni Oyewumi Ajagungbade kẹta, nibi to ti kunlẹ niwaju alufaa ijọ Aguda ti o si tun ṣi fila rẹ niwaju alufaa rẹ pẹlu.

Oríṣun àwòrán, Teju Baby face
"Ooni ati Alaafin naa ti kunlẹ ri ni sọọsi"
Ọba Olaoye ni fọto mii tun jade eyi to ṣafihan bi Alaafin Oyo to ti waja, Ọba Lamidi Adeyemi ṣe kunlẹ ninu ṣọọṣi niwaju pasitọ.
"Musulumi gan an l'awọn ọba yii o, ti wọn n kunlẹ niwaju awọn alufaa o.
Bakan naa ni fọto Ooni Ile Ife naa jade nibi to ti kunlẹ fun adura," Ọba Ghandi ṣalaye.
Soun Ogbomoso ni ilara lo n ṣe awọn to n tabuku oun pe oun kunlẹ niwaju alufaa.
Kabiesi naa ni oun o ni tọrọ aforijin lori wi pe oun kunlẹ niwaju alufaa, ati wi pe ti o ba yẹ ki oun ṣe bẹẹ lọjọ iwaju, oun ko ni ro o lẹẹmeji ki oun to kunlẹ.
O pẹ ti mo ti mọ pe ayanmọ Ghandi ni lati jẹ ọba - Pasitọ Adeboye
Ṣaaju ni Pasitọ Adeboye ijọ Redeem ti sọ wi pe o ti pẹ ti oun ti mọ pe Ọba Ghandi Olaoye, Soun ti ilu Ogbomoso wa saye lati jẹ Ọba ilu Ogbomoso.
Adeboye nigba to n soro ni Beulah Baptist Conference, Ogbomoso ni bi ti isin idupe ti wọn gbe kalẹ lati se ayẹyẹ gbigba ọpa aṣẹ Soun ti ile Ogbomoso sọ wi pe oun mo wí pe Oba Ghandi yóò jẹ Ọba.
Bakan naa lo salaye idi ti ko fi da pasitọ Afolabi Ghandi Adeoye duro nigba to fi to leti pe o fẹ dupo Soun ti ile Ogbomoso.
Pasito Adeboye ni "nigba ti o wa sọdọ mi lati so fun mi nipa oye Oba Soun ti ilẹ Ogbomoso to ṣi silẹ, mo so fun un pe ki o lọ gbadura.
“O pada wa sọ fun mi wi pe oun ko tii gbọ nnkan kan, ti mo tun sọ fun un wi pe ki o tun pada lọ gbadura, lẹyin igba die lo pada wa.
“O sọ fun mi wi pe, Ọlọ́run ti sọrọ, oun gbọ ohun rẹ wi pe ki oun dupo Soun ti ilẹ Ogbomoso nigba naa ni mo sọ fun un pe ko lọ nitori wi pe Ọlọ́run ti kadara rẹ yoo jẹ Ọba.
“Ti mo ba sọ wi pe ko ma jẹ Soun ti ilẹ Ogbomoso, ti Ọlọrun si ni ko jẹ nkọ?
“Ọrọ Ọlọrun si ṣe pataki ju ti temilọ.”
Ninu iwaasu rẹ, Adeboye rọ Ọba Ghandi Olaoye lati gba awọn eniyan mọra ki o si gbe jẹ ki alaafia ati isokan jọba niluu Ogbomoso.
Lẹyin iwaasu rẹ, Pasito Adeboye fi ororo ya Ọba Ghandi Afolabi ati iyawo rẹ si mimọ, o si gbadura fun un pe alaafia ati ilosiwaju yoo jọba lasiko rẹ gẹgẹ bi Soun Ogbomoso.















