Èyí ni ìdí tí Bàbà Mohbad àtàwọn ẹbí rẹ̀ fi da èsì àyẹ̀wò ikú gbájúmọ̀ akọrin náà nù

Oríṣun àwòrán, Instagram/mohbad
Awọn ẹbi Ilerioluwa Aloba (Mohbad), olorin sufee-taka to doloogbe ti kọ esi ayẹwo tijọba ipinlẹ Eko ṣe fun oku ọmọ wọn silẹ. Wọn ni tuntun aladaani lawọn n fẹ.
Nibi ipade oniroyin ti ẹbi Aloba, eyi ti baba Oloogbe, Joseph Aloba ati lọọya rẹ, Wahab Shittu ṣe lori ayẹlujara lọjọ Aje, ọjọ kẹtadinlogun oṣu kẹfa ọdun 2024 yii ni wọn ti fi ero ọkan wọn han.
Ẹka iroyin Premium Times ti wọn jọ ṣepade naa royin pe ẹbi Mohbad sọ pe esi tijọba Eko mu wa tako ireti awọn, ati tawọn ọmọ Naijiria, pẹlu bo ṣe jẹ pe otitọ ko foju han lẹyin rẹ.
Ṣe ṣaaju ni oluyẹwo oku to yẹ oku Mohbad wo nileewosan ijọba Eko, LASUTH, Sunday Osiyemi, ti sọ pe oun ko ri ohun kan tọka si to pa oloogbe lẹyin ayẹwo oku rẹ.
Osiyemi sọ ninu oṣu karun-un ti ayẹwo naa waye, pe o ṣee ko jẹ pe bi oku Mohbad ṣe ti jẹra, ati awọn oogun ti oloogbe lo ṣiwaju iku rẹ ni ko jẹ ki ohun to pa a farahan lẹyin ayẹwo.
Àwọn ẹ̀sùn wo ni ẹbí Aloba fi kan ìjọba Eko lórí èsì àyẹ̀wò òkú Mohbad?

Oríṣun àwòrán, Instagram/Mohbad
Wahab Shittu ti i ṣe lọọya ẹbi Aloba, ẹni to gba ẹnu ẹbi wọn sọrọ, sọ pe,
’’Awa agbẹjọro ẹbi Aloba, n fi asiko yii fi aidunnu wa han si esi ayẹwo oku Oloogbe Ileri Oluwa Aloba (Mohbad).
‘’A ko le gba esi yii wọle rara. A fẹẹ mọ ibi ti wọn ti ṣe ayẹwo naa.
‘’Esi to kuna lati sọ ohun to pa ọmọ wa ko le jẹ itẹwọgba.’’
Bakan naa ni wọn ni awọn gba igbiyanju lati ridi otitọ gbọ, nigba ti wọn ni orilẹ-ede Amẹrika ni wọn ti ṣe ayẹwo naa .
Ẹbi Mohbad sọ pe ṣugbọn si iyalẹnu, iwe iroyin Punch gbe e lọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu karun-un ọdun 2024 yii, pe ilẹ Amẹrika loun ko ṣe ayẹwo kankan fun oku Mohbad.
Wọn lo n ru awọn loju, bi orukọ ile ayẹwo ‘National Medical Services Laboratories’ to wa ni Pennsylvania, ni USA, ṣe han lori esi ayẹwo naa, ti wọn si n sọ pe wọn ko ṣe e nibẹ.
“ O n ruju wa loju si i ni bi iyatọ ṣe wa ninu ibi ti wọn ti ṣayẹwo yii.
‘’ Gbogbo ọmọ Naijiria fẹẹ mọ ajọṣepọ to wa laarin ile ayẹwo DNA Eko ati NMS to wa l’Amẹrika pẹlu ITSI ti wọn lo ṣayẹwo naa lorukọ ijọba Eko.’’
Ohun tí ẹbí Mohbad ń fẹ́

Oríṣun àwòrán, Instagram/Mohbad
Gẹgẹ bi wọn ṣe wi, ẹbi Aloba lawọn fẹ ayẹwo oku naa mi-in ti yo waye nibudo to ṣee fọkan tan to si lorukọ lagbaaye.
Wọn ni gbogbo ilana ayẹwo igbalode ni ki wọn fi ṣe e, ati pe oku ogun ọdun gan-an n ṣe ayẹwo ti esi gidi si n jade.
Ẹbi Aloba sọ pe oku ọmọ awọn ko ti i pẹẹ debi ti wọn ko ni i ridii ohun to pa a.
‘’A fẹ ko jẹ pe awọn akọṣẹmọṣẹ lati oke okun yoo lọwọ si ayẹwo tuntun yii, bi wọn ba da si i, esi naa yoo ṣee gbagbọ ju eyi to wa nilẹ lọ.
‘’Ẹbi Aloba fẹẹ mọ abajade ayẹwo naa lẹkun-un rẹrẹ, otitọ inu ṣe pataki lọtẹ yii lati mọ ohun to ṣẹlẹ gan-an .
‘’A fẹ ko ya, a ko ri akoko fi ṣofo lori ọrọ yii. A fẹ ki ayẹwo naa waye kiakia, ki ẹbi si ri esi kiakia.
‘’Ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria ko ṣeun to lori ọrọ yii, iwadii wọn ko kun to lori ẹjọ ipaniyan ti wọn gbe dani.’’
Lakootan, ẹbi Mohbad ni ki ọga ọlọpaa pata lorilẹ-ede yii, Kayọde Ẹgbẹtokun, funra rẹ kopa ninu iwadii ohun to pa Mohbad.
Wọn ni ọrọ iku ọmọ yii ti pẹ nilẹ ju lai lojutuu, o ti fẹẹ maa gbọn mawọn agbofinro lọwọ, eyi si n ko ibanujẹ ba ọkan awọn gẹgẹ bi abiyamọ.
Tẹ o ba gbagbe, ọjọ kejila, oṣu kẹsan-an ọdun 2023 ni Mohbad ku lẹni ọdun mẹtadinlọgbọn (27).
Iku ọhun di wahala, ko sẹni to le fidi ohun to pa a mulẹ titi dasiko yii.
Baba rẹ sare sin in lọjọ keji, ṣugbọn ijọba pada hu oku naa lati mọ ohun to pa a gan-an.














