Àyájọ́ Juneteenth: Wo bí àyájọ́ fífòpin sí òwò ẹrú ṣe bẹ̀rẹ̀ ní orílẹ̀èdè Amẹ́ríkà

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Author, By Jeremy Howell
- Role, BBC World Service
Ni ọjọ kọkandinlogun oṣu kẹfa ọdọọdun ni isinmi lẹnu iṣẹ fun ayajọfifopin si owo ẹru bẹrẹ lorilẹede Amẹrika lati igba ti Aarẹ Joe Biden ti buwọlu ofin Juneteeth National Independence Day lọdun 2021.
Ki ni ipilẹ ayajọ Juneteenth yii gan, bawo lo ‘ṣe di ọjọ isinmi lẹnu iṣẹ ati wi pe, bawo gan ni o ṣe le gbadun ajọyọ ayajọ yii?
Ki ni àyájó Juneteenth?
Ni ọjọ kọkandinlogun oṣu kẹfa ọdun 1865, lẹyin oṣu diẹ ti ẹkun ariwa ilẹ Amẹrika bori ẹkun gusu nibi ti owo ẹru ti gbilẹ lasiko ogun ti abẹle ilẹ Amẹrika – awọn ẹru ni agbegbe bii Galveston, Texas gba ominira wọn.
Igbesẹ ominra yii waye lẹyin ọdun meji abọ ti aarẹ orilẹede Amẹrika nigba naa, Abraham Lincoln kede pe gbogbo awọn ẹru to wa lawọn ipinlẹ to n faake kọri, ti gba ominira.
Igbesẹ ti Ọgagun Gordon Granger gbe lati rii pe aṣẹ ti aarẹ Lincoln pa yii fidimulẹ ni ipinlẹ Texas ni ọpọ ri gẹgẹ bi igbesẹ gan an to fi opin si owo ẹru nitootọ.
Ki lo de ti wọn fi wa n pe e ni ‘Juneteenth?Ọrọ yii jade nipa asopọ orukọ oṣu kẹfa lede oyinbo, “June” ati ọjọ kọkandilogun lede oyinbo kan naa “nineteenth” papọ.
Ṣe Ọjọ isinmi lẹnu iṣẹ apapọ ni Juneteenth jẹ?
Bẹẹni – lootọ o gba ọpọlọpọ ọdun ki eyi to ṣẹlẹ.
Awọn ipinlẹ lo kọkọ yan ayajọ naa gẹgẹ bi ọjọ isinmi lẹnu iṣẹ ni ipinlẹ Texas lọdun 1980. Ni awọn ọdun to tẹlee, gbogbo awọn ipinlẹ, yatọ si South Dakota, lo wa bẹrẹ si gbe igbesẹ lati yan an gẹgẹ bi ọjọ isinmi lẹnu iṣẹ lawọn ipinlẹ wọn.
Nigba to wa ni ipo Sẹnetọ fun Illinois, Barack Obama, ati akẹgbẹ rẹ kan gbe abadofin kan kalẹ siwaju ile igbimọ aṣofin nibẹ lati sọ ọjọ naa di ọjọ isinmi apapọ, ṣugbọn ile ko fọwọ si abadofin ọhun nigba naa – koda lẹyin igba naa to di aarẹ orilẹede Amẹrika.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lẹyin iṣẹlẹ iwọde ‘Black lives matter’ kaakiri orilẹede Amẹrika lọdun 2020 ni abadofin naa bẹrẹ si ni fi ẹsẹ rinlẹ.
Nigba ti ọjọ kọkandinlogun oṣu kẹfa ọdun 2021 n ṣe kẹrẹkẹrẹ sunmọle, awọn ile igbimọ aṣofin apapọ̀ mejeeji lorilẹede Amẹrika gbe igbesẹ kiakia lori abadofin naa, ti aarẹ Biden si buwọlu di ofin.
Oun ni ayajọ isinmi lẹnu iṣẹ tuntun ti wọn yoo kede lorilẹede naa lẹyin ti wọn kede ayajọ iranti Martin Luther King Jr Day lọdun 1983.
Lara awọn to fọnrere idasilẹ ayajọ isinmi naa ni Opal Lee, ẹni ọdun mọkandinlaadọrun to fi ẹsẹ rin lati Texas lọ si Washinghton DC lọdun 2016 lati pe akiyesi awọn aṣofin sii ki wọn si tun le tete gbe igbesẹ to tọ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Bawo ni wọn ṣe n ṣe ajọyọ ayajọ Juneteenth yii?
Gbogbo awọn ileeṣẹ ijọba ni o maa n wa ni titipa fun ayajọ Juneteenth, bẹẹ naa lawọn ile iṣẹ aladani to ba fẹ darapọ pẹlu.
Fun awọn oṣiṣẹ ijọba ipinlẹ, awọn alaṣẹ ipinlẹ wọn ni yoo sọ boya ọjọ isinmi lẹnu iṣẹ ni tabi ọjọ ayajọ nikan ki wọn to le mọ boya wọn yoo gba owo isinmi lẹnu iṣẹ lọjọ naa tabi rara.
Bi wọn ṣe n ṣe ajọyọ yii n yatọ lati ibi kan de ikeji jakejado orilẹede Amẹrika. Ni awọn ipinlẹ kan, iwọde alaafia, ajọyọ ita gbangba ati wẹjẹwẹmu nibi ti awọn eeyan ti maa n pin ounjẹ ti wọn si ṣe oniruuru ere idaraya.
Bakan naa ni eto orin kikọ, iwe kika ati isin ni ṣọọṣi pẹlu maa n waye lawọn ibi kan.
Awọn kan a tilẹ maa lo ayajọ naa lati fi ba awọn ile itaja to jẹ pe awọn alawọ dudu lo ni wọn dowo pọ.
Ki ni pataki ayajọ Juneteenth?
Fifopin si owo ẹru, ko dopin iwa ẹlẹyamẹya, to bẹ to fi jẹ pe lawọn ọdun ijijangbara to tẹ lee oniruuru awọn ofin ẹlẹyamẹya, ti wọn pe ni ofin Jim Crow to fi aala si aarin awọn alawọdudu atawọn alawọ funfun ati fifi iwọn si ẹtọ wọn.
Awọn abajade ofin wọnyii ṣi wa nilẹ.
Iku George Floyd, Breonna Taylor atawọn alawọ dudu miran lọwọ awọn ọlọpaa ti mu ki ọpọ iwọde waye tako iwa ẹlẹyamẹya nibẹ.
















