‘Àrùn Sickle Cell dá mi dùbúlẹ̀ àìsàn fún ọdún kan gbáko, mi ò lè ṣe ọ́pọ̀ ohun tí mo máa ń ṣe mọ́’
Ọkunrin kan, to ni arun foniku-fọladide ti ọpọ mọ si ‘SS,’ Dotun Oladipupo, ti sọ pe ko rọrun lati maa gbe pẹlu arun naa rara.
Dotun lo sọ ọrọ ọhun ninu ifọrọwerọ kan pẹlu BBC Yoruba, nibi ti oun ati iyawo rẹ ti tu pẹrẹpẹrẹ bo ṣe n gbe pẹlu arun naa.
Dotun, to jẹ olukọ imọ akọroyin nile ẹkọ giga MAPOLY, niluu Abeokuta sọ pe arun ọhun ti ṣọṣẹ lara oun to bẹẹ ti awọn dokita fi irin si ẹsẹ oun lẹyin to da oun dubulẹ fun bii ọdun kan gbako.
Gẹgẹ bii ohun to sọ, asiko to wa ni ọmọ ọdun meje lo to gbọnju pe oun ko dabi awọn ọmọde akẹgbẹ oun.
O ni awọn obi oun maa n sọ fun oun lọdun naa lọhun pe ki oun ma gba bọọlu, ki oun ma si maa ṣe erepa, nibẹ ni oun ti kọkọ funra.
Bo tilẹ jẹ oṣiṣẹ eto ilera ni iya to bi Dotun, wọn ti bi tan ki awọn obi rẹ to mọ pe o ni arun SS lara.
“Mo dubulẹ ṣaisan fun odidi ọdun kan gbako”

Oríṣun àwòrán, bbc
Lọdun 2016 ni Dotun ni aisan nla kan to ku diẹ ko gbẹmi rẹ eyii to mu ko lo nnkan bi ọdun kan lori idubulẹ.
O ni “igba keji ti mo maa gba ẹjẹ sara niyẹn, a gba ẹjẹ kinni titi dori apo ikẹsan an, ko si iyatọ, mo ṣaa wa loju kan nibẹ.
“Mo wa loju kan, mi o le dide, mi o le joko, mi o le tọ fun oṣu kinni, oṣu keji, oṣu kẹta, oṣu kẹrin, oṣu kẹfa, ọdun kan.”

Oríṣun àwòrán, bbc
Dotun sọ pe aisan naa ko lọ titi di igba ti wọn ṣe iṣẹ abẹ fun oun lorilẹede India lati fi irin sinu ẹsẹ oun, nitori aisan naa ti ṣakoba fun egungun ẹsẹ to gbe ara oun duro.
O ni ọpọ nnkan ti oun le ṣe tẹlẹ ni oun ko le ṣe mọ bayii.
Amọ ninu gbogbo wahala yii iyawo rẹ, duro ti i to si n tọju rẹ.
O gba awọn obi lamọran pe ki wọn jẹ ki ọmọ wọn to ba ni irufẹ ipenija SS yii ṣe iṣẹ ti ọkan rẹ ba yan laayo, ki wọn ma si da dubulẹ soju kan.
Wo fidio oke yii fun ẹkunrẹrẹ ohun ti Dotun ati iyawo rẹ ba BBC Yoruba sọ nipa ipenuja arun SS.
















