Ààrẹ Biden fẹ́ fún tọkọ taya 500,000 ní ìwé ìgbélùú Amẹ́ríkà láti lè ṣiṣẹ́

Aworan Joe Biden

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Gbogbo eto lo ti to bayii fun Aarẹ Joe Biden orilẹede Amẹrika lati kede eto kan eyi ti yoo fun ẹgbẹẹgbẹrun tọkọ taya ni iwe igbeluu lati le ṣiṣẹ.

Awọn oṣiṣẹ igbimọ alaṣẹ ijọba Amẹrika lo fidi ọrọ yii mulẹ.

Eto yii yoo fun ọpọlọpọ tọkọ taya ti ko ni iwe igbeluu lọwọ lanfani lati le maa ṣiṣẹ ni Amẹrika, dipo ti ijọba fi le wọn pada si orilẹede abinibi wọn.

Ọrọ awọn to n wa ṣiṣẹ lorilẹede Amẹrika lati awọn orilẹede agbaye mii jẹ ọkan lara awọn ọrọ to ti n jẹyọ lọdun yii ṣaaju idibo gbogbogbo Amẹrika to n kan ilẹkun.

Koda, Aarẹ Biden gan an ti paṣẹ ṣaaju pe kawọn ẹṣọ alaabo dẹkun bi ọgọọrọ eeyan ṣe n gba ibode Mexico wọle si Amẹrika.

Iru awọn tọkọ taya wo ni yoo janfani iwe igbeluu ti Biden fẹ kede yii?

Awọn ti yoo jẹ anfani eto yii lawọn tọkọ taya ti wọn ti n gbe ni Amẹrika fun ọdun mẹwaa, o kere tan.

Ile iṣẹ aarẹ Amẹrika sọ pe tọkọ taya to le ni ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta(500,000) ni yoo jẹ anfani eto naa.

Aarẹ Biden ti ṣeleri ṣaaju wi pe ijọba oun ko ni jẹ ki eto wiwọle si Amẹrika nira fawọn eeyan.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Iṣẹ iwadii ti fihan pe ọrọ yii wa lara awọn ohun to n kọ awọn oludibo lominu ṣaaju eto idibo gbogbogbo ti yoo waye ninu oṣu Kọkanla ọdun 2024 yii.

Ileeṣẹ aarẹ ni igbagbọ pe eto yii yoo ṣe anfani fun ẹgbẹrun lọna aadọta awọn ọdọ ti ọjọ ori wọn ko ju ọdun mọkalelogun lọ ti obi wọn ṣe igbeyawo pẹlu ọmọbibi orilẹede Amẹrika.

Eto yii jẹ ọkan gboogi ti yoo ṣe iranwọ fun ọpọ eeyan to n gbe orilẹede Amẹrika ti wọn ko ni iwe igbeluu.

Iru eto to tun dabi eleyii ni eto aabo Daca ti aarẹ ana ilẹ Amẹrika, Barack Obama kede lọdun 2012 fawọn ọmọde to wa lorilẹede Amẹrika nigba naa.

O kere tan awọn ọmọde to le ni 530,000 ti wọn gbe wa si Amẹrika nigba naa ni eto yii ko jẹ ki ijọba Amẹrika da pada si ibi ti wọn ti gbe wọn wa.

Awọn ti yoo janfani eto yii ni ọdun mẹta lati forukọ silẹ lati di ọmọ ilu Amẹrika.

Bakan naa ni wọn yoo lanfani lati gba iwe ati ṣiṣẹ fun ọdun mẹta l’Amẹrika.

Awọn to koju oṣunwọn lati forukọ silẹ fun eto naa yoo lanfani lati ṣe bẹẹ laipẹ yii, gẹgẹ ọgagba kan lẹnu iṣẹ ọba ṣe fidi rẹ mulẹ.