Èèyàn mẹ́sàn án kú, 78 farapa nínú ìjàmbá ọkọ̀ lásìkò ọdún Iléyá – FRSC

frsc

Oríṣun àwòrán, frsc

Ileeṣe to n ri si irinkede oju popo ni Naijiria, FRSC, ti sọ pe eeyan mesan an lo ku,ti awọn mejidinlọgọrin mii si farapa ninu ijamba ọkọ lasiko ọdun ileya.

Adari ileṣe naa lẹka Osogbo, Leye Adegboyega, lo sọ beẹ ninu atẹjade kan.

O ni ijamba ọkọ mẹtala ọtọtọ lo waye lasiko ọdun naa, ninu eyii to kan ọkọ mọkanlelogun ati eeyan 128, ti mọkanlelogoji ninu awọn eeyan naa ko farapa.

Nigba to n ṣalaye nipa iṣẹ ti wọn ṣe lasiko ọdun naa, Adegboyega sọ pe oṣiṣẹ 3,018 lawọn da sita pẹlu ọkọ 57, to fi mọ ọkọ to n gbe awọn alaisan marun un.

Gẹgẹ bii ohun tọ sọ, awọn oṣiṣẹ to ara wọn sawọn ibi to ṣe koko lati le tete doola awọn to ba ni ijamba ọkọ.

Lara awọn ipinlẹ ti awọn oṣiṣẹ wọn wa lasiko ọdun naa ni ipinlẹ Osun, Ondo ati ipinlẹ Oyo.

O fikun pe wọn tun ṣiṣẹ lawọn ọna maroṣe bii Ife-Ilesa, Ilesa-Ipetujesa-Akure, Sagamu-Ore-Benin ati ọna marosẹ Ibadan-Oyo-Ogbomoso.

Yatọ si awọn to ṣeṣe lasiko ọdun Ileya, FRSC tun fi ṣikun ofin mu awọn dẹrẹba to tapa si ofin irinna oju popo ni Naijiria.

O ni “a mu eeyan 737 to ṣe si ofin oju popo fun ẹsun 766 ọtọtọ eyii to le yọri si ijamba oju popo.

“A ṣe idanilẹkọọ 219 fun awọn awakọ kaakiri awọn ileesẹ iroyin, ibudokọ, ṣọọṣi, mọṣalaṣi atawọn ibomii to ṣe koko.”

Adegboyuega wa parọwa si awọn to n lo oju popo lati maa ṣe pẹlẹ nitori ẹmi ko laarọ.