Kí ló ṣokùnfà ikú akẹ́kọ̀ọ́ fásitì Akungbà yìí lẹ́yìn tó lọ ìṣọ́ òru?

AAUA

Oríṣun àwòrán, AAUA

Iwadii ti bẹrẹ lori iku akẹkọọ fasiti Adekunle Ajasin, AAUA, to wa niluu Akungba-Akoko, nipinlẹ Ondo.

Akẹkọọ ọhun, Ayandare Modupe, ni a gbọ pe o wa ni ipele karun un ni ẹka imọ Agronomy nile ẹkọ naa.

Ṣadede ni awọn akẹgbẹgbẹ akẹkọọ naa ri oku rẹ lẹba ile ijọsin to n lọ, eyii ti ko fi bẹẹ jina si ọgba ile ẹkọ naa niluu Akungba-Akoko.

Iroyin ni iku ọdọbinrin naa waye lẹyin ti wọn pari iṣọ oru tan nile ijọsin naa to jẹ ti alaṣọ funfun.

Agbẹnusọ ẹgbẹ awọn akẹkọọ, SUG, Olaogbebikan Noble, sọ ninu atẹjade kan pe awọn ti gbe igbesẹ lati ṣawari ohun to fa iku oloogbe naa, awọn si ti fi ọrọ ọhun to awọn ọlọpaa leti Akungba.

Ninu atẹjade kan ti Noble fi lede, o ni “inu wa bajẹ gidigi lori iku ọkan lara wa, Ayandare Modupe, to jẹ akẹkọọ ipele karun un ni ẹkọ imọ imọ Agronomy.

“A ti fi ọrọ naa to awọn ọlọpaa leti, iṣẹ si ti bẹrẹ lati mọ kulẹ kulẹ ohun to ṣokunfa iku rẹ.

“A fẹ fi da yin loju awọn agbofinro yoo ṣe iṣẹ wọn bii iṣẹ, idajọ ododo yoo si waye.”

“To ba ni ẹnikẹni to ba mọ ohunkohun nipa iṣẹlẹ naa, ko ma ṣai fi to ẹgbẹ awọn akẹkọọ leti.”

Gbogbo akitiyan lati kan si awọn alaṣẹ AAUA lo ja si pabo.

BBC kan si ileesẹ ọlọpaa ipilẹ Ondo, agbẹnusọ rẹ, Funmilayo Odunlami sọ pe lootọ ni iṣẹlẹ naa waye, awọn si ti bẹrẹ iwadii lori rẹ.