Ẹbí Aduke Gold fọnmú mọ́ iléwòsàn UCH lọ́wọ́ pé àìbíkítà rẹ̀ ló rán ọmọ àwọn lọ sọ́run

Aduke Gold

Oríṣun àwòrán, adukegold1/Instagram

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 11

Lẹyin iku akan, ariwo ẹnu lo kan ni ọrọ iku Oloogbe Aduke Ajayi Morounkola da bayii nitori awuyewuye to n su yọ lẹyin iku rẹ.

Idi ni pe awọn ẹbi Aduke Gold ti n fọnmu lori iku aitọjọ to mu ẹmi oloogbe naa lọ, ti wọn si n fi ẹsun kan ọsibitu UCH, n’Ibadan, pe aibikita rẹ lo pa ọmọ awọn.

Ẹbi Aduke Gold ni awọn dokita ati Nọọsi ile iwosan UCH ko tete kọbi ara si itọju oloogbe naa, ti wọn ko si fun ni itọju to peye, lo se ku sile iwosan naa.

Bakan naa ni wọn tun n fi ẹsun kan ileewosan naa pe bi Aduke se ku tan, dokita to tun yẹ ko buwọ lu iwe ẹri iku rẹ tun sọ pe o rẹ oun, oun ko le sọkalẹ lati tọwọ bọ iwe naa.

Wọn ni wọn tun da oku rẹ duro fun ọpọlọpọ wakati, ti wọn ko jẹ ki awọn gbe e, afi nigba ti ọrọ naa di ariwo.

Fidio kan si ti n ja ranin lori ayelujara nipa bi awọn ẹbi Aduke Gold se n pariwo nile iwosan UCH.

Awọn ẹsun yii n ja ran-in nilẹ lọwọ, ni fidio ibi ti awọn eeyan kan ti n pariwo pe UCH ti papa gbe oku silẹ tun jade sita.

"UCH kọ̀kọ́ fi Aduke Gold ráre, wọn kò fún un ní ìtọ́jú tó péye, ìgbà tó ku ọjọ́ méjì tí yóò kú ni wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí tọ́jú rẹ̀"

Lati mọ ohun to n ṣẹlẹ gan-an nipa itọju Aduke Gold, BBC Yoruba ba Oluwafemi Isola tii se ayaworan Oloogbe Aduke sọrọ, ẹni to ṣalaye kikun nipa ọrọ yii.

Nigba to n ṣalaye ohun to ṣẹlẹ fun BBC Yoruba, Oluwafemi Isola, sọ pe,

‘’UCH ko fun Aduke Gold ni itọju to peye, nitori wọn ko mọ pe eeyan nla ni.

‘’Nigba ti wọn ṣẹṣẹ mọ pe eeyan nla ni, nigba naa ni wọn ṣẹṣẹ bẹrẹ si i tọju rẹ.

‘’ Nigba to ku ọjọ meji to maa ku, ti wọn ti waa mọ pe eeyan nla ni, nigba yẹn ni wọn ṣẹṣẹ waa n fun un ni itọju to peye.

‘’Wọn tun fi oku naa rare, a fẹẹ gba oku lọjọ Iṣẹgun, ọjọ keji to ti ku, wọn tun ni ka duro.

Wọn sọ fun wa pe dokita to yẹ ko buwọ lu iwe iku rẹ sọ pe o ti rẹ oun, oun ko le sọkalẹ lati ori oke. Wakati kan ni wọn ni ka fi duro tẹlẹ, o pada di ọpọlọpọ wakati mọ wa lọwọ.

‘’Igba ti a bẹrẹ si i pariwo le wọn lori ni wọn too gbe oku rẹ fun wa.’’

Nipa iroyin to sọ pe aisan kindinrin lo pa Oloogbe, Oluwafẹmi sọ pe, ‘’ o kan ṣe aarẹ ni, a dẹ gbe e lọ sileewosan’’

"Wọ́n ti gbé òku Aduke Gold dé sí ìlú Eko, ẹbi yoo joko lori ilana isinku rẹ"

Nigba to n fidi ẹ mulẹ pe wọn ti gbe oku Aduke Gold de si ilu Eko lati Ibadan, ayaworan rẹ yii sọ pe ẹbi yoo jokoo lori ilana isinku rẹ bayii .

Laarọ Ọjọruu, ọjọ kẹrinla, oṣu kẹjọ 2024 ti ọkunrin naa ba BBC Yoruba sọro lorii foonu, o ni, ‘’ Awọn ẹbi Aduke Gold yoo jokoo ipade lori isinku rẹ lonii, eyi ti emi naa yoo wa nibẹ pẹlu.’’

Oluwafẹmi fi kun un pe, abajade ipade naa ni yoo kede igba ati eto isinku, eyi ti ko ni i pẹ rara, yoo waye.

Kí ni UCH wi?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Bakan naa, BBC Yoruba tun kan si ileewosan UCH naa, lati gbọ awijare wọn lori ẹsun nla ti awọn ẹbi Aduke Ajayi fi kan wọn yii.

Alukoro ileewosan UCH niluu Ibadan, Abilekọ Obafunmilayo Adetuyibi, to ba BBC Yoruba sọrọ nipa ohun to ṣẹlẹ laarin ọsibitu yii ati awọn eeyan Aduke Gold.

Adetuyibi ni ’’Ki i ṣe ileewosan UCH ni Aduke Gold ti n gba itọju tẹlẹ o, ileewosan Olabisi Onabanjo to wa ni ipinlẹ Ogun ni wọn ti n tọju rẹ tẹlẹ, ibẹ ni wọn ti dari rẹ si ọdọ wa.

‘’Aduke de ọdọ wa ni ọjọ kẹta, oṣu kẹjọ ọdun 2024 yii, o si ku ni ọjọ kejila, oṣu kẹjọ, ko pe ọsẹ meji ti wọn n gbe kiri.

‘’Eyi ti wọn n sọ pe a ko tọju rẹ nitori a ko mọ pe eeyan nla ni, ko ri bẹẹ o.

‘’A ki i ya ẹni kankan ṣotọ gẹgẹ bii eeyan nla tabi talaka, itọju kan naa la maa n fun gbogbo ẹni to ba wa fun itọju.

Ko si ohun to jọ pe a ko tọju wọn rara, a ki i tori pe ẹnikan jẹ gbajumọ ka waa fun un ni itọju to yatọ si eyi ti a maa fun eeyan ti ko gbajumọ.

‘’Ko tiẹ si ẹni to mọ pe gbajumọ ni, wọọdu gbogbo-gbo lo wa titi to fi ku.

‘Ipo to lagbara ni aisan to ṣe Aduke wa nigba ti wọn gbe e de, a ko si tori rẹ kọ ọ, to ba jẹ pe itọju ko lọ daadaa, ariwo aa ti ta tipẹ’

Gẹgẹ bi Alukoro UCH ṣe tẹsiwaju, o ni, ‘’ ipo to lagbara gan-an ni aisan to ṣe oloogbe Aduke Gold wa nigba ti wọn gbe e de ọdọ wa, a ko si tori rẹ kọ ọ.

‘’O dun mi pe ọmọde ni ẹni to ku yii, ṣugbọn mo mọ pe to ba jẹ pa a ko tọju rẹ bo ṣe yẹ ni, ariwo aa ti maa ta tipẹ ṣiwaju asiko yii.

‘’Bi awọn ti wọn n pariwo yii naa ba le sọ ohun to ṣe e fun yin ni, ko ba yee yin gidi.

‘’Ilana iṣẹ iṣegun oyinbo ko gba wa laaye lati maa sọ ohun to ba ṣe alaarẹ fun araalu, ohun ti mi o ṣe le sọ ọ fun yin funra mi niyẹn.

‘’Awọn ẹni ti a n tọju jẹ wa logun gan-an, nitori a mọ pe ko si ẹni to fẹẹ ki eeyan oun to wa nileewosan ku. Gbogbo ariwo to ta lorii redio yẹn, emi o tiẹ laiki ka maa ba orukọ eeyan jẹ.

‘A kò fi òkú oloogbe rare o, eto to yẹ ka ṣe lo pọ, nọọsi ko si pọ mọ, japa ti ko ọpọloọpọ wọn lọ’

Nigba to n dahun si ẹsun kẹta ti i ṣe fifi oku rare, Obafunmilayo sọ pe ko ri bẹẹ.

O ni dokita kankan ko sọ pe o rẹ oun, awọn ti wọn wa ni wọọdu ti Aduke ku si kọ ni yoo kọ iwe rẹ.

Obinrin naa sọ pe UCH tobi pupọ, ẹka ọtọọtọ (units) lo si pin si. O ni awọn ẹka yii to yatọ lo fa a ti awọn igbesẹ ṣe maa n pẹ.

‘’Awọn ti wọn n wo ohun to pa a ni wọọdu yatọ si awọn ti yoo ṣe akọsilẹ tabi kọwọ bọ iwe iku naa, oun to jẹ ko pẹ niyẹn. Ko dẹ ki n ṣe pe o pẹ ju naa.

‘’Ati pe awọn naa n ṣe awọn eto inawo ti wọn yoo fi gba oku, ko dẹ ki i ṣe oju kan naa, ẹka ọtọọtọ ni. Ki i ṣe pe a fi oku rare rara.’’

Ohun kan to tun n fa iṣẹ sẹyin lọsibitu naa bi Obafunmilayo ṣe wi, ni ti awọn nọọsi ti ko to nnkan mọ lẹnu iṣẹ.

‘’Ẹyin naa ṣaa mọ pe japa ti ko ọpọlọpọ nọọsi lọ soke okun, wọn ko pọ mọ. Nigba mi-in, nọọsi meji lo maa wa lori alaisan rẹpẹtẹ. O ti rẹ nọọsi ti mo ba ni wọọdu lọjọ yẹn gan-an, o ti ṣiṣẹ gan-an.

‘’Awọn nnkan to ṣẹlẹ niyẹn.’’

Pẹlu awọn alaye yii, BBC yoo tun maa mu bo ba ṣe n lọ wa fun yin.

Àkọlé fídíò, Fídíò bí ọlọ́pàá Sharia ṣe ń wọ́ obìnrin kan nílẹ̀ torí kò lo ìbòrí dá ariwo sílẹ̀ ní Iran

Àlàyé rèé lórí ohun tó ṣekúpa Aduke Gold nílé ìwòsàn UCH, Ibadan

Oloogbe Aduke Ajayi (Aduke Gold)

Oríṣun àwòrán, Aduke Gold @Facebook

Àkọlé àwòrán, Oloogbe Aduke Ajayi (Aduke Gold)

Ọpọlọpọ iroyin lo ti gba ori ayelujara kan lori ohun to sokunfa iku ojiji gbajugbaja olorin ẹmi nni, Aduke Ajayi Morounkola, ẹni ti ọpọ mọ si Aduke Gold.

Aduke Gold jade laye ni alẹ ọjọ Aje, ọjọ kejila, oṣu kẹjọ ọdun 2024 yii, ni ile iwosan UCH, n’Ibadan, lẹyin to ṣe aisan.

Ilakaka ọpọ eeyan lati mọ ohun to pa akọrin ẹmi naa laipe ọjọ lo mu ki ikọ iroyin BBC Yoruba kan si akẹgbẹ rẹ kan, ti oun naa jẹ olorin ẹmi, Lekan Remilekun Amos.

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Amos ṣalaye pe ohun ko le sọ pe ohun pato to ṣe okunfa iku Aduke ree.

Amọ o ni oun gbọ pe wọn n ṣe itọju Aduke Gold nile iwosan UCH nilu Ibadan, to si gba itọju lati ipasẹ imọ ẹrọ ti a mọ si Dialysis.

Amos ni itọju Dialysis yii ni wọn maa n ṣe fun awọn alaisan to ba ni aisan kindinrin nile iwosan naa, ati pe o ti wa nibẹ fun bii ọsẹ meloo kan.

''Mo gbọ́ pé wọn ṣe 'Dialysis' fun Aduke Gold, UCH lo wa, UCH lo ku si''

Gẹgẹ bi Lekan Remilekun Amos ṣe wi, ‘’Nnkan to ṣẹlẹ ni pe emi gan-an o le sọ pe bayii ni, nnkan ti mo kan gbọ ni pe UCH lo wa, UCH dẹ lo ku si.

‘’Mo dẹ gbọ pe o da bii pe wọn ṣe Dialysis fun un, ẹnikẹni ti wọn ba dẹ ṣe Dialysis fun, o tumọ si pe nnkan naa ni i ṣe pẹlu kindinrin niyẹn.

Mi o wa le sọ nnkan mii pato to fa iku naa, nitori gbogbo wa o gbọ pe o ṣe aarẹ’’.

Amos ni oloogbe ko fi igba kankan sọ fun ẹnikẹni pe aisan n se oun.

O ni o yẹ ki oun ati Aduke jọ ṣe ere papọ ni ọjọ Ẹti to kọja, sugbọn o ya oun lẹnu pe ko wa.

“O yẹ ki Aduke Gold kọrin ni alẹ ọjọ Ẹti, ki emi kọrin temi ni ọjọ Satide, ni Lekki, ipinlẹ Eko, ṣugbọn ko wa lọjọ naa"

Amos tẹsiwaju pe “O yẹ ko kọrin ni alẹ ọjọ Ẹti, ki emi ṣe temi ni ọjọ Satide, ni Lekki, ipinlẹ Eko, ṣugbọn ko wa lọjọ naa.

‘’Nigba ti mo beere rẹ lọjọ Satide pe ṣe o wa lọjọ Ẹti, wọn ni ko wa, pe o sọ pe o rẹ oun diẹ. Emi ro pe bii ko kan rẹ eeyan lasan tabi stress ti awa olorin maa n koju ni, nitori ẹ ni mi o ṣe pe e.

“Ninu oṣu keje ni mo ri i gbẹyin, ni ori Oke Baba Abiye, Ẹdẹ, o si tun ṣere fun awọn eeyan nibẹ. Iyẹn ni nnkan bii ọjọ kẹrin si ikarun-un oṣu keje ọdun yii.

‘’Aduke ko jọ ẹni ti aarẹ kankan n ṣe lara rara, o ṣi duro rẹgi ni. Nigba to ku yii naa ni mo ṣẹṣẹ n gbọ pe o ti wa ni UCH fun igba kan’’

Nipa iru eeyan ti Oloogbe Aduke Gold jẹ,Lekan Amos sọ pe ọmọluabi ni.

O ni Aduke Gold ko ni iwa kan ti eeyan ko gbọdọ gbọ nipa rẹ, eeyan daadaa ni, o si ni ọgbọn atinuda, bẹẹ ni ilana mimọ lo fi n kọ orin rẹ.

Ọsẹ méjì ní Aduke Gold ló ní ilé ìwòsàn UCH kò tóó jáde láyé - Ayàwòrán rẹ̀

Oloogbe Aduke Gold

Oríṣun àwòrán, Aduke Gold @Facebook

Àkọlé àwòrán, Oloogbe Aduke Gold

Ninu ọrọ ti ayaworan Oloogbe Aduke Ajayi, Oluwafemi Isola, ba BBC Yoruba sọ, lo ti ṣalaye pe ọsẹ meji péré ni Oloogbe lo ni UCH ki iku too pa oju rẹ de.

Bakan naa lo sọrọ nipa ibaṣepọ awọn mejeeji, ati ipo ilera Aduke ki iku too mu u lọ.

“Bii ọsẹ meji sẹyin ni aisan yii bẹrẹ, o kan rẹ ẹ ni, a si gbe e lọ si ile iwosan UCH.

‘’Eeyan jẹjẹ ni, ki i ba ẹnikẹni ja, ti eeyan ba si ṣẹ ẹ, ki i di eeyan sinu, o maa jẹ ki o mọ lẹsẹkẹsẹ pe o ṣẹ oun. Ko fẹran wahala rara.

‘’Emi ni mo maa n saba ba a ya awọn fidio rẹ, a sun mọ ara wa daadaa.’’

Bakan naa ni ayaworan Oloogbe fidi ẹ mulẹ pe obinrin naa ko ti i lọkọ, tabi bimọ ti ọlọjọ fi de.

Ta ni Aduke Gold to jade laye?

Aduke Ajayi, ti ọpọ eeyan mọ si Aduke Gold ni wọn bi sile aye lọdun 1990 eyiun ọdun mẹrinlelọgbọn sẹyin.

Ilu Ileṣa, nipinlẹ Osun ni wọn ti bi Aduke Ajayi, ọmọ ọdun mẹrin lo wa to ti padanu awọn obi rẹ mejeeji.

Aduke Penkẹlẹ lo kọkọ n jẹ nigba to bẹrẹ iṣẹ orin nitori eeyan lẹgẹlẹgẹ to fẹlẹ lori itage ni.

Oloogbe Aduke Gold ri anfaani ẹkọ ọfẹ lati lọ si yunifasiti, nigba ti Ọnarebu Opeyemi Bamidele, kọmiṣọ́nna fun ọrọ awọn ọdọ ati ere idaraya nipinlẹ Eko nigba naa, fun ni ẹkọ ọfẹ.

Yunifasiti ipinlẹ Eko, (LASU) ni Aduke ti gboye ninu imọ nipa ibaṣepọ ilẹ okeere (International Relations).

Ọmọbinrin yii tun lọọ kẹkọọ nipa awọn ọmọde, o si gba ami ẹyẹ Diploma lati orilẹede United Kigdom.

Oloogbe Aduke Gold kẹkọọ nipa awọn akanda eeyan, nipa itọju ati ọsin ẹja, o kọ nipa iṣẹ olópò ati akara oyinbo ṣiṣẹ, yatọ si iṣẹ orin to sọ ọ di olokiki.

Oloogbe Aduke Ajayi ti awọn eeyan mọ si Aduke Gold, naa ri awọn iriri aye nla, o gbiyanju iwọn to le ṣe ko too di ẹni ti aye mọ.

Ohun to n dun ọpọ awọn ololufẹ rẹ nipa iku ọdọmọbinrin to di oloogbe naa ni pe o koju awọn ipenija pupọ lati kekere.

Oṣere tiata nni, Gbenga Adewusi ti awọn eeyan mọ si Baba Itunu, lo maa n gbe Aduke Penkele wa si ori eto to n ṣe lorii tẹlifiṣan ipinlẹ Eko ni nnkan bii ogun ọdun sẹyin.

Ori eto naa ni Aduke ti di mimọ fun aye, to si tun n kọrin nibi awọn isọji ṣọọṣi pẹlu awọn eto to ba fi ara pẹ ẹ.

Orin to kọ nibi isinku Baba Ara, olorin ẹmi, tubọ jẹ ko di mimọ.

Nigba ti okiki Aduke Pẹnkẹlẹ bẹrẹ si i kan, lo yi orukọ naa pada si Gold.

O sọ nigba naa pe ohun ti eeyan ba pe mọ ara rẹ ni yoo ṣẹlẹ si i.

Ọmọbinrin naa ni oun ko fẹ pẹnkẹlẹ ti i ṣe ayederu mọ, Gold ti i ṣe wura loun fẹẹ ki aye maa pe mọ oun lọ.

Alẹ ọjọ Aje, ọjọ Kejila osu Kẹjọ ọdun 2024 lo dagbere faye.