Kí ló tún fa èdè àìyedè míì láàárín àwọn ìbejì akọrin P- Square, tí wọn ń fi sọ̀kò ọ̀rọ̀ síra wọn?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọsẹ to kọja ni Paul Okoye, ẹni ti ọpọ mọ si Rudeboy kede sita pe o ṣeeṣe ki opin ti de ba ajọṣepọ to wa laarin oun ati ibeji rẹ, Peter Okoye.
Kii se igba akọkọ ree ti ipinya yoo waye laarin awọn olorin takasufe mejeeji naa, koda ọdun meji sẹyin ni awọn mejeeji pada ni ajọsepọ papọ lẹyin ti wọn kọkọ tuka.
Akọtun ede aiyede yii lo tun fa a ki awọn olorin mejeeji naa maa sọko ọrọ si ara wọn lori ayelujara.
Iroyin kan to tẹ wa lọwọ ṣafihan pe ajọ EFCC mu Paul Okoye, ọkan lara and ibeji akọrin naa ati Jude Okoye to jẹ ẹgbọn wọn lori ọrọ kan to da wọn papọ.
"Peter Okoye fi EFCC mu mi tori o fẹ ka tuka, ọpọ nnkan lo n sẹlẹ laarin wa tawọn ololufẹ wa ko mọ"
Paul Okoye, nigba to kuro ni agọ EFCC sọ lori ayelujara pe oun kii ṣe ole, ti ọwọ oun si mọ tonitoni,
Nigba to n ba ileeṣẹ redio kan sọrọ, Paul ni ipinya tun ti de si aarin wọn bayii tori ọpọ nnkan lo waye ti awọn ololufẹ wọn ko mọ nipa wọn.
O ni Peter Okoye, ẹni ti ọpọ mọ si Mr P lo pe fun pe ki awọn mejeeji tuka ati pe o fi ajọ EFCC mu oun.
“Mo ni lati sọ ọpọ nnkan fun awọn eeyan pe ki wọn irufẹ eeyan ti wọn yoo mu mọra.
“Idi ti a fi pada ni lati sisẹ pọ, gbe awo orin nla jade gẹgẹ bi a ti se tẹlẹ sugbọn bayii, mo fẹ gbaju mọ orin Rudeboy.
“Wọn ni mo sọ pe Peter lo n jo, ti e mi si n kọrin, mo mọ iyẹn, nibi kibi ti mo ba lọ, awọn eeyan ma n bi mi pe ṣe emi ni mo n kọrin tabi jo?
“A ṣe orin kan pẹlu T.I ‘Eja Jo’ ibẹ ni ọrọ ija ti bẹrẹ .
Titi di oni, orin naa lo jẹ milọnu mẹta eeyan lo wo nitori awọn eeyan ko gbọ ohun Psquare ti wọn ma n gbọ nibẹ.”
Ki lo fa ti EFCC fi mu Paul ati Jude Okoye?
Nibi ọsẹ mẹta sẹyin ni ajọ to n gbe ogun ti iwa ibajẹ mu Paul Okoye ati Jude Okoye sugbọn nigba to n fesi ọrọ naa, Peter Okoye naa oun ko fi kankan ro pe ki oun fi ajọ EFCC mu ibeji oun, to si jẹ irọ to jina si otitọ.
O ṣalaye pe oun kẹfin kọlọfin kan nipa owo iṣẹ awọn ti ẹnikan n ko si apa owo mii ati pe eeyan tun da ileeṣẹ to fẹ fi orukọ jọ ileeṣẹ awọn silẹ.
“N ko fi EFCC mu ibeji mi. Mo mọ pe ọpọ awọn ololufẹ wa ni wọn koroju si ọrọ yii nigba ti Paul sọ sita.
“O sọ pe kọ iwe lati pe oun si agọ EFCC, to jẹ ki EFCC ransẹ pe ko wa wi tẹnu rẹ, ti wọn si fi si ahamọ sugbọn gbogbo eyi lo jẹ irọ.
“Peter, Paul ati Jude Okoye ni ileeṣẹ kan papọ ti orukọ n jẹ Northside Enterainment, eyi ti a fi tukọ gbogbo eyi to jẹ mọ Psquare . Ni ọjọ kan, mo ri pe ileeṣẹ mi ti wa pẹlu irufẹ orukọ ileeṣẹ wa sugbọn orukọ fẹ yatọ diẹ, Northside Music.
“Eyi yami lẹnu pupọ, ti mo si bẹrẹ iwadii, sugbọn to yami lẹnu ni pe awọn oludasilẹ ileeṣẹ yii ni wọn ẹgbọn Jude ati iyawo rẹ , Ifeoma Okoye, ti wọn si adirẹsi ile iyawo sibẹ.”
Peter ni oun gbera lati lọ fi to Paul leti sugbọn ọpọ igba ni Paul kọ lati fun oun lesi, to si ni oun ko mọ nipa rẹ.
“Awọn ti mọ kọ we si, mo sọ fun ki wọn se iwadii lori Jude Okoye ati iyawo rẹ, Ifeoma Okoye nitori awọn mejeeji ni oludari ileeṣẹ yii.
“Mo wo ifọwerọ Paul, mo si ri pe irọ lo n pa, n ko le sọ nkankan, ti mo si ni lati bere lọwọ ara mi pe bawo ni Paul le se ma pe irọ to pọ bayii, to si tun tabuku si ajọ EFCC.
Peter ni oun ri pe ọpọ milọnu naira to jẹ owo Psquare lo n lọ si apo owo ikọkọ.
"Jude n ko owo lati apo owo P-square lọ si apo owo ileeṣẹ ti oun ati iyawo rẹ da silẹ"
O tẹsiwaju ninu
“Gbogbo ọrọ yii bẹrẹ nigba ti mo se iwadii kan, eyi to bimi ninu pupọ, pe fun ọpọlọpọ ọdun, ọpọ owo ni o n lọ apo owo ikọkọ ni ọna asiri lati ninu apo owo ileeṣẹ wa, Northside Entertainment
“Ọrọ eyii ko ki n ṣe kekere, o ti n waye fun ọpọ ọdun,”
O ni oun gbiyanju lati ba awọn meji yooku, Paul ati Jude sọrọ sugbọn wọn kọ lati fun ni esi, eyi to mu ransẹ pe ajọ EFCC.
“Mo mọ pe Paul n binu pe mo gbe ọrọ naa lọ ba EFCC, o dẹ ye mi sugbọn ẹ ma gbagbe pe mo gbiyanju lati ba awọn mejeeji sọrọ, koda, nigba ti mo ba Paul sọrọ gbẹyin, o ni ki n lọ ṣe nnkan ti mo ba fẹ se.
“EFCC mu Jude si ahamọ, ti wọn si fọrọ wa lẹnu wo. O jẹwọ pe otitọ ni pe oun da owo si apo owo ileeṣẹ ti oun ati iyawo rẹ jọ ni. Lẹsẹkẹsẹ ni wọn ti gbogbo apo owo Jude pa.”
O wa ṣe ileri lati tu sọrọ sita nigba ti ajọ EFCC ba pari iwadii wọn.
Ta ni P-Square?
Ti a ba n sọrọ awọn takusufe to lamilaka ni ilẹ Adulawọ, ọkan gboogi ni awọn ibeji Okoye, ti a ko si le koyan wọn kere lagbo orin kikọ.
Wọn bi Peter ati Paul Okoye ni oṣu kejidinlogun ọdun 1981 ni ipinlẹ Anambra.
Orukọ awọn obi wọn ni Olusọ aguntan Moses Okoye ati Josephine Okoye, ti wọn si awọn ọmọ iya ati baba bi, Jude, Mary, Tony, Lilian ati Ifeanyi Okoye.
Lati ile ẹkọ tiata St Murumba ni wọn ti bẹrẹ lati ma kọrin, ti wọn si n jo si.
Wọn oreọfẹ lati tun gba boolu ko di pe wọn di olorin.
Ọdun 2003 ni wọn gbe orin ‘Senorita’ sita, eyi to sọ wọn di ilumọka.
Wọn ti gba ọpọ ami ẹyẹ kaakiri agbaye ati loriléede Naijiria.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post















