Wo àwọn ọmọ Nàìjíríà tí wọ́n gba àmì ẹ̀yẹ fún orílẹ́èdè míì ní ìdíje 2024 Olympics

Oríṣun àwòrán, Instagram
Orilẹede Naijiria fidi rẹmi ninu idije Olypics to ṣẹṣẹ pari lorilẹede Paris, ṣugbọn awọn ondije kan ti wọn jẹ ọmọ Naijiria ri ami ẹyẹ gba fun ilu ti wọn n ṣoju fun loke okun.
Ifidirẹmi to ṣẹṣẹ ṣẹlẹ si Naijiria yii ni ẹlẹkẹjọ iru rẹ, ti orilẹede yii ko ti gba ami ẹyẹ kankan.
Awọn awoye ọrọ tilẹ sọ pe ti ọtẹ yii lo buru ju. Bẹẹ ni airọwọ mu rara yii dun ọpọ ọmọ Naijiria gan-an.
Ohun ti wọn n sọ ni pe bawo lo ṣe jẹ ti Naijiria ko rọwọ mu lati ọjọ akọkọ ti idije naa ti bẹrẹ, ti gbogbo ireti si pada ja si ofo lopin ohun gbogbo.
Awọn ọmọ Naijiria to gba ami ẹyẹ fun orilẹede ti wọn n ṣoju fun yii nkọ, awọn eeyan n beere pe ki lo ṣe ti wọn ko le gba ami ẹyẹ kankan lorukọ Naijiria, ilu abinibi wọn.
Awọn mi-in n sọ pe kadara ni ko ṣe orilẹede wa loore, bẹẹ lawọn mi-in n sọ pe awọn ondije Naijiria ko kunju oṣuwọn bii ti awọn ilẹ okeere ni.
Ṣugbọn ju gbogbo ẹ lọ, bi wọn ba n darukọ awọn mẹrin to gba ami ẹyẹ yii, wọn n darukọ ilẹ abinibi wọn ti i ṣe Naijiria mọ ọ.
Àwọn ọmọ Naijiria náà rèé
Yemisi Ogunleye
Ilu Omuo Ekiti ni wọn ti bi Baba to bi Yemisi Ogunleye, eyi to mu ki ọmọbinrin yii naa jẹ ọmọ ilu Ekiti lorilẹede Naijiria.
Orilẹede Germany ni wọn bi Yemisi si lọjọ kẹta, oṣu kẹwaa ọdun 1998.
Yemisi Ogunleye lo gba ami ẹyẹ Wura fun Germany ninu idije Olympics to ṣẹṣẹ pari yii.
Odun 1996 ni Germany ti gba ami ẹyẹ naa gbẹyin.
Salwa Eid Naser
Ebelechukwu Antoinette Agbapuonwu gan-an ni orukọ ti wọn sọ ọmọbinrin yii nigba ti wọn bi i lorilẹde Naijiria.
Naijiria naa lo ti bẹrẹ to si ti yege nibi ere idaraya awọn ọdọ Naijiria lasiko kan.
Ṣugbọn nitori ai si iranlọwọ to nilo, o gba orilẹede Bahrain lọ ni 2014, ni apa Iwọ-Oorun Asia, o yipada si ẹsin Islam, o si pa orukọ rẹ da pẹlu, o n jẹ Salwa Eid Naser latigba naa lọ.
Igbesẹ ti Salwa gbe naa mu ayipada rere ba a pupọ, latigba naa lo ti n gba ami ẹyẹ fun orilẹẹde to ni epo rọbi daadaa naa.
Eyi ti Salwa Eid Naser ṣẹṣẹ gba bayii ni ti ami ẹyẹ Fadaka, nibi ere awọn obinrin oni-irinwo mita.
Annette Echikunwoke
Ibi kan ti wọn n pe ni Pickerington, Ohio, l’America ni wọn bi ọmọbinrin yii si, ṣugbọn ọmọ Naijiria ni awọn obi rẹ.
Annette ti gbaradi lati ṣe oju Naijiria ninu idije Olympics to waye ni Tokyo ni 2020, ṣugbọn wọn ni ko yẹ lati dije.
Ọdun kan lẹyin eyi, ọmọbinrin naa bẹrẹ si i ba Amerika ṣe ere idaraya, o si gba ami ẹyẹ fadaka fun wọn nibi okun fifi to ni bọọlu ninu (hammer throw).
Annette di ọmọbinrin akọkọ nilẹ America to gba ami ẹyẹ nibi ere yii.
Samu Omorodion
Orilẹede Spain ni wọn ti bi Samu Omorodion, ni ibi kan ti wọn n pe ni Melila, bo tilẹ jẹ pe ọmọ Naijiria ni awọn obi rẹ.
Samu gbe ni Seville, ibẹ lo dagba si. Ọkunrin yii yẹ lati gba bọọlu fun Naijiria, ṣugbọn Spain lo n gba bọọlu fun, o si gba ami ẹyẹ Wura fun wọn nibi Olympics to ṣẹṣẹ pari yii.
Aṣeyọrin Omorodion fi han pe awọn ọmọ Naijria to n ṣoju orilẹede miran yii ni ẹbun gidi.
Bi wọn ṣe jẹ ọmọ Naijiria ti wọn si n wulo fun orilẹede mi-in yii, o ṣe pataki lati mojuto awọn to wa nilẹẹ wa pẹlu ẹbun ti wọn ni, ki wọn le gba oriyin wale fun wa lati oke okun lọjọ kan.















