Àwọn ọlọ́pàá Sharia ń fi tipá gbé àwọn obìnrin tí kò lo Hijab sí àhàmọ́, ọ̀rọ̀ di tilé ẹjọ́

Àkọlé fídíò, Fídíò bí ọlọ́pàá Sharia ṣe ń wọ́ obìnrin kan nílẹ̀ torí kò lo ìbòrí dá ariwo sílẹ̀ ní Iran
Àwọn ọlọ́pàá Sharia ń fi tipá gbé àwọn obìnrin tí kò lo Hijab sí àhàmọ́, ọ̀rọ̀ di tilé ẹjọ́

Awuyewuye lo bẹ silẹ nilẹ Iran laipẹ yii lori iwa ọyaju ti awọn ọlọpaa Sharia hu si awọn obinrin meji kan lorilẹede naa.

Fidio kan ti wọn pin sori ayelujara lo se afihan iwa yaju naa, eyi to mu kawọn araalu tutọ soke, foju gbaa.

Awọn obinrin meji yii ti isẹlẹ naa kan, la ri ninu fidio ọhun, ti wọn n sa fun awọn ọlọpaa to n sefilọlẹ asa lilo ibori ti a mọ si Hijab lorilẹede Iran.

Fidio ibi ti awọn obinrin naa ti n sa kiri ni wọn ka silẹ lọjọ Kọkanlelogun osu kẹfa ọdun 2024 eyi to tun bọ sori ayelujara.

Awọn ọlọpaa Sharia n fi tipa gbe obinrin kan sinu mọtọ

Alaye nipa ohun to wa ninu fidio naa ree...

Koda ọrọ naa ti dele ẹjọ, nigba ti ọkan ninu awọn iya awọn ọmọbinrin tawọn ọlọpaa Hijab naa fi tipa gbe, pe awọn agbofinro naa lẹjọ.

Adajọ si ti ni ki wọn lọ tun fidio naa yẹwo, ti ayẹwo naa si fihan pe wọn fi tipa gbe awọn obinrin naa ni.

Fidio naa lo se afihan bi mọto kan se duro lojiji loju popo, tawọn ọlọpaa to wa ninu rẹ si sare sọkalẹ, lọ sọdọ awọn obinrin naa.

Wọn mu ọkan ninu awọn obinrin meji naa wọnu ọkọ amọ ti ikeji rẹ faake kọri lati wọle sinu kọ naa ni pẹlu putu.

Araalu n ran aarẹ Masoud Pezeshklan leti ileri to se pe oun yoo fi opin si ki wọn maa fi tipa mu awọn obinrin lati wọ Hijab

Fidio naa wa se afihan awọn ọlọpaa ọhun ti wọn suru bo obinrin to n lo agidi lati wọle sinu ọkọ bọọsi wọn naa.

Se ni wọn n fi adigi wọ nilẹ lọ sinu ọkọ naa, ti ọmọbinrin ọhun si fi ara pa.

Ileejọ naa ni awọn ọlọpaa ọhun hu iwa to tapa si ẹtọ ọmọniyan, ti wọn ko si sisẹ wọn pẹlu ilana to tọ.

Masoud Pezeshklan ti wọn yan sipo aarẹ losu keje ọdun 2024 ti seleri lasiko ipolongo ibo aarẹ lati fi opin si ki wọn maa mu awọn obinrin lati wọ Hijab.

Ọpọ eeyan lori ayelujara si ti n ran leti itori to se lasiko ipolongo ibo rẹ naa.