"Ohun tó wù mí jùlọ ni kí n ṣí ara àti orí sílẹ̀ àmọ́ wọ́n kan Hijab nípá fún mi láti wọ̀"

Ribell wọ aṣọ kolapa pẹlu tatoo lara.

Oríṣun àwòrán, Supplied

    • Author, Faranak Amidi
    • Role, Women’s Affairs Journalist, BBC World Service

O máa n nira fun ọpọ obinrin to ba jẹ ẹlẹsin musulumi lati ṣadeedee ma wọ hijaabu mọ.

Oju buruku l'awọn eeyan saaba ma n fi wọ wọn lawujọ to fi mọ awọn idile wọn gan an.

Laipẹ yìí ike igbimọ aṣofin orilẹ ède Iran ṣe agbekalẹ ofin kan to ṣe afikun ijiya fun ẹnikẹni to ba tapa sofin ijọba lori aṣọ wiwọ.

Laipẹ yii ni awọn obinrin Iran ṣe ifẹonuhan lori ọkan lara wọn Mahsa Amuni ku Si ahamọ awọn ọlọpaa lẹyin ti wọn fẹsun kan an ko wọ hijaabu rẹ dáadáa.

Ninu biliọnu kan awọn obinrin to jẹ musulumi, awọn ti o bá wú lo maa n wọ hijaabu.

Mahsa Amini

Oríṣun àwòrán, Mahsa Amin

Ribell ni ohun to wu oun ni pe ki awọn obinrin Musulumi le máa wọ ohun to bù wù wọn lọjọ kan.

Lati ọmọ ọdun mẹsan an ni Ribell(kii ṣe orukọ rẹ gan gan an) ti bẹrẹ si ni wọ hijaabu.

Lati ọdun mẹfa ni awọn obi rẹ ti n sọ fún ùn pe o gbọdọ maa wọ hijaabu nitori ojuse rẹ sí Ọlọrun ni o jẹ.

Wọn ijiya n duro de e lẹyin to ba kú tán ti ko bá wọ hijaabu.

Nigba ti o pe ọdun mẹtalelogun ni Ribell fi Iran silẹ lọ sí orilẹ ede Turkey nibi ti o ti n ṣiṣẹ tatoo yiya.

Ribell ni lati kekere ni o ti wu oun lati maa wọ aṣọ penpe eleyii ti ofin ati ẹsin ko faye gba ni Iran.

Ribell wọ Hijab to fi oju ati iwaju ori rẹ han sita

Oríṣun àwòrán, Supplied

Dandan ni fawọn obinrin Musulumi lati wọ hijaabu lorilẹ ede Iran.

Ribell ni mama oun maan so foun lati ma ṣe fi ọwọ ati ẹsẹ oun hàn níwájú awọn ọdọkunrin tori o le mu wọn kọsẹ.

Awọn obi Ribell fi sí ile ẹkọ keu ni ọmọ ọdun metadinlogun.

Ko nifẹ sí ile ẹkọ naa, o ni wọn n ṣegbe lẹyin ọkunrin.

Ribell n fi apa janu lori hijab

Oríṣun àwòrán, Supplied

Lọjọ to dẹkun hijaabu wiwọ lo wọ kootu to ju orunkun rẹ lọ diẹ.

Ọga ile ẹkọ rẹ pe awọn obi Ribell lati ma jẹ ko rin loju titi pẹlu aṣọ to wọ.

Koda mama baba rẹ gbadura pe ki Ribell ku ju ki oju ti ẹbi awọn lọ.

Ribell gbìyànjú lati gba ẹmi ara rẹ nigba ti wahala pọ.

Lẹyin naa ni o fi Iran silẹ lọ sí Turkey nibi to n ṣe àtìpó láì wọ hijaabu.

Mona Eltahawy, fi ọda Yẹlo kun ori rẹ

Oríṣun àwòrán, Supplied

Bó tilẹ jẹ pe ẹbi tiẹ ko le to ti Ribell, ko rọrùn fún Mona Eltahawy naa lati dẹkun wiwọ hijaabu.

Ọdun mẹsan an ni o fi wọ hijaabu.

Nigba to ya ni o ni igboya lati máa wọ ọ mọ.

O ni pẹ ki oun to le maa sọ fawọn eeyan pe oun ti hijaabu sẹyin nigba ti oun ko wọ ọ mọ.

Bella lo ibori to bo ori ati ejika rẹ

Oríṣun àwòrán, Supplied

Akọroyin BBC, Bella Hassan ti wọn bi si Mogadishu ni Somalia ti wọ hijaabu fun gbogbo ọjọ ayé rẹ.

Amọ, lọdun 2022 t'awọn obinrin ṣe ifehonuhan ni Iran ni o dẹkùn hijaabu wiwọ.

Awọn ẹbi rẹ ko dun nu sí bi ko ṣe wọ hijaabu mọ bó tilẹ jẹ pe ilu London lo n gbe bayii.

Bella Hassan

Oríṣun àwòrán, Supplied

Ọpọ eeyan lo mọ Bella ni Somalia.

Aiwọ hijaabu rẹ mọ fà awuyewuye.

O ni ọpọ ọkunrin lo n dunkoko mọ oun pe awọn yóò pa oun.

Awọn mii tiẹ n sọ pe awọn yóò fipa ba oun lopọ.

O ni ko sí ijiya kan pato ninu ẹsin Islamu fun ẹni ti ko ba wọ hijaabu jù pe ijiya wa fun wọn ti wọn ba kú tán.

Ṣugbọn o ni awọn ọkunrin Somalia fẹ fún oun ni idajọ ti ara wọn