Trump kéde ohun tí yóò ṣe fún àwọn àjòjì tó ń wọ America to ba di ààrẹ

Donald Trump

Oríṣun àwòrán, Getty

Àkọlé àwòrán, Donald Trump
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Donald Trump, aarẹ tẹlẹ to tun n du ipo naa lọwọlọwọ lorilẹde America, ti kede awọn nnkan ti yoo ṣe fun awọn ajoji to n wọ America, ti wọn si n gbe nibẹ, to ba fi le de ipo naa loṣu kọkanla ọdun 2024 yii.

Nibi ifọrọwerọ kan to waye laarin Trump, ọmọ ẹgbẹ Republican pẹlu baba olowo, Elon Musk to ni oju opo X, ni Trump ti sọrọ yii.

Donald Trump sọ pe ko le gba oun to oṣu kan, lẹyin toun ba de ori aleefa, ti oun yoo fi gbe ilana ti yoo le awọn ajoji kuro ni America, paapaa, awọn ti wọn n wọle lọna aitọ.

O ni lile ti oun yoo le wọn ni yoo pọ ju ninu itan awọn ajoji ti wọn tii le kuro ni America ri.

Oludije ipo aarẹ Amẹrica naa sọ pe, oun ko ni i yi ipinnu oun pada, lọgan loun yoo gbe gaga si aarin America ati awọn ajoji, to ṣee ṣe ki wọn jẹ ọdaran nibi ti wọn ti n bọ.

Kí ni ìdí tí Trump ṣe fẹ́ẹ́ gbé ìgbésẹ̀ yìí?

Nigba to n sọ idi rẹ to fi fẹẹ gbe igbesẹ yii, Donald Trump ṣalaye pe, ‘’Iwa ọdaran pọ kaakiri aye,o yẹ ki ẹ gbọ iye iwa ọdaran ti a ni.

‘’Iwa ọdaran nla ni ki eeyan maa wọ orilẹede ẹlomi-in lai gba aṣẹ.’’

‘’Awọn ẹlomi-in buru gan-an, wọn ti ju ẹlomiran si ẹwọn ni orilẹede to ti n bọ.

Wọn ti da ẹjọ iku fun ẹlomi-in, wọn aa dẹ maa ran wọn wa si orilẹede tiwa.’’

Trump to sinmi loju opo X fun bii ọdun kan, deede polongo ibo rẹ loju opo naa lọjọ Aje, ọjọ kejila, oṣu kẹjọ ọdun 2024 yii.