ICPC ṣàlàyé ìdí tó fi gbé àwọn òṣìṣẹ́ àjọ tó wà fún ìrìnàjò sílẹ̀ mímọ́

Aworan awọn arinrinajo Hajj to fẹẹ wọ baaluu.

Oríṣun àwòrán, NAHCON

Àkọlé àwòrán, Eeyan 51,447 ni wọn fi orukọ silẹ fun irin ajo Hajj ni 2024.
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Iroyin kan lu jade sita nipa bi ajọ to n gbogun ti iwa ajẹbanu ati awọn iwa aibofin mu, ICPC ṣe mu awọn oṣiṣẹ agba nileeṣẹ to n ri sọrọ eto irin ajo lọ silẹ mimọ, National Pilgrims Commission (NAHCON).

Ọkan lara awọn oṣiṣẹ agba nileeṣẹ eto idajọ ilẹ yii lo sisọ loju ọrọ naa fun BBC, ṣugbọn o sọ pe gbogbo wọn ni wọn ti gba beeli wọn, ti wọn si ti n ran ileeṣẹ naa lọwọ pẹlu ẹri.

Ṣugbọn ṣa, agbẹnusọ ileeṣẹ naa sọ pe ẹnikan ṣoṣo pere ni awọn fi iwe pe lati fi ọrọ wa lẹnu wo.

Iroyin ṣafihan pe ileeṣẹ naa n wa alaye lori bi ajọ NAHCON ṣe na owo biliọnu lọna aadọrun naira ti ijọba apapọ fun wọn lati fi ṣe iranwọ fun awọn to rin irin ajo lọ si ilẹ mimọ lọdun 2024.

Lakọkọ, ajọ naa sọ pe miliọnu marundinlọgọrun kan (N4.9m) naira ni owo ti awọn ọkunrin yoo san.

Ṣugbọn wọn tun gbe owo naa lọ si miliọnu mẹfa ati ẹgbẹrun lọna ọgọrin naira, ti wọn si ni bi owo naira ṣe lọ soke lo fa a.

Iroyin naa lo tu aṣiri sita wi pe ijọba apapọ ti gbe aadọrin biliọnu naira silẹ lati fi ṣe iranwọ fawọn arinrin ajo Hajj.

Ajọ naa si sọ pe oun pin owo naa sori owo awọn arinrin ajo ẹgbẹrun marunlenirinwo ati arundinlaadọta (5,447) ti wọn lọ nipasẹ ijọba.

ICPC fi ọwọ ofin mu àwọn alákòoso NAHCON tori wọn kọ lati jẹ ipe wọn

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ni ọgbọn ọjọ, oṣu keje ọdun 2024, ICPC pe alakooso ajọ NAHCON, Jalal Arabi, lati waa ṣalaye bi ajọ ọhun ṣe na owo tijọba ya sọtọ fun ọdun to kọja.

Atẹjade ti ICPC gbe jade jẹ ko di mimọ pe wọn pe ọkunrin naa lati ṣalaye gẹgẹ bi wọn ti ṣe maa n ṣe lọdọọdun.

“Bo tilẹ jẹ pe pipe ti a pe e maa ko ibẹru sọkan awọn alabaṣiṣẹpọ rẹ, sibẹ wọn ni bi wọn ti n ṣee niyẹn lati le maa ṣagbeyẹwo iwa jibiti,” Fatima Sanda Usara to jẹ agbẹnusọ ajọ naa lo sọ bẹẹ.

Igbakeji alakoso eto iroyin, Hassan Salihu sọ fun BBC pe awọn tun pe awọn adari ajọ naa lati wa ṣalaye tẹnu wọn, ṣugbọn ti awọn ti wa fi ofin gbe wọn lẹyin “ti wọn kọ jalẹ lati yọju si wọn.”

Bo tilẹ jẹ pe ko darukọ wọn.

“To ba jẹ pe wọn ti yọju nigba ti a fi iwe pe wọn, niṣe la ma maa ba iwadii wa lọ labẹlẹ, gẹgẹ bo ṣe n lọ lagbaye, ti wọn si ti gba beeli wọn.”

Nigba to n sọrọ nipa orukọ wọn, o ni “Ofin ko gba wa laaye lati fi orukọ wọn sita.”

Sibẹsibẹ, agbẹnusọ ajọ NAHCON, Fatima Usara sọ pe ẹnikan pere lawọn fiwe pe.

“Ẹnikan pere la ranṣẹ pe, kii tiẹ tun un ṣe alakoso,” o sọ bẹẹ.

Gbogbo awọn alakoso wa ni wọn fiwe pe, ti gbogbo wọn si lọ. Mo mọ ẹnikan ti to kọ lati dahun ipe, ṣugbọn ti wọn wa gbe e lọ.”

Ìbanilórúkọjẹ́ tí ilé aṣòfin ṣàwárí nípa NAHCON

Sẹnetọ Ibrahim Abdullahi Dan Baba, aṣofin to n ṣoju ẹkun Guusu ipinlẹ Sokoto nile igbimọ aṣofin ilẹ Naijiria tẹlẹri, sọ fun BBC nipa ẹsun ibanilorukọjẹ ti awọn ṣawari nipa iwa awọn oṣiṣẹ NAHCON.

Sẹnetọ naa sọ pe awọn ti bẹrẹ igbesẹ lati yi awọn ofin ajọ naa pada fun awọn arinrinajọ Hajj, lati maa san owo lọdọọdun lọ si Saudi Arabia.

O loun sọ fun ile igbimọ aṣofin kẹsan-an to kọja lati ṣewadi awọn ẹsun iwa ibajẹ to ṣẹlẹ ni Hajj lorileede Naijiria, ti wọn si gbe igbimọ oluwadi dide.

“Iwadii ti a ri sọ pe niṣe ni wọn n ji owo arinrin ajo, awọn otẹẹli to yẹ ki wọn tipa fun ogoji ọjọ, aadọrun ọjọ ni wọn fi n tipa, ati pe owo to ku to yẹ ki wọn da pada lẹyin ti awọ arinrin ajo Haj ba ti pada, apapin ni awọn alakoso otẹẹli ati awọn oṣiṣẹ NAHCON fin ṣe. Ati pe awọn alakoso otẹẹli naa yoo mu ida marundinlọgbọn, nigba ti awọn alakoso NAHCON yoo mu ida marundinlọgọrin.” Gẹgẹ bi sẹnetọ naa ṣe ṣalaye.

O fi kun ọrẹ rẹ pe owo ti wọn ji ko to ko din ni biliọnu kan naira.

Awọn ọmọ ile aṣofin lero pe miliọnu mẹta naira kere fun awọn to n lọ si Haj, ati pe “bi wọn ba tẹle ilana to tọ, owo Haj ko nii pọ to iye ti awọn eeyan n san.”

Fun ọpọlọpọ ọdun, oriṣiriṣi ọrọ ati awuyewuye lo ti jẹyọ nipa agbeyẹwo ofin, ṣugbọn ti ko wa foju han boya ile igbimọ aṣofin kẹwaa ti bẹrẹ iṣẹ lee lori.