"Tírélà tó sọ ìjánu rẹ̀ nù n‘Ibadan àti ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ ń bọ̀ tààrà sínú ṣọ́ọ̀bú mi tí àwa mẹ́rin wà, àwa mẹ́ta moribọ́, abẹ́ tírélà la ti yọ ẹnì kẹrin"

Eeyan mẹrindinlogun lo padanu ẹmi wọn ninu ijamba ọkọ̀ to waye lagbegbe agbowo, opopona marose ilu Oyo si Ibadan, ti i ṣe oluulu ipinlẹ Ọyọ.
Ọkan lara awọn ti iṣẹlẹ naa ṣe oju rẹ, Ibitoye Musa, ṣalaye fun akọroyin BBC Yoruba pe Ijamba naa waye ni nkan aago mẹwaa si aago mẹwa aabọ oorọ.
Musa ni ọkọ tirela alawọ dudu, to ko irin ati orule, sọ ijanu rẹ nu ti o si kọlu ọkọ akero, to n bọ lati Ipinlẹ Kano.
Ibitola ṣalaye siwaju sii wi pe, yatọ si Ọkọ akero naa ti eeyan mejidinlogun n bẹ ninu rẹ, ọkọ nla ọhun tun kọlu ọkọ agbero micra ati ọkọ jeepu Honda.
Awọn eeyan mẹrindinlogun sì lo ba ijamba naa lọ, nigba ti eeyan mẹtadinlogun farapa yanna-yanna.

Oríṣun àwòrán, Oyo FRSC
"Mo ri ọkọ ayọkẹlẹ ati tirela ń tọ ọdọ mi bọ̀ ninu sọọbu, afi bi ẹni wipe ọrun n yabọ"
Ibitoye Musa ni, "Mo wa ninu sọọbu mi nigbati awọn kan pe mi lati wa ra ọja lọwọ mi tori oniṣowo irin ni mi.
Bi a ṣe n dunadura lọwọ, ni mo ṣadede gbọ ariwo kan, bẹẹ ni mo ri ti awọn ọkọ ayọkẹlẹ ati ọkọ tirela naa ń tọ ọdọ mi bọ̀, afi bi ẹni wipe ọrun n yabọ.
Loju ẹsẹ ni mọ ba ẹsẹ mi sọrọ, ninu awa mẹrin ta jọ n dunadura lọ́wọ́, awa mẹta moribọ, abẹ ọkọ akérò, ni wọn ti yọ ẹni kẹrin, sugbọn ko gba ẹmi rẹ".

"Ẹ̀yà Arewa mẹrinla la sin n‘ibadan, awọn meji to ku la fi oku wọn ransẹ si Kano pẹlu awọn meje to farapa"
Alli Muhammed, ọkan lara awọn olori ẹya Arewa tí wọn pe lati wa ṣe idamọ awọn to ṣe alabapade ijamba ọkọ naa ba BBC Yoruba sọrọ nipa isẹlẹ naa.
Alli ṣalaye wi pe, ọkọ akero ẹlẹni mejidinlogun lo n bọ lati ilu Kano, ti o si nlọ si ilu Eko.
Alli ni awọn mẹrindinlogun ni wọn padanu ẹmi wọn, ti awọn si ti sin awọn mẹrinla si ilẹ isinku to wa ni agbegbe Akinyele nilu Ibadan.
O fikun pe awọn meji to sẹku ni awọn fi oku wọn ransẹ si ilu Kano lalẹ ana pẹlu awọn meje ti o farapa nibi isẹlẹ naa.

Eeyan mẹrindinlogun ni wọn gbe wa pẹlu orisirisi ipalara sile iwosan wa, tí awọn si fi awọn mẹta ranṣẹ lọ si ile iwosan UCH - Dokita aladani
BBC Yoruba tun morile ilewosan aladani kan nilu Ibadan, ti wọn ko awọn eeyan to fori sọta ijamba ọhun, ti wọn wa laaye lọ.
Ọga Agba ile iwosan Hamdala to wa ladugbo agbowo nilu Ibadan, nibiti wọn gbe awọn to farapa lọ, Olugboyega Onasanya ṣalaye nipa isẹlẹ naa.
Onasanya ni eeyan mẹrindinlogun ni wọn gbe wa pẹlu orisirisi ipalara tí awọn si fi awọn mẹta ranṣẹ lọ si ile iwosan UCH.
O tesiwaju wi pe, gbogbo awọn ti wọn gbe wa si ile iwosan Hamdala ni ori ko yọ, ti ọkankan ninu wọn ko si padanu ẹmi rẹ.
O ni, "titi di akoko yii awọn to jẹ ara ilu Ibadan ṣi n wa fun itọju loni, tí awọn meje to jẹ ti ẹya Arewa si ti pada si ilu Kano nibiti wọn ti wa.

Ìjàmbá ọkọ̀ gbẹ̀mí èèyàn 16, èèyàn 15 míì farapa n'Ibadan, ohun tó fà á rèé

Oríṣun àwòrán, Oyo FRSC
Ọjọ buruku ni Ọjọ Iṣegun, ọjọ kẹtala oṣu kẹjọ ọdun 2024 niluu Ibadan nigba ti ijamba ọkọ kan waye, to si mu ẹmi eeyan mẹrindinlogun lọ lẹsẹkẹsẹ.
Ijamba yii waye ni loju opopona marosẹ Ojoo-Iwo-road .
Gẹgẹ bii ajọ to n ri si oju opopona., FRSC se ṣalaye, eeyan mẹtadinlogun mii lo ti dero ile iwosan lẹyin ti wọn farapa yanayana.
Agbẹnusọ fun FRSC nipinlẹ Oyo, CRC Mayowa Odewo ni ijamba naa waye lẹyin ti bireki ọkọ naa kuna lati sisẹ.
“Iṣẹlẹ yii waye lẹyin ti ọkọ nla kan to n ko irin kọlu ọpọ ayọkẹlẹ to n bọ lati Oke Oya pẹlu ero ọkọ mejidinlogun, ti ọpọ wọn jẹ ọmọde.
“Ọkọ nla naa kọlu ọkọ Micra ati Honda CR-V, ti eeyan mẹrindinlogun si padanu ẹmi wọn lẹsẹkẹsẹ.
“Eeyan mẹtadinlogun mii farapa yanayana, ti ori si ko eeyan meji to wa ninu ọkọ Honda yọ, ti wọn si ti wa ni ile iwosan.
“Diẹ ninu awọn eeyan to farapa lo jẹ pe Hausa ni wọn, ti wọn si kọ lati duro ni ile iwosan.”
Odewo ni ọga agba ajọ FRSC nipinlẹ Oyo, Rosemary Alo ati awọn ikọ naa balẹ si ibi ti isẹlẹ naa ti waye, ti wọn ri daju pe wọn se ohun to tọ lasiko.
“Pupọ awọn ti padanu ẹmi wọn ni wọn jẹ Hausa, ti wọn si ti gbe wọn Shasa tabi Ojoo. Seriki Hausa ti ba wa sọrọ, ti a si ti fi oku wọn eeyan naa ransẹ si wọn.
“Ajọ FRSC tun morile ile iwosan lati mọ nipa alaafia awọn eeyan to farapa.
Áwọn to farapa wa ni ile iwosan Amudalat ni agbegbe Agbowo, ti wọn si ti gbe awọn oku kan lọ si ile igbe oku si ni agbegbe Akinyele.
“Awọn ọkọ to ni ijamba naa ti wa ni ileeṣẹ ọlọpaaa ni Irepodun ni agbegbe Ojoo.”

Oríṣun àwòrán, Oyo FRSC















