Ìgbìmọ̀ lọ́balọ́ba ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà kéde bí orò ìsìnkú Ọba Aromolaran yóò ṣe wáyé

Aworan Oba Aromolaran

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Igbimọ lọbalọba ti kede sita pe oro isinku fun Ọwa Obokun tí ilẹ Ijesa, Ọba Adekunle Aromolaran to waja ti bẹrẹ.

Ọba Aromolaran darapọ mọ awọn baba nla rẹ ni ọjọ kọkanla, oṣu Kẹsan an, ọdun 2024 lẹyin aisan ranpẹ.

Asiwaju ti ilẹ Ijesa, Oloye Yinka Fasuyi lo kede iroyin iku rẹ lọjọ kejila oṣu, Kẹsan an ọdun 2024.

Nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ ninu aafin Owa niluu Ilesa, Obaala tí Ilesa, Oloye Adeniyi Ibitoye ati igbimọ lọbalọba bi Odole Owa tí Ilesa, Oloye Adebola Orolugbagbe salaye oro isinku naa yoo waye fun aadọrun ọjọ.

Orolugbagbe, Olootu ìjọba aafin fidi rẹ mulẹ pe igbimọ lọba lọba ko ti kede ofin ko oni ile gbe ile ni ilu naa.

Ẹwẹ, o ni gbogbo ọja nilẹ Ijẹṣa ni yoo wa ni titi pa titi di ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹsan an.

"Gbogbo ọja ni yoo wa ni titi pa, bẹrẹ lati ọjọ kẹrinla titi di ọjọ kọkanlelogun oṣu Kẹsan an.

"Ko si ofin konile o gbele nilẹ Ijẹṣa. Fun idi eyi, a rọ awọn araalu lati tẹsiwaju pẹlu isẹ wọn.

"Aafin Ọba ni Okemese yoo wa ni titi pa bayii. Oro isinku yoo waye fun aadọrun ọjọ."

Orolugbagbe kan sara si igbe aye ti Ọba Aromolaran gbe, to si sapejuwe ipapoda Ọba to lo ọdun mejilelogoji lori itẹ gẹgẹ bii eyi ti yoo jẹ awukọse fun awọn ọmọ ẹlẹyin.

O wa rọ awọn ọmọ ijesa lati se ara wọn lọkan, ki wọn si ma gba adura fun mọlẹbi Aromolaran.

Ọpọ awọn eeyan jakanjakan lo ti ransẹ ibanikẹdun si mọlẹbi Aromolaran lẹyin ipapoda Ọba to waja.