Èèyàn bí ogójì kú nínú ìjàmbá ọkọ̀ ojú omi tó dànù

Awọn eero ọkọ oju omi

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ko din ni ogoji eeyan, ninu eyi ti awọn ọmọde wa, to padanu ẹmi wọn lọjọ Abamẹta lẹyin ti ọkọ oju omi kan danu niluu Gummi, nipinlẹ Zamfara.

Oludari ajọ to n mojuto iṣẹlẹ pajawiri nipinlẹ Zamfara, Hassan Dauran, sọ fun ileeṣẹ iroyin Channels Television pe, aadọta eero ni ọkọ oju omi naa ko nigba to doju de.

Gẹgẹ bi Dauran ṣe sọ, perete lara awọn eeyan naa ni wọn ri doola laaye, ti pupọ ninu wọn, to jẹ obinrin ati ọmọde si ku.

Ẹnikan ti iṣẹlẹ naa ṣoju rẹ sọ pe, oko ni awọn eeyan naa n lọ ni owurọ kutu ọjọ Abamẹta nigba ti ọkọ wọn doju de, to si ri sinu odo.

'Awọn àgbẹ̀ mẹtalelaadọta ninu eyi ti ọmọde ati awọn obinrin wa, lo wa ninu ọkọ oju omi ọhun, eeyan mọkanla pere, pẹlu awakọ ni wọn ri doola.'

Abubakar Umar, to jẹ agbẹnusọ ijọba ibilẹ ti ijanba naa ti waye sọ pe pupọ awọn to wa ninu ọkọ naa lo jẹ agbẹ ti wọn n gbiyanju lati wọ rekọja lọ sinu oko wọn ṣaaju iṣẹlẹ naa.

Nigba ti BBC kan si kọmiṣọna eto iroyin ipinlẹ naa, Mannir Haidara Kaura, o fidi iroyin naa mulẹ.

O ni o ṣoro lati mọ iye eeyan ti ọrọ naa kan ni pato lasiko yii.

Iṣẹlẹ yii lo n waye lẹyin ọsẹ diẹ ti agbara omiyale kọlu ilu Gmmi yii kan naa, eyii to ba ọpọlọpọ dukia jẹ.

Iṣẹlẹ ọkọ oju omi riri ti n di lemọlemọ ni Naijiria lẹnu aipẹ yii, eyii ti awọn onimọ sọ pe o n waye latari bi irufẹ ọkọ oju omi bẹẹ ṣe maa n ko iye ero to pọ ju agbara rẹ lọ.