Èèyàn 24 jóná gúrúgú níbi tí wọ́n ti ń gbọ́n epo nínú tańka tó ṣubú

Tanker explosion

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Eeyan mẹrinlelogun ti jade laye lorilẹede Haiti lẹyin ti ọkọ agbepo kan gbina lorilẹede naa.

Yatọ si awọn to ku, ọpọ awọn mii lo farapa yanayana ti ida 80% ara awọn ninu wọn jona.

Agbegbe Miragoane, to jẹ nnkan bii ọgọrun kilomita si ilu Port-au-Prince to jẹ olu ilu orilẹede naa ni iṣẹlẹ ọhun ti waye.

Awọn ileeṣẹ iroyin abẹle jabọ pe iṣẹlẹ naa waye lẹyin ti ọkọ agbepo naa fori sọ ọkọ mii laarin ọna, ti epo si danu si oju popo.

A gbọ pe asiko ti awọn araalu n ko epo to danu ọhun ni ibugbanui naa waye.

Olootu ijọba, Garry Coville sọ fun awọn akọroyin pe iṣẹlẹ ọhun jẹ eyii to gba omije loju ẹni.

Lẹyin naa lo ṣeleri pe oun yoo ṣe gbogbo ohun to yẹ lati ri pe awọn ti ọrọ naa kan gba itọju to peye.

Emmanuel Pierre, to jẹ olori ẹṣọ alaabo Haiti sọ fun ileeṣẹ iroyin AFP pe eeyan mẹrindinlogun lo kọkọ padanu ẹmi wọn ki awọn to ri awọn oku mii he lẹba ọna.

Kii ṣe igba kọkọ ree ti ọpọ ẹmi yoo sọnu ni Haiti latari ibugbamu ọkọ agbepo.

Irufẹ iṣẹlẹ bẹẹ mu ẹmi ọgọta eeyan nibẹ lọdun 2021.

Wayi o, nnkan ko fararọ ni ẹka eto oṣelu orilẹede naa latari bi oniruru awọn oni jagidijagan ṣe gba ọpọ agbegbe lorilẹede ọhun.