Taa ni Ryan Routh, afurasí tó gbìyànjú láti pa Trump nígbà kejì?

Oríṣun àwòrán, Reuters
Ori tun ti ko aarẹ Amẹrika nigba kan, Donald Trump, yọ lọwọ iku, lẹyin ikọlu kan ti awọn oṣiṣẹ alaabo FBI ṣapejuwe gẹgẹ bi igbimọ lati paa ni papa bọọlu Golf rẹ to wa ni west Palm Beach ni Florida.
Ọjọ Aiku, ọjọ kẹdogun, oṣu Kẹsan-an, ọdun 2024 ni iṣẹlẹ naa waye.
Iṣẹlẹ naa waye lẹyin bi oṣu meji ti ẹnikan yinbọn mọ Trump lasiko ipolongo ibo ni Butler, Pennsylvania, nibi ti Trump ti farapa, ti alatilẹyin rẹ kan si ku u.
Ninu ikọlu tuntun yii, awọn ileeṣẹ iroyin ni America sọ pe orukọ ọkunrin naa ni Ryan Routh.
Ọkan lara awọn oṣiṣẹ alaabo ọtẹlẹmuyẹ lo ri afurasi naa nibi to farapamọ si ninu igbo kekere kan.
Oṣiṣẹ alaabo naa deede ri ibọn to yọ ori jade ninu igbo, lo ba ṣina ibọn bo ibẹ.
Awọn alaṣẹ sọ pe ibi ti wọn ti ri afurasi ọhun ko ju ibusọ 300 si 500 si ibi ti Trump ti n gba Golf.
Lootọ ni afurasi naa raaye salọ pẹlu ọkọ ayọkẹlẹ kan, ṣugbọn ọwọ pada tẹ ẹ ni opopona nla kan.
Taa ni Ryan Routh to ‘tun fẹ ẹ pa Trump’?
Ileeṣẹ iroyin CBS News sọ pe Ryan Wesley Routh ni orukọ arakunrin naa.
Lara awọn nnkan ti BBC fimu finlẹ nipa Ọgbẹni Routh ni pe o ti pe fun pe ki awọn ọmọ ogun ilẹ okeere lọ si Ukraine ri lori ayelujara Facebook rẹ, lati doju ogun kọ Russia.
Botilẹ jẹ pe Routh ko ni iriri kankan ninu ṣẹ ogun jija, o sọ fun ileeṣẹ iroyin New York times lọdun 2023 pe, oun rinrinajo lọ si Ukraine ni kete ti Russia yabo o lọdun 2022, lati wa awọn ọmọ ogun laarin awọn ọmọ ogun Afghanistan to sa kuro lọwọ ijọba Taliban.
Awọn iroyin kan sọ pe Routh ni akọsilẹ fun iwa ọdaran, to si ti lọ si ẹwọn ri fun oriṣiriṣi ẹsun iwa ọdaran, ninu eyi ti gbigbe nnkan ija oloro wa.
Nigba to n ba ileeṣẹ iroyin sọrọ ni America, ọmọ Routh, Oran, ṣapejuwe baba rẹ gẹgẹ bi “baba daadaa to nifẹ awọn ọmọ rẹ”.
A ṣi n ṣe akojọpọ iroyin yii lọwọ.












