Èyí ni bí àwọn àgbẹ̀ ṣe di olówó nípasẹ̀ ọtí ọ̀gẹ̀dẹ̀ ní Malawi

Emily Nkhana

Oríṣun àwòrán, Anne Okumu/BBC

    • Author, Anne Okumu & Ashley Lime
    • Role, BBC News, Karonga
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Agbẹ kekere kan ni ariwa Malawi, Emily Nkhana lo ma sọ ogede ti o ti pọn ju nu tabi eyi to ti bajẹ fun jijẹ nu, ṣugbọn o ti rii ọna abayo fun lilo ti o ni ere fun wọn - ọti-waini ọgẹdẹ.

Ooru gbigbona n fa ti ọgẹdẹ fi n pọn ni kiakia, ti o si n yọ ri si ọpọ adanu nla fun Ms Nkhana ati ọpọlọpọ awọn agbe miiran ti o n gbe ni agbegbe Karonga.

"Lẹyin ti a ṣe awari bi a ṣe le ṣe ọti-waini ọgẹdẹ," o sọ fun BBC, bi o ṣe n yọ awọn lemoni ti yoo lo lati ṣe itọju itọwo ọgẹdẹ ni ile-iṣẹ Twitule Cooperative Group.

Fun awọn agbe, kii ṣe nipa ṣiṣe ọti-waini nikan - ṣugbọn bi ko n se pe ki sun siwaju nipa awọn nnkan ti wọn pese latara ọgẹdẹ.

Wọn maa n da oko lẹgbẹẹ etí omi adagun Malawi, awọn ohun ọgbin ọgẹdẹ wọn ni omi ma n fọ danu nitori apọju ojo, eyi to jẹ ki wọn sun soke

“Ni oko atijọ, ipenija wa ni ọpọlọpọ omi lati adagun. Diẹ ninu awọn ogede lo ma omi lọ. Diẹ ninu awọn ọgẹdẹ, a ko ni ri ibi ti a gbin wọn si.

Aworan oko ọgẹdẹ ninu omi

Oríṣun àwòrán, Anne Okumu/BBC

“Ni ibi yii, a ni ọpọ oorun. O jẹ ki ogede wa ma pọn ni kiakia, ti a si ma padanu wọn, ”Ms Nkhana sọ.

Nkhana jẹ ọmọ ẹgbẹ awọn obinrin ti o pejọ lati ẹgbẹ alajẹsẹku silẹ lati mojuto eto-ọrọ aje wọn nipasẹ iṣẹ-ogbin.

Ṣiṣe ọti-waini jẹ iṣowo-kekere ni awọn ẹyinkunle awọn obirin, nibiti wọn ti gbin ọgẹdẹ si.

Ilana ṣiṣe ọti-waini ma n waye ni agbala ile oni oju mẹrin ni abule Mchenjere.

Ilana naa rọrun: awọn ọgẹdẹ to ti pọn ju yii ni wọn ma bo, ge wọn si wẹwẹ, po wọn pọ pẹlu suga, omi ati awọn ohun aladun mii.

Wọn ma fi adalu naa silẹ lati po pọ fun ọpọ ọsẹ, eyi ti yo yi pada si ọti waini, ti yoo si tun ọti ida mẹtala lara

"O jẹ ọti-waini ti o dara pupọ. O ni lati mu nigba ti o joko ki o le gbadun adun rẹ, ”Ms Nkhana sọ.

Igo ọti waini ọgẹdẹ

Oríṣun àwòrán, Anne Okumu/BBC

Wọn ma fi adalu naa silẹ lati po pọ fun ọpọ ọsẹ, eyi ti yo yi pada si ọti waini, ti yoo si tun ọti ida mẹtala lara

"O jẹ ọti-waini ti o dara pupọ. O ni lati mu nigba ti o joko ki o le gbadun adun rẹ, ”Ms Nkhana sọ.

Ọti waini ọgẹdẹ naa, eyi ti o le wa ni awọ orisirisi, ni itọwo didun diẹ, to dun mọni pupọ.

"O dan lẹnu, o fẹrẹ dabi ọti-waini desaati," Paul Kamwendo, olutaja ọti-waini ni agbegbe kan ti o ti di ọkan ninu awọn ololufẹ ọti-waini ọgẹde ni Karonga. ṣalaye.

"N ko ni ero pe eeyan le ṣẹda ọti waini lati ara ọgẹdẹ."

Fun Ms Nkhana ati awọn akẹgbẹ rẹ, kọkọrọ pipese ọti waini to dara da lori iwọnsuwọn gbogbo ele rẹ.

“Asiko ni gbogbo nnkan,” o sọ. “O ni lati mọ igba ti ọgẹdẹ ba dará lati lo. To ba ti pọn ju, ọti-waini yoo dun ju.”

Ewe ọgẹdẹ ni Malawi

Oríṣun àwòrán, Anne Okumu/BBC

Ọti-waini ogede ni Malawi ti fa ajọsepọ nla laarin awọn ontaja ati awọn onibara.

Tennyson Gondwe, adari agba ti ẹgbẹ alajẹsẹku ni agbegbe sọ pe “A n ta awọn waini yii ni awọn ọja kaakiri Malawi, ni olu-ilu Lilongwe ati ni ilu nla Blantyre ati pe o ma n ta gbogbo rẹ tan.

O tẹsiwaju pe wọn se idanilẹkọ fun awọn obinrin lori pipese ọti waini ọgẹdẹ

Ms Nkhana sọ pe ṣiṣe ọti-waini, ti mu ayipada ba igbesi aye rẹ ati awọn obinrin mii, to si pe ju ki o kan ma ta awọn ọgẹdẹ to ti bajẹ lọ

"Diẹ ninu wa ti kọ ile, diẹ ninu wa ni awọn ẹran-ọsin. A le jẹ ounjẹ to dara."

Ẹgbẹ Twitule n pese laarin 20-50 liters ọti-waini ni oṣu kan ati pe wọn ni reti lati ra awọn ẹrọ lati ṣe iranlọwọ fun wọn lati faagun.

"A fẹ ma pese ọpọ ọti-waini sii. A fẹ kro lati okowo kekere wa si ile-iṣẹ nla, "Ms Nkhana sọ.