Èèyàn mẹ́je farapa níbi ilé alájà méje tó dàwó l‘Eko, òṣìṣẹ́ kan sọnù, kò sẹ́ni tó kú - Ìjọba Eko

Oríṣun àwòrán, FACEBOOK/LASEMA
Oludari agba fun akanse isẹ fun gomina tipinlẹ Eko, Mobolaji Ogunlende, ti sọrọ nipa ile alaje meje to da wo lulẹ ni agbegbe Banana Island, Ikoyi nilu Eko.
Irọlẹ ọjọru ni ile alaja meje naa da wo lulẹ.
Nigba o n ba BBC Yoruba sọrọ, Ogunlende ni irọlẹ Ọjọru ni ipe pajawiri tọ awn wa pe isẹlẹ naa waye.
Amọ o ni oun ko tii le sọ ohun to mu ki ile naa da wo lulẹ sugbọn iwadii ti n lọ lọwọ lati mọ ohun to faa.
"A ko gbe awọn to fara pa lọ sile iwosan, ọkọ pajawiri ijọba Eko lo setọju ranpẹ fun wọn"
Nigba to n tẹsiwaju ninu ọrọ rẹ Ogunlende salaye pe eeyan meje lo fara pa ranpẹ ninu ile alaja meje to da wo naa.
O ni ko si ẹnikẹni to ba isẹlẹ naa lọ amọ awọn si n wa eeyan kan lara awọn osisẹ ibẹ, ti wọn ko mọ ibi to wa.
O ni ni kete ti isẹlẹ ile didawo naa waye, ni ọkọ itọju alaisan ni pajawiri to jẹ tijọba Eko ti de sibi isẹlẹ naa.
O fikun pe ọkọ yii si ni awọn lo lati fi tọju awọn eeyan meje to ni ifarapa ranpẹ nibi isẹlẹ naa.
O ni awọn ko gbe ẹnikẹni lọ sile iwosan fun itọju nitori ohun to se wọn ko pọ rara.
Amọ o ni awọn ti gba awọn eeyan naa nimọran lati gba ile iwosan lọ lati se ayẹwo ara wọn siwaju si, aibaamọ, ohun to se wọn le ju bawọn se lero lọ.
"A dan ile mẹta to ku wo lati mọ boya yoo duro tabi bẹẹ kọ"
Ninu ọrọ rẹ, oludamọran si gomina fun akanse isẹ ni ile alaja meje to jẹ iru kannaa bii mẹrin lo wa ninu ọgba ti ile ti da wo naa.
O ni ọkan ninu awọn ile naa lo wo lulẹ, ti awọn ko si le sọ boya mẹrin yoku poju owo tabi wọn si le da wo lulẹ bii ti akọkọ.
O wa fọwọ gbaya pe ayẹwo yoo waye lati mọ boya awọn ile naa pegede, ti wọn si le duro tabi bẹẹ kọ.
Mobolaji Ogunlenle wa sisọ loju rẹ pe ileesẹ abanikọle Joe Farade lo n kọle to dawo lulẹ naa.
Ile alaja meje to da wo ko ni iwe asẹ pe a fọwọ si - Ijọba Eko
Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko ti sọ̀rọ̀ lórí ilé alájà méje tí wọ́n ń kọ́ lọ́wọ́ tó wó lulẹ̀ ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́rú ní agbègbè Banana Island, Ikoyi.
Àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ ilé iṣẹ́ tó ń rí sí ààtò ìlú, Mukaila Sanusi fi léde ní àwọn tó ń kọ́ ilé ọ̀hún kò gbàṣẹ lọ́wọ́ ìjọba kí wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ilé náà.
Sanusi ní kété tí ìjàm̀bá náà wáyé ní Kọmíṣọ́nà fún ààtò ìpínlẹ̀ Eko, Onímọ̀ ẹ̀rọ Tayo Bamgbose-Martins ti ṣe àbẹ̀wò síbi ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Ìjọba Eko bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ilé tó dàwó

Oríṣun àwòrán, FACEBOOK/LASEMA
Ó ní Bamgbose-Martins ti pè fún ìwádìí tó péye sínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà tó sì tún ṣàlàyé pé ìjọba Eko kò mọ̀ sí iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe níbẹ̀ nítorí wọn ò gbàṣẹ lọ́wọ́ ìjọba kí wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́.
Sanusi fi kun pé gbogbo àwon farapa nínú ìjàm̀bá ọ̀hún ló ti ń gba ìtọ́jú.
Ó ṣàlàyé pé lásìkò tí wọ́n ń gbìyànjú láti gbé ìpele ilé mìíràn mọ́ èyí tí wọ́n ń kọ́ lọ́wọ́ ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé.
Ó wá rọ àwọn ará ìlú láti má mikàn àti pé bí nǹkan bá ṣe ń lọ ni àwọn yóò máa fi tó ìlú létí.
Ìwádìí fi hàn pé àwọn ilé alájà mẹ́sàn-án méjì mìíràn tí wọ́n ń kọ́ lọ́wọ́ ṣì wà ní digbí ní tirẹ̀ àmọ́ ìjọba ni àwọn máa ṣe àyẹ̀wò rẹ̀ láti mọ bí àwọn náà ṣe dúró sí.
A ṣì ń wá ènìyàn kan tó há sábẹ́ ilé náà - LASEMA

Oríṣun àwòrán, FACEBOOK/LASEMA
Kò dín ní ènìyàn méje tí wọ́n móríbọ́ nínú ilé tó dà wó lulẹ̀ lọ́jọ́rú ní agbègbè Banana Island, Ikoyi, ìpínlẹ̀ Eko.
Ní nǹkan bíi aago márùn-ún ìrọ̀lẹ́ ọjọ́rú ni ilé alájà méje tí wọ́n ń kọ́ lọ́wọ́ náà ṣàdédé dà wó lásìkò tí àwọn òṣìṣẹ́ ibẹ̀ ń ṣiṣẹ́ lọ́wọ́.
Ìròyìn ní pé àwọn òṣìṣẹ́ kan móríbọ́ láì farapa, tí àwọn mìíràn sì farapa kékeré, tí àwọn mìíràn sì tún há sábẹ́ ilé náà.
Títí di àsìkò tí à ń kó ìròyìn yìí jọ, àjọ tó ń mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì ní ìpínlẹ̀ Eko, LASEMA ní àwọn ṣì ń wá ènìyàn kan tó ṣeéṣe kó jẹ́ wí pé ó há sábẹ́ ilé náà.
Ọ̀kan lára àwọn òṣìṣẹ́ ilé náà tó bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ ní orí àjà kẹfà ilé náà ní àwọn ṣiṣẹ́ dé láti gbé àjà keje le lórí kí ilé náà tó dà wó lulẹ̀.
Àtẹ̀jáde kan tí ọ̀gá àgbà àjọ LASEMA, Olufemi Oke-Osanyintolu fi léde ní ìwádìí fi hàn pé ọkọ̀ ńlá tó ń po sìmẹ́ǹtì ló ṣokùnfà bí ilé náà ṣe dàwó.
Oke-Osanyintolu ṣàlàyé pé nígbà tí ọ̀gá ẹ̀ṣọ́ ààbò ilé náà, Anthony Onah ka àwọn òṣìṣẹ́ tó ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀, ó ku òṣìṣẹ́ tí wọ́n ń wá tó sì ṣeéṣe kó ṣì wà lábẹ́ ilé ọ̀hún.
Ó ní iṣẹ́ ń lọ láti ṣàwárí ọkùnrin náà, àti pé gbogbo àwọn ohun èlò tí àwọn nílò láti fi ṣiṣẹ́ ló ti wà níbẹ̀.
Ọ̀gá àgbà ilé iṣẹ́ panápaná ìpínlẹ̀ Eko, Margaret Adeseye nínú ọ̀rọ̀ tirẹ̀ ní ènìyàn méje ni àwọn ti yọ tó sì jẹ́ wí pé wọ́n farapa.
Adeseye ní ènìyàn kan ló ṣì wà tó há sábẹ́ ilé náà tí iṣẹ́ kò sì dúró láti yọ ẹni náà.















