Àwọn ará Ìsàlẹ̀ Eko bínú lórí fíímù 'Gangs of Lagos' tí wọ́n ló tàbùkù eégún Ẹ̀yọ̀, ìjọba ìpínlẹ̀ Eko sọ̀rọ̀

Aworan

Oríṣun àwòrán, Gang of Lagos/Others

Ọpọlọpọ awọn eniyan tii wọn jẹ ọmọ bibi ipinlẹ Eko lo ti fi aidunnu wọn han si fiimu tuntun kan ti o ṣẹṣẹ jade, ti wọn pe akọle rẹ ni 'Gangs of Lagos'.

Fiimu naa lo ṣafihan bi awọn ọdọmọde ni agbegbe Iṣalẹ Eko nipinlẹ Eko ṣe bẹrẹ iṣẹ ọdaran ni agbegbe naa.

Isale Eko, ti fiimu naa da le lori jẹ ọkan lara awọn agbegbe to gbajugbaja nipinlẹ Eko.

Amọ ijọba ipinlẹ Eko, to fi mọ awọn ara isalẹ Eko ati Ọba Adebola Dosunmu to jẹ Akinsiku ti ilu Eko, lo ti fesi si isẹlẹ naa.

Gbogbo wọn si lo fi aidunnu wọn han lori bi fiimu naa ṣe tabuku eegun Ẹyọ, Adimu Orisa ati awọn ohun iṣẹṣe nipinlẹ Eko.

''Ẹ fofin de fiimu Gangs of Lagos ni kiakia, awa ara Eko korira fiimu naa''

Akinsiku ti ilu Eko, Oloye Adebola Dosunmu, ninu atẹjade kan to fisita nipa is. ti ni ki wọn fofin de fiimu tuntun to ṣeṣẹ jade naa.

Dosunmu ni fiimu naa safihan awọn eegun Ẹyọ gẹgẹ bi awọn ọmọ ita akọkọ nipinlẹ Eko.

O ni fiimu naa jẹ ohun idọti, to si kun fun irira awọn ohun ti wọn di mu gẹgẹ bi aṣa ati iṣe ipinlẹ Eko.

Ninu ọrọ rẹ, Akinsiku ti ilu Eko ni eniyan ko le dede gbe Eyo jade nitori o jẹ ọmọ Eko.

‘’Ẹyọ kii ṣe fun fiimu tabi ere ọmọde, bẹẹ ni kii se ohun ti wọn n gbe jade lasiko igbeyawo abi asiko ti wọn ba n ṣe ikomọjade ni agbegbe kan.’’

‘’Adamu Orisha naa kii ṣe ohun atẹmẹrẹ, eto to n se afọmọ ilu ni, ti wọn ma n se fun ọba to ba waja tabi ọmọ ipinlẹ Eko to ti ṣiṣẹ takun takun nilẹ naa.

‘’Awọn Ejilu ati Malakin to jẹ awọn ibatan Olori Olugbani ni wọn kọ́kọ́ se Eyo ni iranti Ọba Ado Keme.

Lati igba naa ni Adamu Orisha ti jẹ ohun iyi ni ipinlẹ Eko’’

Aworan

Oríṣun àwòrán, PRESS RELEASE

''Awa ara Isale Eko la ni Eyo, a ki n ṣe apaniyan tabi ọdaran'' – Isale Eko Decendant Union

Bakan naa ni ẹgbẹ awọn ọmọ agbegbe Isalẹ Eko, Isale Eko decendant Union t i fi ero wọn han lori fiimu naa.

Wọn ni fiimu naa ṣafihan awọn ara isalẹ Eko gẹgẹ bi ọdaran ati apaniyan ti ko ni ọjọ iwaju.

Bakan naa ni wọn ni awọn lo ni Eyo ni Isalẹ Eko ti kii si n ṣe ohun atẹmẹrẹ ti wọn le maa fi sere.

Nibayii a ti kesi ajọ to n risi fiimu ni Naijiria lati ri pe wọn fofin de fiimu naa, nitori ko dun mọ wa ninu rara.

Amọ fiimu naa ṣafihan Eyo gẹgẹ bi ohun ti awọn ọdaran fi n boju lati fi ṣe aṣemaṣe ati hu iwa ọdaran to fi mọ ipaniyan ni agbegbe naa.

Skip Instagram post, 1
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post, 1

Skip Instagram post, 2
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post, 2

Fiimu ''Gang of Lagos'' tabuku ipinlẹ Eko ati awọn ohun to pọn dandan si wa – Ijọba ipinlẹ Eko

Ninu ọrọ wọn, ijọba ipinlẹ Eko ti ko si ohun iwuri kankan ninu fiimu gang of Lagos nitori o tabuku gbogbo ohun to sẹ koko si awọn ara ipinlẹ Eko.

Ninu atẹjade ti kọmiṣọnna fun ọrọ igbafẹ, Uzamat Akinbile-Yussuf fi lede ni awọn to gbe fiimu naa jade ko ṣe iwadii finifini lori awọn ohun ti wọn tọkasi ninu fiimu naa.

O ni wọn ṣe fiimu naa lati sọ wi pe ilu Eko kun fun awọn onijagidijagan ati oniwa ipa, to fi mọ awọn ọdaran.

O ni eleyii ko safihan awọn ara Eko gẹgẹ bi ọmọluwabi, ti o ni ko yẹ ko ri bẹẹ.

Bakan naa ni ijọba ipinlẹ Eko ni Adamu Orisha ti ọpọ mọ si Eyo kii sẹ ohun ti wọn le maa fi ṣere tabi tabuku rẹ bi wọn ṣe ṣe ninu ere naa.

Ijọba ni Ẹyo kii ṣe ohun ti wọn n gbe jade nigba to ba wu wọn, igba ti eniyan jankanjankan ba lọ si ibi agba n re tabi ọba nikan ni Eyo ma n jade, ti o si ni awọn asa ati ise to rọmọ.

Wọn fikun un pe ohun iyi ati ẹyẹ ni Eyo, kii ṣe ohun ti wọn le maa tabuku rẹ lai bọwọ fun asa ilẹ Yoruba.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Bawo ni Fiimu ‘’Gang of Lagos’’ se jẹ?

Fiimu Gang of Lagos jẹ fiimu to ṣafihan iwa ọdaran ati iwa ipa , eleyii ti awọn eniyan mọ si action fiim.

Fiimu naa ni wọn fi agbekalẹ rẹ si agbegbe Isalẹ Eko, nipinlẹ Eko lo sọ itan awọn ogo wẹẹrẹ ti wọn jọ n dagba papọ ati igbe aye wọn ni agbegbe ti wọn si dagba.

Jade Osiberu ati Kemi Lala Akindoju ni wọn gbe fiimu naa jade.

Awọn oṣere tiata to wa ninu fiimu naa ni Bankole Wellington, Adesua Etomi-Wellington, Kola Aina ati bẹẹ bẹẹ lọ.