INEC fún Obi, Atiku lésì nílé ẹjọ́, Ó ní Tinubu ló borí ìbò ààrẹ

Oríṣun àwòrán, apc/twitter
Ajọ eleto idibo Naijiria INEC ti rọ ile ẹjọ to n gbọ awuyewuye esi idibo aarẹ lorilẹede Naijiria pe ko wọgile awọn ẹjọ gbogbo ti wọn pe siwaju rẹ lati tako kikede ti wọn kede Bọla Ahmed Tinubu, ti APC gẹgẹ bi aarẹ ti wọn dibo yan lasiko ibo aarẹ to waye loṣu keji ọdun 2023.
Tinubu ni ajọ INEC kéde gẹgẹ bi olubori ibo naa pẹlu ibo miliọnu mẹjọ ati ẹgbẹrun lọna ẹgberin o din diẹ.
Bakan naa ninu esi ibo ti Ajọ INEC kede, o ṣalaye pe ibo miliọnu meje o din diẹ ni Atiku Abubakar ti PDP to ṣe ipo keji ni, ti Peter Obi ti ẹgbẹ oṣelu Labour Party si ni ibo to le diẹ ni miliọnu mẹfa lati ṣe ipo kẹta.
Amọ o, Atiku ati Obi faake kọri oe awọn ko le gba esi ti INEC kede naa, ni wọn fi gba ile ẹjọ lọ pe ki ile ẹjọ wọgile idibo naa.
INEC fesi si ipẹjọ Obi lori ọrọ olu ilu Naijiria FCT Abuja
Ninu awijare ti awọn agbẹjọro INEC, eyi ti A B. Mahmoud,SAN ko sodi, gbe kalẹ tako gbogbo ipẹjọ to waye nipa idibo naa, INEC ni ipẹjọ Atiku “ko lẹsẹ nlẹ, ko kun oju iwọn, eremọde lasan ati aṣilo ilana idajọ.”

Oríṣun àwòrán, twitter/peter obi
INEC ṣalaye fun ile ẹjọ to n gbọ awuyewuye esi idibo naa pe Tinubu ni ilu dibo yan lootọ nitori pe oun nikan lo ni ida mẹrin ibo ni ipinlẹ mọkandinlọgbọn eyi to ju ipinlẹ mẹrinlelogun ti ofin la kalẹ, yatọ si nini akojọpọ ibo to pọ julọ ninu ibo ti araalu di, nitori naa ko si a iani pe oun lo gbe oroke.
Lori awuyewuye pe Tinubu ko bori ni olu ilu Naijiria, Abuja, INEC ṣalaye pẹlu ila kalẹ iwe ofin ọdun 1999, “ipo ipinlẹ ni olu ilu Naijiria Abuja dimu, to si yẹ ki wọn rii ẹ gẹgẹ bi ara awọn ipinlẹ ni Naijiria.”
INEC ni yatọ si pe Abuja jẹ ilu ilu Naijiria, ko si aye pataki kan to ni lori awọn ipinlẹ mẹrindinlogoji to wa lorileede Naijiria ti yoo fi wa di dandan pe ki oludije sipo aarẹ ni ida kan ninu mẹrin ibo ni ẹ ki wọn to le kede oludije bẹẹ gẹgẹ bii olubori idibo sipo aarẹ.
‘Atiku ni idibo ko dara sibẹ o n fẹ ka kede oun pẹlu esi to ni ni ibo yii kan naa’

Oríṣun àwòrán, twitter/ atiku abubakar
Nigba to n fesi si ipẹjọ Atiku Abubakar, Oludije ẹgbẹ oṣelu PDP, Ajọ eleto idibo Naijiria, INEC sọ peko si bi Atiku ṣe le ni oun lo bori ibo naa nitori pe o kuna lati ni ida mẹrin ibo ni ida meji ninu meta ipinlẹ to wa ni Naijiria.
Bakan naa ni INEC tun tẹnu mọ ọ pe ibo naa tẹle ilana ofin eto idibo ni Naijiria.
Inec ni oun “tẹle gbogbo ofin ati ilana to yẹ, oun ṣe ojuṣe oun bi o ti tọ ati bi o ṣe yẹ lasiko kika ibo olupẹjọ akọkọ (Atiku) eyi ti apapọ rẹ jẹ, miliọnu mẹfa, ẹgbẹrun lọna ọrinlelẹẹdẹgbẹrun o le mẹrin ati okoo le ẹẹdẹgbẹta 6,984, 520.”
INEC ni, Atiku to n lọgun pe awuruju pọ ninu eto idibo naa ati akojọpọ esi idibo ohun gba iye ibo tiwọn gẹgẹ bí ootọ lori eyi ti wọn fi n rọ ile ẹjọ naa ko kede oun gegebi olubori, sibẹ o n pariwo pe eto idibo naa ko dara.
A mu ileri wa lati seto idibo ti ko lẹjambakan ninu ṣẹ - INEC

Oríṣun àwòrán, rinubu/twitter
INEC ni oun mu ileri ti oun ṣe fun ọmọ Naijiria ṣẹ lati ṣeto idibo “ti ko lẹja n bakan ninu nipa lilo eroja imọ ẹrọ igbalode BVAS ati ṣiṣe afihan esi ibo lori atẹ ayelujara IReV.” INEC tun ṣalaye pe fifi esi idibo ranṣẹ si ori atẹ ayelujara IReV kii ṣe ara gbendeke fun kikede esi idibo labẹ iwe ofin idibo ni Naijiria.
INEC ni Ofin naa ko ni oun “gbọdọ fi esi ibo ranṣẹ si ori IReV ki ikede olubori ibo aarẹ to waye.”
Ajọ naa tun fi kun un pe BVAS ko wa fun fifi esi ranṣẹ si arumọjẹ atẹ ayelujara alakojọpọ esi ibo Electronic Collation System kankan gẹgẹ bi ẹsun ti Atiku gbe kalẹ
Awijare APC
Ẹgbẹ oṣelu APC pẹlu ti gbe awijare rẹ tọ ile ẹjọ to n gbọ awuyewuye esi idibo aarẹ lọ lati tako gbogbo ipẹjọ to tako oludije rẹ.
Lara awọn ohun ti awọn to n pẹjọ tako Tinubu n sọ ni pe Tinubu ko kun oju iwọn lati dije fun idibo aarẹ naa. Wọn n tọka si ejọ kan to waye nilẹ Amẹrika nibi ti wọn ti gbẹsẹ le awon owo kan ninu aṣuwọn ifowopamọ si rẹ.
Ninu esi rẹ si ẹsun yii, APC ni gbọyisọyi lo pọju ninu ipẹjọ ati ẹsun ti awọn ẹgbẹ oṣelu yooku n gbe jade, ko si lẹsẹ nlẹ rara.
‘Lootọ ni ijọba Amẹrika gbẹsẹle owo oṣuwọn kan lorukọ Tinubu ṣugbọn…'

Oríṣun àwòrán, apc/twitter
APC ni lootọ ni ijọba gbẹsẹ le owo Tinubu ti jẹ ẹgbẹrun lọna ọtalerinwo dollar $460,000 sugbon ile ẹjọ ko da aarẹ ti ilu ṣẹṣẹ dibo yan naa l’ẹjọ tabi lẹbi iwa ọdaran kankan.
“ko si igba kankan ti olujẹjọ keji (Tinubu) san owo itanran ẹgbẹrun lọna ọtalerinwo dollar $460,000 fun iwa ọdaran kankan to nii ṣe pẹlu aiṣootọ tabi iwa odaran kankan ninu ẹjọ ‘United States of America V Funds in Account 263226700 held by First Heritage Bank in the name of Bola Tinubu & 2 Ors.’ to wa l’orukọ Bola Tinubu ni banki First Heritage Bank.”

Oríṣun àwòrán, tinubu/twitter
APC ni Tinubu ko si lara awọn ti ile ẹjọ pe lẹjọ ninu ẹjọ ti wọn tọka si naa ati pe ẹjọ naa ki ṣe ẹjọ iwa ọdaran.
O fi kun un pe “ ileeṣẹ aṣoju ijọba Amẹrika ni Naijiria ti fihan pe ko si akọsilẹ kankan pe wọn figba kankan mu olujẹjọ keji yii (Tinubu) fun iwa ọdaran tabi daa lẹbi iwa ọdaran kankan”













