APC sọ̀rọ̀ lórí ìdí tí Tinubu fi jọ̀wọ́ $460,000 fún ìjọba Amẹ́ríkà lórí ẹ̀sùn egbògi olóró

Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, Twitter

Ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, APC ti ní lóòótọ́ ni Ààrẹ tuntun tí Nàìjíríà ṣẹ̀ṣẹ̀ dìbò yàn, Bola Tinubu jọ̀wọ́ owó $460,000 sápò ìjọba Amẹ́ríkà lọ́dún 1993 lórí ẹ̀sùn tó ní í ṣe pẹ̀lú egbògi olóró.

Àmọ́ APC ní kìí ṣe wí pé ilé ẹjọ́ dá Tinubu lẹ́bi lórí ẹ̀sùn náà, ló ṣe jọ̀wọ́ owó náà sílẹ̀.

Ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party àti olùdíje rẹ̀, Peter Obi ló ti ṣaájú pe ìjáwé olúborí Tinubu níbi ètò ìdìbò Ààrẹ lẹ́jọ́ tó sì ní kí ilé ẹjọ́ kéde òun gẹ́gẹ́ bí ẹni tó jáwé olúborí ìbò náà.

Ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé lọ́dún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n sẹ́yìn kò tó láti sọ pé Tinubu kò le díje dupò Ààrẹ - APC

Obi ní jíjọwọ́ owó náà fún ìjọba Amẹ́ríkà túmọ̀ sí pé Tinubu lọ́wọ́ nínú gbígbé egbògi olóró ló jẹ́ kó le gbàgbé owó náà.

Àmọ́ ẹgbẹ́ APC ní Tinubu kàn fi owó náà sílẹ̀ ni kìí ṣe wí pé ìjọba ló dájọ́ fun.

Bákan náà ni APC tún sọ fún ìgbìmọ̀ tó ń gbọ́ ẹ̀hónú ìbò tó wà ní Abuja ní àwọn owó tí Tinubu jọ̀wọ́ rẹ̀ jẹ́ owó tó wà ní akoto báńkì ilẹ̀ Amẹ́ríkà méjì.

Bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n sọ wí pé ìṣẹ̀lẹ̀ tó ti wáyé láti ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n sẹ́yìn kò tó láti sọ wí pé Tinubu kò le díje dupò Ààrẹ lásìkò yìí.

Àkọlé fídíò, Orisabunmi Olasanya: Pásítọ̀ àti Alfa ń wá ṣe òògùn lọ́dọ̀ bàbá mi

Àbájáde èsì ìdìbò ọdún yíì fihàn pé àwọn olùdìbò ti gbọ́n - Buhari

Aworan

Oríṣun àwòrán, Muhammadu Buhari

Aarẹ Muhammadu Buhari ni esi abajade eto dibo ọdun 2023 nibiti gomina mẹwa ti bọrẹlẹ ninu eto idibo sile igbimo aṣofin agba ti fihan wi pe awọn ọmọ orilẹede yii mo oun ti wọn n ṣe.

Aarẹ Buhari sọrọ naa nigba ti oun gba alejo Emir Dutse tuntun, Alhaji Hamin Nuhu Sanusi, o ni abajadẹ esi idibọ ọdun 2023 ti fihan wi pe iṣejọba awarawa ti gbilẹ sii lorilẹede yii.

Ọpọ igba ni awọn gomina ma n wole pada gẹgẹ bi aṣofin agba lati ipinlẹ wọn ṣugbọn, bi awọn mẹwa ti bọrẹlẹ fihan wi pe ki eeyan jẹ gomina, ko ni ki wọn dibo yan an gẹgẹ bii sẹnetọ.

Aarẹ ni “igbagbọ gbogbo wa ni wi pe lẹyin ọdun mẹjọ gẹgẹ bi gomina, waa lọ sile igbimo aṣofin gẹgẹ bi sẹneto lati kadi iṣejọba rẹ nilẹ, ṣugbon pẹlu bi oṣelu orilẹede yi ti n lọ, aa le foju di awọn oludibo nitori eto oṣelu wa ti n yatọ si ti tẹlẹ o n le sii ni.

Lara awọn gomina to padanu ninu eto idibo sipo sẹneto ni,

Okezie Ikpeazu (Abia),

Samuel Ortom (Benue),

Ifeanyi Ugwuanyi (Enugu),

Simon Lalong (Plateau),

Darius Ishaku (Taraba),

Ben Ayade (Cross River)

Abubakar Atiku Bagudu (Kebbi)

Buhari nigba ti oun ki Emir Dutse Tuntun ṣeleri lati mu opin ba iṣoro aisi omi ni ipinlẹ Jigawa ki iṣejọba oun to pari.

Emir naa dupẹ lọwọ aarẹ Buhari fun ipa ribiribi to ko lati rii wi pe ipinlẹ Jigawa di ọkan gbo ogi lara awọn ipinlẹ to n gbin irẹsi lorilẹede yii, ati bi o ti fọwọ si ipese lila ọkọ oju irin lati Dutse si Kano ati alafia to ti pada si ipinlẹ Jigawa ati awọn ipinlẹ to mule ti.