Àwọn ọ̀dọ́ tó ń jà nítorí ọ̀rẹ́bìnrin tó wà ní JSS 2 ba ọkọ̀ 25 jẹ́ nílùú Ilorin

Oríṣun àwòrán, Tribune Online
Ko din ni ọkọ eyọkẹlẹ marundinlọgbọn ti awọn ọdọ kan bajẹ niluu Ilorin lẹyin ija kan to waye nibẹ.
Iroyin ni awọn ọdọ lati Itamerin ati Ode Popo lo dawọjọ lati na ọrẹkunrin ọmọdebirnin kan ti orukẹ rẹ n jẹ Aisha, to jẹ ọmọ ile ẹkọ girama.
Gẹgẹ bii ohun ti a gbọ, ija naa bẹ silẹ lẹyin ariyanjiyan to waye laarin awọn ọdọ ọhun lori ẹni tojẹ ojulowo ọrẹkunrin ọmọge naa.
Agbalagba kan ti ọrọ naa ṣoju rẹ ni Ode Popo, Alhaji AbdulRazaq ṣalaye pe “Nnkan bii aago kan ọsan ọjọ Abamẹta ni iṣẹlẹ naa waye nitori ọmọbirin kan to wa ni JSS2, iyẹn Aisha, ti ọjọ ori rẹ ko ju ọdun mejidinlogun lọ.”
“Wọn bẹrẹ si n ko ara wọn jọ fun ija lọjọ Ẹti, wọn si ba ọkọ to le ni marundinlọgbọn jẹ lọjọ Abamẹta.”
“A ke si awọn ọlọpaa ki wọn da si ọrọ naa ko to kọja oju ẹ.”
Ẹlomiran to jẹ olugbe agbegbe ti iṣẹlẹ ọhun ti waye, Omotayo, ṣalaye pe ọlọpaa ti fi ṣikun mu ọmọbirin ti wọn n ja tori rẹ, ati pe olori awọn ẹgbẹ mejeji to n ja ti na papa bora.
Iroyin ni awọn ọlọpaa G Division ati Oloje ti lọ sagbegbe ọhun, wọn si ti fi ṣikun ofin mu awọn afurasi kan.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara, Okasanmi Ajayi fidi iroyin naa mulẹ fun BBC Yoruba.
Amọ o ni awọn agbagba ilu ti yanju aawọ naa bayii.








