Ṣé lóòtọ́ ní àwọn orílẹ̀èdè àgbáyé ń ṣe ìrànwọ́ fún ẹgbẹ́ alakatakiti IPOB? Lai Muhammed sọ̀kò ọ̀rọ̀ sí wọn

Aworan minisita lai

Oríṣun àwòrán, LAIMUHAMMED/FACEBOOK

Ijọba apapọ orilẹede yii ti yẹpẹrẹ awọn orilẹede agbaye to n fun ẹgbẹ IPOB ti ijọba orilẹede yii ka si ẹgbẹ awọn agbesunmọmi ni idanimọ.

Minisita fun iroyin ati asa, Alhaji Lai Muhammed lo sọ ọrọ yii ni Washinton DC nigba ti o n ba awọn ile isẹ akọroyin ati awọn ile ẹkọ imọ ijinlẹ sọrọ.

Lai muhammed lọ si Washinton lati sọrọ lori eto idibo to ṣẹṣẹ pari ni Naijiria.

Minisita ni ẹgbẹ alakatakiti IPOB jẹ ẹgbẹ awọn agbesunmọmi ti ijọba orilẹede Nigeria fofin de, sibẹ awọn orilẹede agbaye kan gba wọn laaye, wọn tun n ba wọn ni ibaṣepọ”.

“Won gba wọn laye lati ko owo jọ, ti wọn si tun ba awọn aṣofin sọrọ, wọn n lo owo ti wọn ri lati da wahala silẹ ni orilẹede wa”.

Minisita ni iwa agabagebe awọn orilẹede alawọ funfun niyẹn, wọn ni awọn un gbogun ti ẹgbẹ alakatakiti bẹẹ awọn yi kan na ni wọn fun awọn ẹgbẹ alakatakiti ni atilẹyin.

O rọ awọn ile isẹ akọroyin ile okere lati se iwadii gbogbo ohun ti wọn ri lori ẹrọ ayelujara ki wọn to royin papajulọ lori abajade esi idibo ọdun 2023,ki wọn si ri daaju wi pe o jẹ otoọro ki wọn to gbe jade.

Peter Obi gbọdọ́ ṣọ́ra fún sísọ ọ̀rọ̀ tó lè dá ogun sílẹ̀ ní Naijiria - Lai Mohammed

Lai Mohammed

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ijọba apapọ ti kilọ fun oludije sipo Aarẹ ninu ẹgbẹ oṣelu Labour, Peter Obi, pe ko dẹkun ati maa sọrọ to le da rogbodiyan silẹ ni Naijiria.

Minisita fun iroyin at aṣa, Lai Mohammed lo kilọ bẹẹ lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ niluu Washington DC, l’Amẹrika.

Lara awọn ileeṣẹ iroyin ti Lai ba sọrọ ni Washington Post, Voice of America, Associated Press ati Foreign Policy Magazine.

"Obi n hu iwa iditẹgbajọba"

O sọ fun awọn ileeṣẹ iroyin naa pe ko tọna fun Obi lati maa sọrọ to le da ilu ru lẹyin to ti gba ile ẹjọ lori esi idibo Aarẹ to waye loṣu Keji.

Lai Mohammed ni “Obi ati igbakeji rẹ, Datti Ahmed ko le maa dunkoko mọ awọn ọmọ Naijiria pe opin yoo de ba ijọba awarawa ni Naijiria ti wọn ba le burawọle fun Tinubu.”

“Iwa iditẹgbajọba niyẹn.”

“Obi ko sọrọ bii ẹni to ni igbagbọ ninu ijọba awarawa rara, ni ṣe lo n sọrọ bii ẹni ti ireti ti pin fun.”

“Ko yẹ ki ẹni to ni igbagbọ ninu ijọba awarawa fi igbagbọ si asiko to ba bori ninu idibo nikan.”

Minisita naa sọ siwaju si pe bo tilẹ jẹ pe Obi ati Atiku ti pe ẹjọ tako esi ibo naa, wọn yoo pada lulẹ nile ẹjọ.

O pari ọrọ rẹ pe o ṣoro ki oludije jawe olubori ninu eto idibo nigba to jẹ pe oun lo ṣe ipo kẹta ninu ibo ọhun.