Àfi kí bàbà kọ̀wé fipò sílẹ̀ kí ẹgbẹ́ Afenifere lè ní ìlọsíwájú - Kole Omololu

Adebanjo ati Abagun

Pẹlu bi awọn ọdọ Afenifere ṣe sọ ninu ifọrọwerọ kan wi pe awọn ko ni igbagbọ ninu idari Pa Ayo Adebanjo gẹgẹ bi adari ẹgbẹ ọhun ti wọn si rọ ọ ko fipo silẹ.

Abagun Kole Omololu akọwe ẹgbẹ Afenifere ni igbesẹ awọn ọdọ to pe fun ikọwe fipo silẹ Baba Ayo Adebanjo gẹgẹ bi adari ẹgbẹ Afenifere ko sẹyin bi idari rẹ ṣe ti ṣu awọn ọmọ ẹgbẹ Afenifere.

Abagun Kole ni Baba Ayo Adebanjọ gba ipo adari fidihẹ lọwọ Baba Fasoranti nigbati o pe ọdun marundinlọgọrun, "bayii ti Baba Ayo Adebanjo ti pe ẹni ọdun marundinlọgọrun o ye ki awọn naa fipo silẹ fun ẹniti o kere si wọn".

Abogun Kole ni "igbesẹ awọn ọdọ ẹgbẹ Afenifere ko ya mi lẹnu nitori ọjọ iwaaju wọn ni wọn ja fun, ko yẹ ka ṣẹṣẹ sọ fun eeyan ko to mọ wi pe o yẹ ki oun fipo silẹ to ba jẹ wi pe lootọ lootọ la nifẹ iran Yoruba".

Ayo Adebanjo ko fa awọn ọmọ ẹgbẹ mora - Kole Ọmọlolu

Akọwe ẹgbẹ Afenifere ni “Baba Ayo Adebanjo ko fa awọn ọmọ ẹgbẹ mora, gbogbo awọn agbagba ilẹ Yoruba lo ti sa fun ẹgbẹ Afenifere ti wọn n joko sile ara wọn, Baba nse alaṣẹ waa, ko yẹ ko ri bẹẹ, nilẹ Yoruba Ọba ati Ọyomesi ni wọn n jọ gbimopọ ṣe'pinu, awọn agbagba ilẹ Yoruba ni wọn maa gbimopọ se ipinu, ti wọn ba ti sọrọ, Yoruba ti sọrọ niyen”.

O tẹsiwaju ninu ọrọ rẹ wi pe "ninu wọn ni Baba Fasoranti, Baba Adebanjo, Baba Falaye, C O Adebayo, Ọjọgbon Bolaji Akinyemi, Basorun Arogbofa, Baba Adebayo, wa. Ẹ bere lọwọ Baba, eeyan melo ni Baba Ayo Adebanjo n ba se pọ, nkan to n ṣe awọn ọdọ yii niyẹn".

O ni ori kan kii jẹ awa de, ilana olori ẹbi ni a n tẹle ninu ẹgbẹ Afenifere, ki oyinbo to de ni a ti n ṣe ijọba, "a fi Baba Adebanjo ṣe adari fidihẹ wọn si gba ojulowo adari sẹgbẹ ko dun mọ wa ninu o, igba akọkọ kọ niyi ti a o ni adari fidihẹ."

Abagun sapejuwe bi awọn adari ẹgbẹ Afenifere ti maa n ṣaaju yan adari fidihẹ.

"Nigbati Baba Ajasin wa ni idubulẹ aisan Baba Adesanya lo fidihẹ, ile Baba Ajasin ni a ti n ṣe ipade gẹgẹ bi olori ẹbi, nigbati Baba Adesanya wa ni idubulẹ aisan Baba Fasoranti ni wọn fidihẹ, Baba Fasoranti lo ni ki Baba Adebanjo maa ṣe e lọ, ile olori ẹbi ni o ti yẹ ki a maa ṣe ipade ṣugbọn Baba Adebanjo ko wa si ipade, ṣugbon wọn le lọ si Enugu lo ṣe ipade, wọn le lọ si Abuja lọ ṣe ipade o, ṣugbon eleyi to jẹ ti tiwatiwa ni Akure wọn o wa”.

Abagun ni baba ko gba imọran, tinu rẹ lo fẹ ṣe, eyi to buru julọ ni wi pe, Yoruba ni nnkan ti awọn n fẹ niyi, to ba je wi pe lotoo Yoruba ni a n ja fun nkan to yẹ ka se niyen, to ba si jẹ wi pe o fẹran ẹniti Yoruba nfẹ o ye ko dakẹ, Baba ko le fi tipatipa gbe ero wọn le wa lori”.

Ọna Abayo

Abagun ni baba gbọdọ gbọran si awa ọmọ lẹnu ti Baba ba ti fẹyinti gbogbo wa ni a o pada soju kan naa, Baba ni baba wa lọjọkọjọ, baba gbọdọ sinmi ki ẹlomiran gba ipo gẹgẹ bi adari.

Agba ẹgbẹ miran Pa Sehinde Arogbofa ni tirẹ sọ fun BBC Yoruba pe ti aawọ ba wa yoo ni ipari, nitori ko si oun to ni ibẹrẹ ti ko lopin.

Ẹwẹ, nigba ti a kan si Baba Ayo Adebanjo, ninu esi rẹ o ni, "ọrọ awọn yẹn (awọn ọdọ ẹgbẹ Afenifere) ko lesi rara, oun ti mo koju mọ nisinsinyi ni bi atunto yoo ṣe ba orilẹede yii, kini mo n wa, mi o fẹ sọrọ si ohun to wa nilẹ kii ṣe ẹsun to ba ojumu’.