Wo ohun tí àwọn èèyàn ń sọ nípa ìfọ̀rọ̀wérọ̀ Obi ati Oyedepo tó lu síta

Peter Obi/David Oyedepo

Oríṣun àwòrán, Naija News

Lẹyin ti fọran ifọrọwerọ Peter Obi ati alufa David Oyede lu sita, ọpọ awọn araalu lo ti bẹrẹ si n fi erongba wọn lede lori rẹ.

Bi awọn kan ṣe n da Obi lẹbi pe o n lo ọrọ ẹsin atawọn ọmọlẹyin Kristi fun oṣelu, lawọn mii n bere pe bawo ni ifọrọwerọ naa ṣe lu sita.

Lara awọn to sọrọ nipa ohun naa to jade ni awọn agbẹnusọ ẹgbẹ oṣelu Labour ati APC.

Alufaa David Oyedepo naa ti sọrọ soke lẹyin ti ifọrọwerọ ọhun lu jade.

Amọ ṣa, titi di akoko yii, Peter Obi funra rẹ ko tii sọ ohunkohun lori iṣẹ naa.

Femi Fani-Kayode, FFK

Nigba to n da si ọrọ naa, FFK, to jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC bu ẹnu atẹ lu Obi fun bo ṣe ti ọrọ ẹsin bọ osẹlu.

O ni Obi ko wu iwa ọmọluabi bo ṣe juwe eto idibo Aarẹ to waye loṣu Keji ọdun yii.

FFK ni “Fun Peter Obi lati juwe eto idibo naa gẹgẹ bii ija ẹsin fi han pe wọn ko kọ daadaa lati ile, o bajẹ, ko mọ ọrọ sọ, o fẹran ẹtanu ati iditẹ.”

O pari ọrọ rẹ pe ipo Aarẹ kii fun eeyan bii Peter Obi.

Festus Keyamo

Agbẹjọro agba, to tun jẹ agbẹnusọ fun ikọ ipolongo Bola Tinubu, Festus Keyamo sọ pe awọn alatilẹyin Obi buru ju awọn ti wọn n naka abuku si lọ.

Ọrọ Keyamo lo jade lẹyin ti agbẹnusọ Peter Obi, Valentine Obienyem, fidi rẹ mulẹ pe ifọrọwerọ to lu sita naa kii ṣe ayederu.

O ni “Awọn to n tẹle Obi yii ti fi han gbangba pe wọn buru ju iwa ibajẹ ti wọn ni awọn fẹ parẹ ni Naijria.”

Kenneth Okonkwo

Agbẹnusọ ikọ ipolongo Peter Obi, Kenneth Okonkwo ni tirẹ ni ẹgbẹ alatako n mọọmọ lo ifọrọwerọ naa lati ba orukọ Obi jẹ ni.

Ninu atẹjade kan loju Twitter rẹ lo ti sọ bẹẹ.

O ni “Ko yani lẹni pe ẹgbẹ alatako n lọ ọrọ yii mọ Peter Obi lẹsẹ lati fi han bii ẹni to n lo ẹsin fun oṣẹlu.”

Okonkwo sọ pe Obi ko ṣe bẹẹ rara, niṣe lo n ke si alufaa Oyedepo lati ṣatilẹyin fun un lọna ati tu Naijiria ṣe.

O pari ọrọ rẹ pe ẹgbẹ oṣelu APC gan lo n lo oṣelu, ati pe nitori bẹẹ loun ṣe fi ẹgbẹ oṣelu naa silẹ.

Valentine Obienyem

Agbẹnusọ Peter Obi, Valentine Obienyem nigba to n da si ọrọ naa ni lootọ ni ọrọ ọhun waye laarin Obi ati Oyedepo, amọ awọn eeyan ti tọwọ bọ fọran naa lati ba Obi lorukọ jẹ.

O ni awọn kan ti n ka gbogbo ọrọ ti Obi n sọ lori foonu silẹ lọna ati fi ṣikun ofin mu lori ẹsun iditẹ amọ wọn ko ṣaṣeyọri lo jẹ ki wọn gbe ifọrọwerọ naa jade.

Ohun tí Bishop Oyedepo sọ lẹ́yìn tí ìfọ̀rọ̀wérọ̀ rẹ̀ pẹ́lú Peter Obi lu sita rèé

KEN OKONKWO & BISHOP OYEDEPO

Oríṣun àwòrán, KEN OKONKWO & BISHOP OYEDEPO

Iroyin to n tẹ wa lọwọ ti fidi rẹ mulẹ pe ifọrọwerọ laarin Peter Obi ati alufaa David Oyedepo to lu sita kii ṣe ayederu.

Agbẹnusọ ikọ ipolongo Peter Obi ninu ẹgbẹ oṣelu Labour, Kenneth Okonkwo lo fidi iroyin naa mulẹ ninu atẹjade kan loju opo Twitter rẹ lọjọ Aiku.

Ninu ifọrọwerọ naa ni Obi ti n pe Oyedepo ni ‘Daddy’ to si n bẹ ẹ pe ko ba oun ba awọn ọmọ ijọ rẹ atawọn eeyan ipinlẹ Kwara sọrọ ki wọn le dibo fun oun.

Iroyin ni alẹ ọjọ to ṣaaju idibo Aarẹ ni Obi pe alufaa ọhun to si bẹẹ fun iranlọwọ ko le wọle ibo.

Iṣẹlẹ yi lo n waye lẹyin eto idibo Aarẹ Naijiria, eyii ti inu awọn ọmọ Naijiria kan ko dun si, paapaa awọn alatilẹyin Obi ato Atiku.

Peter Obi funra rẹ ati Atiku Abubakar ti gba ile ẹjọ lọ lori ọrọ ọhun.

Amọ ṣa, awọn ọmọ Naijiria kan naa tun ti n bu ẹnu atẹ lu Obi lori ẹsun pe o n lo ọrọ ẹsin lati fi polongo ibo, to si n lọ si awọn ile ijọsin fun itẹwọgba.

Oyedepo fesi ninu iwaasu

Ẹwẹ, alufaa David Oyedepo ti sọrọ soke lẹyin ti ifọrọwerọ naa pẹlu Obi lu jade lori ayelujara.

Ninu iwaasu rẹ to ṣe laarọ ọjọ Aiku ninu ijọ rẹ to wa niluu Otta, Oyedepo ni oun kii sọ ohun ti awọn n fẹ lati gbọ, bikoṣe eyii ti Ọlọrun ba fi si oun lẹnu.

O ni “Eredi ree ti awọn kan ṣe n binu si mi, ko si ẹni to tii sọ fun mi oun to yẹ ki n sọ nile aye yii ayafi Ọlọrun.”

“Mi o tii ṣe ipolongo ibo fun ẹnikẹni ri tabi ki n gba ẹnu oloṣelu sọrọ, mi o si ni ṣe bẹe lailai.”

O pari ọrọ rẹ naa pe “Ko si ẹgbẹ oṣelu kankan ni Naijiria yii ti ko tii wa sọdọ mi fun adura tabi amọran ri, temi ni lati gba wọn nimọran, awọn kan a gbọ, awọn kan ko si ni tẹle imọran mi.”